Romerbrevet 5 – BPH & YCB

Bibelen på hverdagsdansk

Romerbrevet 5:1-21

Forsoning og fred med Gud

1Vi blev altså accepteret af Gud, da vi kom til tro på Jesus Kristus, vores Herre. Derfor er vi nu forsonet med Gud og har fået fred i hjertet. 2Det er også Jesus, der gennem vores tro har ført os ind i den nåde, vi nu lever i, og vi ser med glæde frem til, at vi engang skal få del i al Guds herlighed. 3Men ikke bare det. Vi glæder os endda over at blive forfulgt, for vi ved, at forfølgelserne styrker vores udholdenhed. 4Udholdenheden giver os karakterstyrke, og karakterstyrken giver os en stærk forventning om at få del i Guds herlighed engang. 5Og vi bliver ikke skuffet i vores forventning, for Gud har givet os Helligåndens kraft og fyldt vores hjerter med sin kærlighed.

6Mens vi endnu var magtesløse og ugudelige, kom Kristus i rette tid og ofrede sit liv for at redde os. 7Der er ikke mange, der vil ofre livet for at redde et medmenneske! Jo, måske hvis det er et usædvanlig godt menneske. 8Men Gud viser sin kærlighed mod os, ved at Kristus ofrede sit liv for os, mens vi stadig var syndere, 9og han har nu accepteret os på grund af Kristi stedfortrædende død. Derfor kan vi trygt regne med, at når Kristus ved sin død forsonede os med Gud, vil han også redde os på dommens dag. 10Selvom vi var fjender af Gud, blev vi alligevel forsonet med ham, fordi hans Søn døde for os. Nu, da vi er blevet Guds venner, kan vi være forvissede om, at vi vil få det evige liv, fordi Jesus lever. 11Altså er det en utrolig glæde for os, at vi er blevet forsonet med Gud gennem Jesus Kristus, vores Herre.

Adam og Kristus som modsætninger

12Det første menneske, Adam, bragte synden ind i verden, og synden førte døden med sig. Sådan fik døden magt over alle mennesker, fordi alle syndede. 13Synden var i verden, inden loven kom, men den kunne ikke udpeges, så længe der ingen lov var. 14Døden herskede derfor også i verden, før loven kom, det vil sige fra Adam til Moses. Selv de, der ikke var ulydige mod Gud på samme direkte måde som Adam, måtte dø.

Adam kan sammenlignes med Jesus i den forstand, 15-16at ét menneskes handling har fået konsekvenser for hele menneskeheden. Men hvor ét menneskes ulydighed førte til død for et utal af mennesker, bragte ét andet menneskes lydighed Guds vældige kærlighed og nåde ud til et utal af mennesker. Efter at ét menneske havde forsyndet sig, måtte Gud afsige dommen over os mennesker og erklære os skyldige. Men efter at mange mennesker havde forsyndet sig, gav Jesus Kristus frivilligt sit liv for os, og derved kunne Gud erklære os skyldfri. 17Det var ét menneskes synd, som førte til, at døden fik herredømmet over menneskene. Men det var ét menneskes gave, som fører til, at livet får herredømmet over alle, som tager imod Guds overstrømmende nåde og tilgivelse i Jesus Kristus.

18Det vil altså sige, at ét menneskes forkerte handling førte til fordømmelse og død for alle mennesker. Men det var også ét menneskes rigtige handling, der førte til frikendelse og liv for alle mennesker. 19Ét menneskes ulydighed førte til, at mange andre gjorde oprør mod Gud. Men det er også ét menneskes lydighed, der fører til, at mange andre ønsker at gøre Guds vilje.

20Da loven kom til, voksede synden. Men da synden blev større, blev Guds nåde endnu større. 21Før havde synden herredømmet, og det førte til død. Men hos dem, som har opnået Guds tilgivelse, er det nåden, som har herredømmet, og det fører til det evige liv ved Jesus Kristus, vores Herre.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Romu 5:1-21

Àlàáfíà àti ayọ̀

15.1: Ro 3.28.Nítorí náà, níwọ̀n ìgbà tí a ti dá wa láre nípa ìgbàgbọ́, àwa ní àlàáfíà lọ́dọ̀ Ọlọ́run nípasẹ̀ Olúwa wa Jesu Kristi. 25.2: Ef 2.18; 3.12; Hb 10.19-20.Nípasẹ̀ ẹni tí àwa sì ti rí ọ̀nà gbà nípa ìgbàgbọ́ sí inú oore-ọ̀fẹ́ yìí nínú èyí tí àwa gbé dúró. Àwa sì ń yọ̀ nínú ìrètí ògo Ọlọ́run. 35.3: Ro 5.11; 2Kọ 12.10; Jk 1.3.Kì í sì ṣe bẹ́ẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n àwa tún ń ṣògo nínú ìjìyà pẹ̀lú: bí a ti mọ̀ pé ìjìyà ń ṣiṣẹ́ sùúrù; 4àti pé sùúrù ń ṣiṣẹ́ ìwà rere; àti pé ìwà rere ń ṣiṣẹ́ ìrètí: 55.5: Sm 119.116; Ap 2.33; Fp 1.20.Ìrètí kì í sì í dójúti ni nítorí a ti dá ìfẹ́ Ọlọ́run sí wa lọ́kàn láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ tí a fi fún wa.

6Nítorí ìgbà tí àwa jẹ́ aláìlera, ní àkókò tí ó yẹ, Kristi kú fún àwa aláìwà-bí-Ọlọ́run. 7Nítorí ó ṣọ̀wọ́n kí ẹnìkan tó kú fún olódodo: ṣùgbọ́n fún ènìyàn rere bóyá ẹlòmíràn tilẹ̀ lè dábàá láti kú. 85.8: Jh 15.13; Ro 8.32; 1Pt 3.18; 1Jh 3.16; 4.10.Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fi ìfẹ́ òun pàápàá sí wa hàn nínú èyí pé, nígbà tí àwa jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fún wa.

95.9: Ro 3.5,24-25; Ef 1.7; 1Tẹ 1.10.Mélòó mélòó sì ni tí a dá wa láre nísinsin yìí nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ni a ó gbà wá là kúrò nínú ìbínú nípasẹ̀ rẹ̀. 105.10: Kl 1.21.Ǹjẹ́, nígbà tí àwa wà ní ọ̀tá, a mú wa, ba Ọlọ́run làjà nípa ikú Ọmọ rẹ̀, mélòó mélòó, nígbà tí a là wá ní ìjà tan, ni a ó gbà wá là nípa ìyè rẹ̀. 115.11: Ro 5.3.Kì sì í ṣe bẹ́ẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n àwa ń ṣògo nínú Ọlọ́run nípa Olúwa wa Jesu Kristi, nípasẹ̀ ẹni tí àwa ti rí ìlàjà gbà nísinsin yìí.

Ikú nípasẹ̀ Adamu, iyè nípasẹ̀ Jesu

125.12: 1Kọ 15.21-22; Ro 6.23; Jk 1.15.Nítorí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ ti tipa ọ̀dọ̀ ènìyàn kan wọ ayé, àti ikú nípa ẹ̀ṣẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni ikú sì kọjá sórí ènìyàn gbogbo, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí gbogbo ènìyàn ti dẹ́ṣẹ̀:

13Nítorí kí òfin tó dé, ẹ̀ṣẹ̀ ti wà láyé; ṣùgbọ́n a kò ka ẹ̀ṣẹ̀ sí ni lọ́rùn nígbà tí òfin kò sí. 145.14: 1Kọ 15.22,45.Ṣùgbọ́n ikú jẹ ọba láti ìgbà Adamu wá títí fi di ìgbà ti Mose, àti lórí àwọn tí ẹ̀ṣẹ̀ wọn kò dàbí irú ìrékọjá Adamu, ẹni tí í ṣe àpẹẹrẹ ẹni tí ń bọ̀.

155.15: Ap 15.11.Ṣùgbọ́n ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ kò dàbí ẹ̀ṣẹ̀. Nítorí bí nípa ẹ̀ṣẹ̀. Nítorí bí o bá jẹ pé ẹnìkan ẹni púpọ̀ kú, mélòó mélòó ni oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, àti ẹ̀bùn nínú oore-ọ̀fẹ́ ọkùnrin kan, Jesu Kristi, di púpọ̀ fún ẹni púpọ̀. 165.16: Ro 8.1.Kì í ṣe nípa ẹnìkan tí ó sẹ̀ ni ẹ̀bùn náà: Nítorí ìdájọ́ ti ipasẹ̀ ẹnìkan wá fún ìdálẹ́bi, ṣùgbọ́n ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ ti inú ẹ̀ṣẹ̀ púpọ̀ wá fún ìdáláre, 17Ǹjẹ́ bí o bá jẹ pé nípa ẹ̀ṣẹ̀ ọkùnrin kan, ikú jẹ ọba nípasẹ̀ ẹnìkan náà; mélòó mélòó ni àwọn tí ń gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ oore-ọ̀fẹ́ àti ẹ̀bùn òdodo yóò jẹ ọba nínú ìyè nípasẹ̀ ẹnìkan, Jesu Kristi.

18Ǹjẹ́ bí o bá jẹ pé nípa ẹ̀ṣẹ̀ ẹnìkan ìdájọ́ dé bá gbogbo ènìyàn sí ìdálẹ́bi; gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni nípa ìwà òdodo ẹnìkan, ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ dé sórí gbogbo ènìyàn fún ìdáláre sí ìyè. 195.19: Fp 2.8.Nítorí gẹ́gẹ́ bí nípa àìgbọ́ràn ọkùnrin kan, ènìyàn púpọ̀ di ẹlẹ́ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni nípa ìgbọ́ràn ẹnìkan, a ó sọ ènìyàn púpọ̀ di olódodo.

205.20: Ro 7.7-8; Ga 3.19; 1Tm 1.14.Ṣùgbọ́n òfin bọ́ sí inú rẹ̀, kí ẹ̀ṣẹ̀ lè di púpọ̀, ṣùgbọ́n ni ibi ti ẹ̀ṣẹ̀ di púpọ̀, oore-ọ̀fẹ́ di púpọ̀ rékọjá. 215.21: Ro 6.23.Pé, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ ti jẹ ọba nípa ikú bẹ́ẹ̀ ni kí oore-ọ̀fẹ́ sì lè jẹ ọba nípa òdodo títí ìyè àìnípẹ̀kun nípasẹ̀ Jesu Kristi Olúwa wa.