Josvabogen 13 – BPH & YCB

Bibelen på hverdagsdansk

Josvabogen 13:1-33

Områder, der endnu ikke er erobret

1Da Josva var blevet gammel, sagde Herren til ham: „Du er langt oppe i årene, men der er endnu meget land at indtage. 2Det drejer sig om filistrenes og geshuritternes landområder. 3I det sydlige Kana’an drejer det sig om området, der går fra den mudrede13,3 På hebraisk: shihor. Der refereres her til den wadi, der også kaldes Egyptens Bæk, en flod, der tørrer ud i tørtiden. wadi på grænsen til Egypten, op til Ekron mod nord med de fem filisterbyer: Gaza, Ashdod, Ashkalon, Gat og Ekron (der hvor avvitterne engang boede). 4I det nordlige Kana’an er det de øde områder, der hører under Sidon, fra Afek til den amoritiske grænse. 5Desuden er der gebalitternes område langs kysten mod nord og området øst for Libanons bjerge fra Ba’al-Gad neden for Hermonbjerget i syd til Lebo-Hamat i nord, 6-7samt alle dem, der bor vest for Libanons bjerge og ud til Misrefot-Majim ved kysten, det er sidonierne. Jeg er parat til selv at drive dem bort foran jer. Derfor skal du medregne hele området, når du fordeler landet mellem de ni stammer og Manasses halve stamme, sådan som jeg har befalet.”

Fordelingen af landet øst for Jordanfloden

8Den ene halvdel af Manasses stamme samt Rubens og Gads stamme havde allerede af Moses fået tildelt deres arvelod på den østlige side af Jordanfloden. 9Deres område indbefattede Medeba højsletten ned til Dibon og byen Aroer på toppen af skrænten ved Arnonfloden, samt byen nede i floddalen. 10Det indeholdt også de øvrige byer, som tidligere hørte under amoritterkongen Sihon af Heshbon, ud til Ammons grænse. 11Området indbefattede også Gilead, geshuritternes og ma’akatitternes land, hele Hermonbjerget, hele Bashan så langt som til byen Salka 12og alt det land, som tidligere hørte under kong Og af Bashan, der regerede fra Ashtarot og Edrei. Kong Og var en af de sidste refaitter. Det var i Moses’ tid, de blev angrebet og drevet bort. 13Men israelitterne var ikke i stand til at fordrive geshuritterne og ma’akatitterne, og derfor bor de endnu i dag iblandt dem.

Levis arvelod

14Moses tildelte ikke levitterne nogen jord, for Herren havde lovet at sørge for dem, at de måtte få del i det, der blev ofret til Herren, Israels Gud.

Rubens arvelod

15Moses tildelte klanerne fra Rubens stamme 16Medeba højsletten ned til Aroer og byen nede i Arnondalen. 17Deres område indbefattede Heshbon og de andre byer på højsletten: Dibon, Bamot-Ba’al, Bet-Ba’al-Meon, 18Jahatz, Kedemot, Mefa’at, 19Kirjatajim, Sibma, Seret-ha-Shahar på bjerget over dalen, 20Bet-Peor, Bet-ha-Jeshimot og Pisgabjergets skråninger.

21Rubens arvelod indbefattede hele det landområde, kong Sihon havde regeret over med alle byer og landsbyer. Sihon var den amoritiske konge, som regerede fra Heshbon, og som blev dræbt af Moses sammen med de midjanitiske høvdinge Evi, Rekem, Zur, Hur og Reba, der alle var underlagt kong Sihon. 22Israelitterne dræbte ved den lejlighed også spåmanden Bileam, Beors søn. 23Jordanfloden og Det Døde Hav udgjorde den vestlige grænse for det land, der blev tildelt Rubens stamme.

Gads arvelod

24Moses tildelte følgende områder til klanerne i Gads stamme: 25Højsletterne med Jazer, alle Gileads byer og halvdelen af ammonitternes land indtil Aroer ved Rabba mod øst, 26området fra Heshbon mod syd til Ramat-ha-Mitzpe og Betonim, og op til Mahanajim og Lodebar mod nord. 27-28I Jordandalen var der byerne Bet-Haram, Bet-Nimra, Sukkot, Zafon og resten af kong Sihon af Heshbons rige. Jordanfloden dannede grænse mod vest helt op til Galilæasøen.

Manasses halve stammes arvelod

29Moses tildelte følgende område til klanerne fra Manasses halve stamme: 30Deres territorium strakte sig nordpå fra Mahanajim og indbefattede hele Bashan, hele kong Ogs tidligere rige, og Jairs 60 landsbyer i Bashan, 31desuden det halve Gilead samt kong Ogs residensbyer, Ashtarot og Edrei. Det blev alt sammen givet til efterkommere af Makir, Manasses søn.

32Sådan fordelte Moses moabitternes land øst for Jordanfloden over for Jeriko, hvor folket i sin tid slog lejr. 33Men Levis stamme gav han ingen jord, for Herren, Israels Gud, skulle være deres arvelod. Herren selv havde lovet at sørge for dem.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Joṣua 13:1-33

Ilẹ̀ tí ó kù láti gbà

1Nígbà tí Joṣua sì darúgbó tí ọjọ́ orí rẹ̀ sì pọ̀ jọjọ, Olúwa sọ fún un pé, “Ìwọ ti darúgbó púpọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ilẹ̀ sì kù lọ́pọ̀lọpọ̀ fún yín láti gbà.

2“Èyí ni ilẹ̀ tí ó kù:

“gbogbo àwọn agbègbè àwọn Filistini, àti ti ara Geṣuri: 3láti odò Ṣihori ní ìlà-oòrùn Ejibiti sí agbègbè Ekroni ìhà àríwá, gbogbo rẹ̀ ni a kà kún Kenaani (agbègbè ìjòyè Filistini márùn-ún ní Gasa, Aṣdodu, Aṣkeloni, Gitti àti Ekroni;

ti àwọn ará Affimu); 4láti gúúsù;

gbogbo ilẹ̀ àwọn ará Kenaani, láti Arah ti àwọn ará Sidoni títí ó fi dé Afeki, agbègbè àwọn ará Amori;

5Àti ilẹ̀ àwọn ará Gebali;

àti gbogbo àwọn Lebanoni dé ìlà-oòrùn, láti Baali-Gadi ní ìsàlẹ̀ Òkè Hermoni dé Lebo-Hamati.

6“Ní ti gbogbo àwọn olùgbé agbègbè òkè, láti Lebanoni sí Misrefoti-Maimu, àní, gbogbo àwọn ará Sidoni, èmi fúnra mi ní yóò lé wọn jáde ní iwájú àwọn ará Israẹli. Kí o ri dájú pé o pín ilẹ̀ yí fún Israẹli ní ilẹ̀ ìní, gẹ́gẹ́ bí mo ṣe fi àṣẹ fún ọ, 7pín ilẹ̀ yìí ní ilẹ̀ ìní fún àwọn ẹ̀yà mẹ́sàn-án àti ìdajì ẹ̀yà Manase.”

Pínpín ilẹ̀ ìhà ìlà-oòrùn Jordani

8Àwọn ìdajì ẹ̀yà Manase tí ó kù, àti àwọn Reubeni àti àwọn Gadi ti gba ilẹ̀ ìní, tí Mose ti fún wọn ní ìhà ìlà-oòrùn Jordani bí Mose ìránṣẹ́ Olúwa ti fi fún wọn.

9Ó sì lọ títí láti Aroeri tí ń bẹ létí Àfonífojì Arnoni, àti láti ìlú náà tí ń bẹ ní àárín Àfonífojì náà, àti pẹ̀lú gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ Medeba títí dé Diboni. 10Gbogbo ìlú Sihoni ọba àwọn Amori, tí ó ṣe àkóso ní Heṣboni, títí dé ààlà àwọn ará Ammoni.

11Àti Gileadi, ní agbègbè àwọn ènìyàn Geṣuri àti Maakati, gbogbo Òkè Hermoni àti gbogbo Baṣani títí dé Saleka, 12Ìyẹn, gbogbo ilẹ̀ ọba Ogu ní Baṣani, tí ó jẹ ọba ní Aṣtarotu àti Edrei, ẹni tí ó kù nínú àwọn Refaimu ìyókù. Mose ti ṣẹ́gun wọn, ó sì ti gba ilẹ̀ wọn. 13Ṣùgbọ́n àwọn ará Israẹli kò lé àwọn ará Geṣuri àti Maakati jáde, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń gbé ní àárín àwọn ará Israẹli títí di òní yìí.

14Ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀yà Lefi ni kò fi ogún kankan fún, níwọ̀n ìgbà tí ó ti jẹ́ pé ọrẹ àfinásun sí Olúwa Ọlọ́run Israẹli ni ogún tiwọn, gẹ́gẹ́ bí o ti ṣèlérí fún wọn.

15Èyí ni Mose fi fún ẹ̀yà Reubeni ni agbo ilé sí agbo ilé:

16Láti agbègbè Aroeri ní etí Arnoni Jọ́ọ́jì àti láti ìlú tí ń bẹ láàrín Jọ́ọ́jì, àti gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ ní ìkọjá Medeba 17sí Heṣboni àti gbogbo ìlú rẹ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, pẹ̀lú Diboni, Bamoti Baali, Beti-Baali-Mioni, 18Jahisa, Kedemoti, Mefaati, 19Kiriataimu, Sibma, Sereti Ṣahari lórí òkè ní àfonífojì. 20Beti-Peori, gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Pisga, àti Beti-Jeṣimoti 21gbogbo ìlú tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ àti gbogbo agbègbè Sihoni ọba Amori, tí ó ṣe àkóso Heṣboni. Mose sì ti ṣẹ́gun rẹ̀ àti àwọn ọmọ ìjòyè Midiani, Efi, Rekemu, Suri, Huri àti Reba, àwọn ọmọ ọba pawọ́pọ̀ pẹ̀lú Sihoni tí ó gbé ilẹ̀ náà. 22Ní àfikún àwọn tí a pa ní ogun, àwọn ọmọ Israẹli fi idà pa Balaamu ọmọ Beori alásọtẹ́lẹ̀.

23Ààlà àwọn ọmọ Reubeni ni etí odò Jordani. Àwọn ìlú wọ̀nyí àti abúlé rẹ̀ ni ilẹ̀ ìní àwọn ọmọ Reubeni ní agbo ilé ní agbo ilé.

24Èyí ni ohun tí Mose ti fi fún ẹ̀yà Gadi, ní agbo ilé ní agbo ilé:

25Agbègbè ìlú Jaseri, gbogbo ìlú Gileadi àti ìdajì orílẹ̀-èdè àwọn ọmọ ará Ammoni títí dé Aroeri, ní ẹ̀bá Rabba; 26àti láti Heṣboni lọ sí Ramati-Mispa àti Betonimu, àti láti Mahanaimu sí agbègbè ìlú Debiri, 27àti ní Àfonífojì Beti-Haramu, Beti-Nimra, Sukkoti àti Safoni pẹ̀lú ìyókù agbègbè ilẹ̀ Sihoni ọba Heṣboni (ní ìhà ìlà-oòrùn Jordani, agbègbè rẹ̀ títí dé òpin Òkun Kinnereti).

28Àwọn ìlú wọ̀nyí àti abúlé rẹ̀ jẹ́ ogún àwọn ọmọ Gadi, ní agbo ilé ní agbo ilé.

29Èyí ni ohun tí Mose ti fi fún ìdajì ẹ̀yà Manase, èyí ni pé, fún ìdajì ìdílé irú-ọmọ Manase, ní agbo ilé ní agbo ilé:

30Ilẹ̀ náà fẹ̀ dé Mahanaimu àti gbogbo Baṣani, gbogbo agbègbè ilẹ̀ Ogu ọba Baṣani, èyí tí í ṣe ibùgbé Jairi ní Baṣani, ọgọ́ta ìlú, 31ìdajì Gileadi, àti Aṣtarotu àti Edrei (àwọn ìlú ọba Ogu ní Baṣani).

Èyí ni fún irú àwọn ọmọ Makiri ọmọ Manase fún ààbọ̀ àwọn ọmọ Makiri, ní agbo ilé ní agbo ilé.

32Èyí ni ogún tí Mose fi fún wọn nígbà tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu ní ìhà kejì Jordani ní ìlà-oòrùn Jeriko. 33Ṣùgbọ́n fún ẹ̀yà Lefi, Mose kò fi ogún fún un; Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, ní ogún wọn, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ìlérí fún wọn.