Esajasʼ Bog 22 – BPH & YCB

Bibelen på hverdagsdansk

Esajasʼ Bog 22:1-25

Et budskab om Jerusalems fald

1Et budskab om Zions dal:22,1 Efter LXX. Den hebraiske tekst, vi bruger, siger „Synets dal” her og i vers 5. Der er tale om Jerusalem.

Hvorfor samles folk på hustagene? 2Hvorfor er der fest og ballade i byen?22,2 Teksten er uklar.

De, som før eller siden døde, blev ikke dræbt med sværd eller fældet i kamp. 3Alle lederne flygtede, men blev fanget uden at gøre modstand. Alle, som blev i byen, blev taget til fange, selv om de ønskede at flygte langt væk.

4Derfor sagde jeg: „Lad mig være i fred med mine bitre tårer. Prøv ikke at trøste mig, men lad mig græde over mit folks undergang.” 5Herren, den Almægtige, har beredt en frygtelig trængselsdag for dem i Zions dal. Jerusalems mur brydes ned, og der lyder råb mod bjerget22,5 Sikkert Zions bjerg, hvor templet stod. om hjælp. 6Der er bueskytter fra Elam, kavaleri fra Aram og fodfolk fra Kir med løftede skjolde. 7De dejlige dale fyldes med stridsvogne, og rytterne presser sig på ved portene. 8Men Judas skæbne blev afgjort allerede dengang, I løb til det kongelige rustkammer efter våben. 9-11I så, at Jerusalems mur var fuld af revner. I undersøgte husene og rev nogle af dem ned for at få sten til at udbedre muren. I samlede vand i den nedre dam mellem de to mure ved at udgrave den gamle dam. Men I satte ikke jeres lid til Herren, som skabte det alt sammen, ham, som står bag det hele.

12Herren, den Almægtige, kaldte jer til at græde og sørge. Han bad jer rage håret af som tegn på, at I sørgede over jeres synder, og til at klæde jer i sæk og aske for at vise jeres anger. 13Men I holdt gilde og morede jer, I sang, dansede og lo, I slagtede okser og får, spiste kød og drak vin. „Lad os spise og drikke,” råbte I, „for I morgen skal vi dø!” 14Men Herren, den Almægtige, har fortalt mig, at den synd ikke skal tilgives jer, så længe I lever. Det er Herrens egne ord.

En advarsel til Shebna og senere Eljakim

15Herren, den Almægtige, sendte mig til kongens slotsforvalter, Shebna, med følgende besked:

16„Hvem tror du, du er? Hvorfor udhugger du dig et fornemt gravkammer her i byen, en smuk bolig højt oppe på klippevæggen? 17Herren vil slynge dig langt bort, du stolte mand. 18Han vil rulle dig sammen som en bold og kaste dig bort til et vidtstrakt land. Både du og dine smukke vogne skal føres bort, og du skal dø i det fremmede, for du har bragt skam over din herre. 19Men først vil jeg tage din stilling fra dig 20og i stedet udnævne min tjener Eljakim, Hilkijas søn, som din efterfølger. 21Han skal overtage din embedsdragt, din titel og din autoritet. Han vil være en omsorgsfuld far for Jerusalem og Judas folk. 22Jeg gør ham til kongens øverste embedsmand. Hans ord skal være lov, og ingen vil turde modsætte sig hans vilje. 23-24Jeg slår hans myndighed fast som et syvtommersøm i en solid mur. Fordi han lever op til sit ansvar, vil folk have stor respekt for ham og hans familie.”

25„Men engang vil selv det syvtommersøm blive revet løs,” siger Herren, den Almægtige. „Selv om det var banket godt fast i den solide mur, vil det blive revet ud af muren og falde til jorden. Og alt, hvad der var afhængigt af det søm, vil falde til jorden og blive knust.” Det er Herrens ord.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Isaiah 22:1-25

Àsọtẹ́lẹ̀ kan nípa Jerusalẹmu

1Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó jẹ mọ́ Àfonífojì ìran:

Kí ni ó ń dààmú yín báyìí,

tí gbogbo yín fi gun orí òrùlé lọ?

2Ìwọ ìlú tí ó kún fún rúkèrúdò,

ìwọ ìlú àìtòrò òun rògbòdìyàn

a kò fi idà pa àwọn òkú rẹ,

bẹ́ẹ̀ ni wọn kò kú ní ojú ogun.

3Gbogbo àwọn olórí i yín ti jùmọ̀ sálọ;

a ti kó wọn nígbèkùn láìlo ọfà.

Ẹ̀yin tí a mú ni a ti kó lẹ́rú papọ̀,

lẹ́yìn tí ẹ ti sá nígbà tí ọ̀tá ṣì wà

lọ́nà jíjìn réré.

4Nítorí náà ni mo wí pé, “Yípadà kúrò lọ́dọ̀ mi:

jẹ́ kí n sọkún kíkorò.

Má ṣe gbìyànjú àti tù mí nínú

nítorí ìparun àwọn ènìyàn mi.”

5Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ní ọjọ́ kan

tí rúkèrúdò, rògbòdìyàn àti ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀

ní Àfonífojì ìmọ̀,

ọjọ́ tí a ń wó ògiri lulẹ̀

àti sísun ẹkún lọ sí àwọn orí òkè.

6Elamu mú apó-ọfà lọ́wọ́,

pẹ̀lú àwọn agun-kẹ̀kẹ́-ogun àti àwọn ẹṣin,

Kiri yọ àpáta rẹ̀ síta.

7Àyànfẹ́ Àfonífojì rẹ kún fún kẹ̀kẹ́ ogun,

àwọn ẹlẹ́ṣin ni a gbá jọ sí ẹnu-bodè ìlú.

8Gbogbo ààbò Juda ni a ti ká kúrò.

Ìwọ sì gbójú sókè ní ọjọ́ náà

sí àwọn ohun ìjà ní ààfin ti inú aginjù,

9Ìwọ rí i pé ìlú u Dafidi

ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ààyè níbi ààbò rẹ̀,

ìwọ ti tọ́jú omi

sínú adágún ti ìsàlẹ̀.

10Ìwọ ka àwọn ilé tí ó wà ní Jerusalẹmu

ó sì wó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé lulẹ̀ láti fún ògiri lágbára.

11Ìwọ mọ agbemi sí àárín ògiri méjì

fún omi inú adágún àtijọ́,

ṣùgbọ́n ìwọ kò wo ẹni tí ó ṣe é tẹ́lẹ̀

tàbí kí o kọbi ara sí ẹni tí ó

gbèrò rẹ̀ ní ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn.

12Olúwa, àní Olúwa àwọn ọmọ-ogun,

pè ọ́ ní ọjọ́ náà

láti sọkún kí o sì pohùnréré,

kí o tu irun rẹ dànù kí o sì

da aṣọ ọ̀fọ̀ bora.

13Ṣùgbọ́n Wò ó, ayọ̀ àti ayẹyẹ wà

màlúù pípa àti àgùntàn pípa,

ẹran jíjẹ àti ọtí wáìnì mímu!

“Jẹ́ kí a jẹ kí a mu,” ni ẹ̀yin wí,

“nítorí pé lọ́la àwa ó kú!”

14Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti sọ èyí di mí mọ̀ létí ì mi: “Títí di ọjọ́ ikú yín a kò ní ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ yìí,” ni Olúwa wí, àní Olúwa àwọn ọmọ-ogun.

15Èyí ni ohun tí Olúwa, àní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí:

Lọ, sọ fún ìríjú yìí pé,

fún Ṣebna, ẹni tí ààfin wà ní ìkáwọ́ rẹ̀:

16Kí ni ohun tí ò ń ṣe níhìn-ín-yìí àti pé

ta ni ó sì fún ọ ní àṣẹ

láti gbẹ́ ibojì kan fún ara rẹ níhìn-ín-yìí,

tí ó gbẹ́ ibojì ní ibi gíga

tí ó sì gbẹ́ ibi ìsinmi rẹ nínú àpáta?

17“Kíyèsára, Olúwa fẹ́ gbá ọ mú gírígírí

kí ó sì jù ọ́ nù, Ìwọ ọkùnrin alágbára.

18Òun yóò ká ọ rúgúdù bí i òkìtì

yóò sì sọ ọ́ sí orílẹ̀-èdè ńlá kan.

Níbẹ̀ ni ìwọ yóò sì kú sí

àti níbẹ̀ pẹ̀lú ni àwọn kẹ̀kẹ́ ogun

àràmọ̀ǹdà rẹ yóò wà—

ìwọ di ìtìjú sí ilé ọ̀gá rẹ!

19Èmi yóò yọ ọ́ kúrò ní ipò rẹ,

a ó sì lé ọ kúrò ní ipò rẹ.

20“Ní ọjọ́ náà. Èmi yóò ké sí ọmọ ọ̀dọ̀ mi, Eliakimu ọmọ Hilkiah. 21Èmi yóò fi aṣọ rẹ wọ̀ ọ́, n ó sì so ẹ̀wọ̀n rẹ mọ́ ọn ní ọrùn, èmi ó sì gbé àṣẹ rẹ lé e lọ́wọ́. Òun yó sì jẹ́ baba fún gbogbo olùgbé e Jerusalẹmu àti fún ilé e Juda. 2222.22: If 3.7.Èmi yóò sì fi kọ́kọ́rọ́ ilé e Dafidi lé e ní èjìká; ohunkóhun tí ó bá ṣí, ẹnikẹ́ni kì yóò lè ti, ohunkóhun tí ó bá sì tì, ẹnikẹ́ni kì yóò le è ṣí. 23Èmi yóò sì kàn mọ́lẹ̀ bí èèkàn tí ó dúró gírígírí ní ààyè e rẹ̀; òun yóò sì jẹ́ ibùjókòó ọlá fún ilé baba rẹ̀. 24Gbogbo ògo ìdílé rẹ̀ ni wọn yóò sì fi kọ ní ọrùn: ìran rẹ̀ àti àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀, gbogbo ohun èlò ife, títí dé orí ago ọtí.

25“Ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “Èèkàn tí a kàn mọ́lẹ̀ gírígírí ní ààyè e rẹ̀ yóò yẹrí, yóò dẹ̀gbẹ́ yóò sì fẹ̀gbẹ́ lélẹ̀ àti ẹrù tí ó létéńté lórí i rẹ̀ ni a ó gé lulẹ̀.” Olúwa ni ó ti sọ ọ́.