Esajasʼ Bog 11 – BPH & YCB

Bibelen på hverdagsdansk

Esajasʼ Bog 11:1-16

Rodskuddet fra Isajs stub

1Der vil komme et rodskud fra Isajs stub, et nyt skud på Davids stamtræ. 2Herrens Ånd hviler over ham og giver ham visdom, indsigt, karakterstyrke, kundskab og gudsfrygt. 3Han lever og ånder for at gøre Herrens vilje. Han bedømmer aldrig en sag blot på grundlag af, hvad han ser og hører. 4Han forsvarer fattiges rettigheder og dømmer de svage retfærdigt. Han sætter voldsmænd til vægs med et visdomsord, tilintetgør de onde med et åndepust. 5Han bærer ret adfærd som bælte om sit liv, klæder sig i trofasthed og sandhed.

6Engang vil ulven og lammet følges ad, leoparden hvile sig hos gedekiddet, kalven og løven græsse sammen, så et barn kan passe dem. 7Køer og bjørne vil blive venner, så deres unger ligger side om side. Løven vil æde græs som oksen. 8Spædbørn kan lege ved slangens hule, og småbørn kan uskadt stikke hånden i hugormens rede. 9Ingen gør fortræd i hele mit hellige bjergland, for alverden skal fyldes af en dyb forståelse af Herren, som vandet fylder verdenshavene.

10Engang vil Isajs rodskud stå som et banner og kalde på alle folkeslagene. Menneskene vil søge svar hos ham, og hans bolig bliver herlig. 11Da vil Herren igen række hånden ud for at hjemkalde den rest, der er tilbage af hans folk, og de skal komme fra Assyrien, fra nedre og øvre Egypten, Kush, Elam, Babylonien, Hamat og fjerne kyster. 12Herren kalder på folkeslagene med sit banner, og han samler Israels og Judas bortdrevne og adspredte folk fra de fire verdenshjørner. 13Da skal fjendskabet mellem Israel og Juda høre op, og de skal ikke længere bekrige hinanden. 14I stedet angriber de i fællesskab filistrene i vest og tager bytte fra folkene i øst. De erobrer Edom og Moab, og gør ammonitterne til deres undersåtter.

15Herren baner en vej gennem Egyptens Hav. Han hæver sin hånd over Eufratfloden og lader en mægtig vind dele den i syv bække, som man let kan komme over. 16Der bliver en banet vej for den rest af hans folk, der er tilbage i Assyrien, ligesom der blev for Israel, da de drog op fra Egypten.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Isaiah 11:1-16

Ẹ̀ka láti ọ̀dọ̀ Jese

111.1: Isa 11.10; Ro 15.12.Èèkàn kan yóò sọ láti ibi

kùkùté Jese,

láti ara gbòǹgbò rẹ̀ ni ẹ̀ka kan

yóò ti so èso.

211.2: 1Pt 4.14.Ẹ̀mí Olúwa yóò sì bà lé e

ẹ̀mí ọgbọ́n àti ti òye

ẹ̀mí ìmọ̀ràn àti ti agbára

ẹ̀mí ìmọ̀ àti ti ìbẹ̀rù Olúwa

3Òun yóò sì ní inú dídùn nínú ìbẹ̀rù Olúwa.

Òun kì yóò ṣe ìdájọ́ pẹ̀lú ohun tí ó fi ojú u rẹ̀ rí,

tàbí pẹ̀lú ohun tí ó fi etí i rẹ̀ gbọ́,

4Ṣùgbọ́n pẹ̀lú òdodo ni yóò ṣe ìdájọ́ àwọn aláìní,

pẹ̀lú òtítọ́ ni yóò ṣe ìpinnu

fún àwọn aláìní ayé.

Òun yóò lu ayé pẹ̀lú ọ̀pá tí ó wà ní ẹnu rẹ̀,

pẹ̀lú èémí ẹnu rẹ̀ ni yóò pa àwọn ìkà.

511.5: Ef 6.14.Òdodo ni yóò jẹ́ ìgbànú rẹ̀

àti òtítọ́ ni yóò ṣe ọ̀já yí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ká.

611.6-9: Isa 65.25; Hk 2.14.Ìkookò yóò sì máa bá ọmọ àgùntàn gbé,

ẹkùn yóò sì sùn ti ewúrẹ́

ọmọ màlúù òun ọmọ kìnnìún

àti ọmọ ẹran ó wà papọ̀

ọ̀dọ́mọdé yóò sì máa dà wọ́n.

7Màlúù àti beari yóò máa jẹun pọ̀,

àwọn ọmọ wọn yóò dùbúlẹ̀ pọ̀,

kìnnìún yóò sì máa jẹ koríko

gẹ́gẹ́ bí akọ màlúù.

8Ọ̀dọ́mọdé yóò ṣeré lẹ́bàá ihò ọká,

ọmọdé yóò ki ọwọ́ rẹ̀ bọ ìtẹ́ paramọ́lẹ̀.

9Wọn kò ní ṣe ni léṣe tàbí pa ni run

ní gbogbo òkè mímọ́ mi,

nítorí gbogbo ayé yóò kún fún ìmọ̀ Olúwa

gẹ́gẹ́ bí omi ti bo Òkun.

1011.10: Isa 11.1; Ro 15.12.Ní ọjọ́ náà, gbòǹgbò Jese yóò dúró gẹ́gẹ́ bí àsíá fún gbogbo ènìyàn, àwọn orílẹ̀-èdè yóò pagbo yí i ká, ibùdó ìsinmi rẹ̀ yóò jẹ́ èyí tí ó lógo. 11Ní ọjọ́ náà, Olúwa yóò na ọwọ́ rẹ̀ jáde nígbà kejì láti tún gba àwọn tí ó ṣẹ́kù àní àwọn tí a ṣẹ́kù nínú àwọn ènìyàn an rẹ̀ láti Asiria wá, láti ìsàlẹ̀ Ejibiti àti Òkè Ejibiti, láti Kuṣi, láti Elamu láti Babiloni, láti Hamati àti láti àwọn erékùṣù inú Òkun.

12Òun yóò gbé àsíá sókè fún àwọn orílẹ̀-èdè,

yóò sì kó àwọn ìgbèkùn Israẹli jọ,

yóò kó gbogbo àwọn ènìyàn Juda tí a ti fọ́n káàkiri jọ,

láti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ ayé.

13Owú jíjẹ Efraimu yóò pòórá,

àwọn ọ̀tá Juda ni a ó ké kúrò,

Efraimu kò ní jowú Juda,

tàbí Juda kó dojúkọ Efraimu.

14Wọn yóò fò mọ́ èjìká Filistini

sí apá ìwọ̀-oòrùn,

wọn yóò pawọ́pọ̀ kọlu àwọn

ènìyàn apá ìlà-oòrùn.

Wọn yóò gbé ọwọ́ wọn lé Edomu àti Moabu,

àwọn ará Ammoni yóò sì di ìwẹ̀fà wọn.

15Olúwa yóò sọ di gbígbé

àyasí Òkun Ejibiti,

pẹ̀lú atẹ́gùn gbígbóná ni yóò na ọwọ́ rẹ̀,

kọjá lórí odò Eufurate.

Òun yóò sì sọ ọ́ di ọmọdò méje

tó fi jẹ́ pé àwọn ènìyàn

yóò máa là á kọjá pẹ̀lú bàtà.

16Ọ̀nà gidi yóò wà fún àwọn ènìyàn an rẹ̀ tí ó ṣẹ́kù

tí ó kù sílẹ̀ ní Asiria,

gẹ́gẹ́ bí ó ti wà fún Israẹli

nígbà tí wọ́n gòkè láti Ejibiti wá.