Amosʼ Bog 6 – BPH & YCB

Bibelen på hverdagsdansk

Amosʼ Bog 6:1-14

1Ve jer, der tager den med ro i Jerusalem og lever sorgløst i Samaria. I betragter jer selv som de bedste ledere i det bedste land, og Israels folk kommer til jer for at få råd og hjælp. 2Men tænk på, hvordan det er gået Kalno6,2 Eller: „Kalne”, se Es. 10,9. og den tidligere storby Hamat. Og hvad med filisterbyen Gat? Når de blev lagt i ruiner, hvad så med jer? Er jeres byer og lande bedre end deres? 3I tror, at dommen er langt borte, men jeres handlinger bringer den tæt på.

4I nyder livet henslængt på jeres elfenbensudsmykkede senge og divaner. I frådser i fede lamme- og kalvestege, 5mens I synger viser og spiller på lyrer fra Davids tid. 6I drikker vin af de hellige offerskåle og bruger de bedste aromatiske olier på jer selv i stedet for at faste og sørge over Israels forfald. 7Derfor skal I blive de første, som føres i eksil. Jeres lystige fester får en brat ende.

8Herren, den almægtige Gud, har svoret ved sig selv: „Jeg hader Israels hovmod og foragter deres paladser. Derfor overgiver jeg deres by med alle dens indbyggere i fjendens hånd.”

9Om så ti mænd skjuler sig i et hus, skal de alle dø. 10Hvis en slægtning kommer for at hente de døde i huset og begrave dem, råber han måske ind i huset, om der er flere tilbage. Hvis svaret er: „Nej!” vil han sige: „Pas på, nævn ikke Herrens navn, for at han ikke skal høre dig!” 11For når først Herren har afsagt sin dom, skal både små og store huse jævnes med jorden.

12Lader man heste galopere på klipper? Lader man okser pløje havet? Men I har stik imod al fornuft vendt retten til uret og erstattet det gode med det onde. 13I praler over at have besejret de magtesløse og er stolte over, hvad I har kunnet udrette i egen kraft.

14„Åh, Israels folk,” siger Herren, den almægtige Gud. „Jeg sender et fremmed folk imod jer. De vil hærge jeres land fra Lebo-Hamat i nord til Arabadalen mod syd.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Amosi 6:1-14

Ègbé ni fún àwọn tí ara rọ̀

1Ègbé ni fún ẹ̀yin tí ará rọ̀ ní Sioni

àti ẹ̀yin tí ẹ wà ní abẹ́ ààbò ní òkè Samaria

àti ẹ̀yin olókìkí orílẹ̀-èdè

tí ẹ̀yin ènìyàn Israẹli máa ń tọ̀ ọ́ wá

2Ẹ lọ Kalne kí ẹ lọ wò ó

kí ẹ sí tí ibẹ̀ lọ sí Hamati ìlú ńlá a nì.

Kí ẹ sì tún sọ̀kalẹ̀ lọ Gati ní ilẹ̀ Filistini

Ǹjẹ́ wọ́n ha dára ju ìpínlẹ̀ yín méjèèjì lọ?

Ǹjẹ́ a ha rí ilẹ̀ tó tóbi ju tiyín lọ bí?

3Ẹ̀yin sún ọjọ́ ibi síwájú,

ẹ sì mú ìjọba òǹrorò súnmọ́ tòsí

4Ẹ̀yin sùn lé ibùsùn tí a fi eyín erin ṣe

ẹ sì tẹ́ ara sílẹ̀ ni orí àwọn ibùsùn

ẹyin pa èyí tí o dára nínú àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn yín jẹ

ẹ sì ń pa àwọn ọ̀dọ́ màlúù láàrín agbo wọn jẹ

5Ẹ̀yin ń lo ohun èlò orin bí i Dafidi

ẹ sì ń ṣe àwọn àpilẹ̀rọ àwọn ohun èlò orin

6Ẹ̀yin mu wáìnì ẹ̀kún ọpọ́n kan

àti ìkunra tí o dára jùlọ

ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò káàánú ilé Josẹfu tí ó di ahoro

7Nítorí náà, àwọn ni yóò lọ sí ìgbèkùn

pẹ̀lú àwọn tí ó ti kó lọ sí ìgbèkùn

àsè àwọn tí ń ṣe àṣelékè ni a ó mú kúrò.

Olúwa Kórìíra Ìgbéraga Ọmọ Israẹli

8Olúwa Olódùmarè ti búra fúnrarẹ̀, Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun sì ti wí pé:

“Mo kórìíra ìgbéraga Jakọbu

n kò sì ní inú dídùn sí odi alágbára rẹ̀

Èmi yóò sì fa ìlú náà lé wọn lọ́wọ́

àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀.”

9Bí Ọkùnrin mẹ́wàá bá ṣẹ́kù nínú ilé kan, àwọn náà yóò kú 10Bí ẹbí tí ó yẹ kí ó gbé òkú wọn jáde fún sínsin bá wọlé, bí o ba sì béèrè pé ǹjẹ́ ẹnìkan wa tí ó fi ara pamọ́ níbẹ̀, “Ǹjẹ́ ẹnìkankan wà lọ́dọ̀ yín?” tí ó bá sì dáhùn wí pé, “Rárá,” nígbà náà ni yóò wí pé, “Pa ẹnu rẹ mọ́ àwa kò gbọdọ̀ dárúkọ Olúwa.”

11Nítorí Olúwa tí pa àṣẹ náà,

Òun yóò sì wó ilé ńlá náà lulẹ̀ túútúú

Àti àwọn ilé kéékèèkéé sí wẹ́wẹ́.

12Ǹjẹ́ ẹṣin a máa sáré lórí àpáta bí?

Ǹjẹ́ ènìyàn a máa fi akọ màlúù kọ ilẹ̀ níbẹ̀?

Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti yí òtítọ́ padà sí májèlé

ẹ sì ti sọ èso òdodo di ìkorò.

13Ẹ̀yin yọ̀ torí ìṣẹ́gun lórí Lo-Debari

Ẹ̀yin sì wí pé, “Ṣé kì í ṣe agbára wa ni àwa fi gba Karnaimu?”

14Nítorí Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun wí pé,

“Èmi yóò gbé orílẹ̀-èdè kan dìde sí ọ ìwọ Israẹli,

wọn yóò pọ́n yín lójú ní gbogbo ọ̀nà,

láti Lebo-Hamati, títí dé pẹ̀tẹ́lẹ̀ Arabah.”