5. Mosebog 29 – BPH & YCB

Bibelen på hverdagsdansk

5. Mosebog 29:1-28

Opfordring til lydighed mod pagten

1-2Moses fortsatte med at tale til folket: „I har hørt om de vældige undere og frygtelige plager, som Herren sendte over egypterkongen, hans tjenere og hele hans folk. 3Men Herren har endnu ikke givet jer forstand til at fatte det, øjne til at se det eller ører til at høre det. 4I 40 år har han ført jer gennem ørkenen, uden at jeres tøj og sko blev slidt op. 5I fik hverken almindeligt brød eller vin og øl, men Herren sørgede for jeres behov for at lære jer at sætte jeres lid til ham som Herren, jeres Gud.

6Da vi kom hertil, rykkede kong Sihon af Heshbon og kong Og af Bashan ud imod os, men vi tilintetgjorde dem 7og overdrog deres land til Rubens og Gads stammer samt Manasses halve stamme. 8Overhold derfor omhyggeligt pagtens betingelser, så I må få velsignelse og fremgang i alt, hvad I tager jer for. 9I dag står I for Herrens ansigt sammen med jeres stammeoverhoveder og ledere på alle niveauer, 10jeres koner og børn og de fremmede, som hugger brænde og henter vand for jer. 11I står her for under ed at skulle tilslutte jer den pagt, som Herren i dag vil indgå med jer. 12Gør I det, skal I være hans folk, og han vil være jeres Gud, sådan som han også lovede jeres forfædre Abraham, Isak og Jakob. 13-14Denne pagt gælder ikke kun jer, som står her i dag, men også de kommende generationer i Israel.

Advarsel imod ulydighed mod pagten

15I husker, hvordan det var at bo i Egypten, og I husker, hvordan vi passerede gennem andre folkeslags territorier, 16og med jeres egne øjne så I deres afskyelige afgudsbilleder af træ, sten, sølv og guld. 17Der må ikke være nogen iblandt jer, mand eller kvinde, slægt eller stamme, der vender sig fra Herren for at dyrke den slags fremmede guder. Der må ikke være nogen bitter rod, som vokser op og spreder gift omkring sig. 18Skulle der findes nogen, som har hørt denne pagts ord og alligevel tror, at der ikke sker dem noget, hvis de gør oprør imod deres Gud, så vil Guds straf ramme både dem og andre omkring dem. 19-20Herren vil ikke tilgive sådanne mennesker, men straffe dem hårdt, for han vil ikke dele jeres hengivenhed med andre guder. Hans vrede vil blusse op imod dem, og han vil ramme dem med alle de forbandelser, som er nævnt i denne bog, indtil de er udryddet og deres slægtsnavn glemt.

21Hvis I bryder pagten med Herren, vil jeres efterkommere og de fremmede, der kommer langvejsfra, se følgerne af den katastrofe og de sygdomme, som Herren vil ramme landet med. 22De vil se øde, svovlholdige saltsletter, en gold og uopdyrket brandtomt uden vegetation overhovedet, når Herren i sin voldsomme vrede har gjort landet så øde som Sodoma, Gomorra, Adma og Sebojim.

23‚Hvad skyldes Herrens voldsomme vrede imod det land?’ vil man spørge. 24Svaret lyder: ‚Landets indbyggere brød deres pagt med Herren, deres fædres Gud, efter at han havde ført dem ud af Egypten. 25De dyrkede fremmede guder, som de aldrig før havde kendt, og som Herren havde forbudt dem at dyrke. 26Derfor blussede Herrens vrede op imod dem, så han ramte dem med alle de plager, der er nævnt i denne bog. 27I sin store vrede rykkede Herren dem op med rode og smed dem bort, bort til det land, hvor de nu bor.’

28Der findes hemmeligheder, som Herren ikke har åbenbaret for os. Men hvad han har åbenbaret, de ord, som er nedskrevet i denne lov, har vi pligt til at adlyde, både vi og vores børn.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Deuteronomi 29:1-29

Ìsọdi tuntun májẹ̀mú

1Èyí ni àwọn ìpinnu májẹ̀mú tí Olúwa pàṣẹ fún Mose láti ṣe pẹ̀lú àwọn ọmọ Israẹli ní Moabu, ní àfikún májẹ̀mú tí ó ti ṣe pẹ̀lú u wọn ní Horebu.

2Mose pàṣẹ fún gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, ó sì wí fún wọn wí pé:

Ojú rẹ ti rí gbogbo ohun tí Olúwa ti ṣe ní Ejibiti sí Farao àti, sí gbogbo àwọn ìjòyè e rẹ̀ àti sí ilẹ̀ ẹ rẹ̀. 3Pẹ̀lú ojú ara rẹ ni ìwọ rí àwọn ìdánwò ńlá náà, àwọn iṣẹ́ ààmì àti iṣẹ́ ìyanu ńlá. 429.4: Ro 11.8.Ṣùgbọ́n títí di àsìkò yìí Olúwa kò fi ọkàn ìmòye tàbí ojú tí ó ń rí tàbí etí tí ó n gbọ́ fún ọ. 5Nígbà ogójì ọdún tí mò ń tọ́ yín ṣọ́nà ní aginjù, aṣọ ọ̀ rẹ kò gbó tàbí bàtà ẹsẹ̀ rẹ. 6O kò jẹ oúnjẹ tàbí mu wáìnì kankan tàbí rú ohun mímu mìíràn. Mo ṣe èyí kí o lè mọ̀ pé èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ.

7Nígbà tí o dé ibí yìí, Sihoni ọba Heṣboni àti Ogu ọba Baṣani jáde wá láti bá ọ jà, ṣùgbọ́n a ṣẹ́gun wọn. 8A gba ilẹ̀ wọn a sì fi fún àwọn ọmọ Reubeni, àti àwọn ọmọ Gadi, àti ààbọ̀ ẹ̀yà Manase bí ogún.

9Nítorí náà, ẹ pa májẹ̀mú yìí mọ́, kí ẹ sì máa ṣe wọ́n, kí ẹ̀yin kí ó lè máa rí ire nínú gbogbo ohun tí o bá ń ṣe. 10Gbogbo yín ń dúró lónìí yìí níwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ: àwọn olórí yín, àwọn ẹ̀yà yín, àwọn àgbàgbà yín àti àwọn ìjòyè yín, àní gbogbo àwọn ọkùnrin mìíràn ní Israẹli, 11pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ ọ̀ rẹ àti ìyàwó ò rẹ àti àwọn àjèjì tí wọ́n ń gbé ní àgọ́ ọ̀ rẹ, tí ó ké pópòpó igi rẹ, tí ó sì gbé omi rẹ. 12O dúró níhìn-ín yìí kí o lè wọ inú májẹ̀mú pẹ̀lú Olúwa Ọlọ́run rẹ, májẹ̀mú tí Olúwa ń ṣe pẹ̀lú rẹ lónìí yìí àti tí òun dè pẹ̀lú ìbúra, 13láti jẹ́wọ́ rẹ lónìí yìí bí ènìyàn an rẹ̀, pé kí ó lè jẹ́ Ọlọ́run rẹ bí ó ti ṣèlérí àti bí ó ti ṣe ìbúra fún àwọn baba à rẹ Abrahamu, Isaaki àti Jakọbu. 14Èmi ń ṣe májẹ̀mú yìí, pẹ̀lú ìbúra rẹ̀, kì í ṣe fún ìwọ nìkan 15tí ó dúró níbí pẹ̀lú wa lónìí níwájú Olúwa Ọlọ́run wa ṣùgbọ́n àti fún gbogbo àwọn tí kò sí níbí lónìí.

16Ìwọ fúnra à rẹ mọ bí a ṣe gbé ní Ejibiti àti bí a ṣe kọjá láàrín àwọn orílẹ̀-èdè nílẹ̀ ibí yìí. 17Ìwọ rí láàrín wọn ìríra wọn, àwọn ère àti àwọn òrìṣà igi àti ti òkúta, ti fàdákà àti ti wúrà. 1829.18: Ap 8.23; Hb 12.15.Rí i dájú pé kò sí ọkùnrin tàbí obìnrin, ìdílé tàbí ẹ̀yà láàrín yín lónìí tí ọkàn an rẹ̀ yóò yí kúrò lọ́dọ̀ Olúwa Ọlọ́run wa láti lọ àti láti sin àwọn ọlọ́run àwọn orílẹ̀-èdè náà; rí i dájú pé kò sí gbòǹgbò tí ó ń mú irú èso kíkan bẹ́ẹ̀ jáde láàrín yín.

19Nígbà tí irú ẹni bẹ́ẹ̀ bá gbọ́ ìbúra yìí, kí ó gbàdúrà ìbùkún sórí ara rẹ̀ nígbà náà ni kí ó ronú, “Èmi yóò wà ní àlàáfíà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti fi àáké kọ́rí nípa lílọ nínú ọ̀nà ti ara à mi.” Èyí yóò mú àjálù wá sórí ilẹ̀ tútù àti sórí ilẹ̀ gbígbẹ bákan náà 20Olúwa kì yóò ní ìfẹ́ sí àti dáríjì í; ìbínú àti ìtara rẹ̀ yóò jó ọkùnrin náà. Gbogbo àwọn ègún tí a kọ sínú ìwé yìí yóò wá sórí i rẹ̀, Olúwa yóò sì yọ orúkọ rẹ̀ kúrò lábẹ́ ọ̀run. 21Olúwa yóò sì yọ òun nìkan kúrò nínú gbogbo ẹ̀yà Israẹli fún àjálù, gẹ́gẹ́ bí gbogbo ègún májẹ̀mú tí a kọ sí inú ìwé òfin yìí.

22Àwọn ọmọ rẹ tí ó tẹ̀lé ìran rẹ lẹ́yìn àti àwọn àjèjì tí ó wá láti ilẹ̀ jíjìn yóò rí wàhálà tí ó wá sórí ilẹ̀ àti àwọn ààrùn pẹ̀lú tí Olúwa mú bá ọ. 23Gbogbo ilẹ̀ náà yóò di imí-oòrùn, àti iyọ̀, àti ìjóná tí a kò lè fi ọkàn sí, tàbí tí kò lè so èso tàbí tí koríko kò lè hù nínú u rẹ̀, yóò dàbí ìbìṣubú Sodomu àti Gomorra, Adma àti Ṣeboimu, tí Olúwa bì ṣubú nínú ìbínú rẹ̀, àti ìkáàánú rẹ̀. 24Gbogbo orílẹ̀-èdè yóò béèrè pé, “Kí ló dé tí Olúwa fi ṣe èyí sí ilẹ̀ yìí? Kí ni a lè mọ ooru ìbínú ńlá yìí sí?”

25Ìdáhùn yóò sì jẹ́ báyìí: “Nítorí tí ènìyàn yìí kọ Olúwa Ọlọ́run baba wọn sílẹ̀, májẹ̀mú tí ó ti bá wọn dá nígbà tí ó mú wọn jáde wá láti Ejibiti. 26Wọ́n lọ wọ́n sì sin ọlọ́run mìíràn, wọ́n sì foríbalẹ̀ fún wọn, ọlọ́run tí wọn kò mọ̀, ọlọ́run tí kò fi fún wọn. 27Nígbà náà ni ìbínú Olúwa ru sí ilẹ̀ wọn, dé bi pé ó mú gbogbo ègún tí a kọ sínú ìwé yìí wá sórí i rẹ̀. 28Ní ìbínú àti ní ìkáàánú, àti ní ìrunú ńlá, Olúwa sì fà wọ́n tu kúrò ní ilẹ̀ wọn, ó sì lé wọn lọ sí ilẹ̀ mìíràn, bí ó ti rí ní òní yìí.”

29Ohun ìkọ̀kọ̀ jẹ́ ti Olúwa Ọlọ́run wa, ṣùgbọ́n ohun tí a fihàn jẹ́ ti wa àti ti àwọn ọmọ wa títí láé, kí a lè tẹ̀lé gbogbo ọ̀rọ̀ inú òfin yìí.