4. Mosebog 21 – BPH & YCB

Bibelen på hverdagsdansk

4. Mosebog 21:1-35

Moses laver en kobberslange

1Da kongen af Arad i Negev hørte, at israelitterne kom op ad vejen mod Atarim, samlede han sin hær og angreb dem, og det lykkedes ham at tage en del af dem til fange. 2Da lovede Israels folk højt og helligt Herren, at hvis han ville hjælpe dem med at besejre kongen af Arad og hans hær, ville de totalt udslette alle de kana’anæiske byer i området uden at tage noget bytte til sig selv. 3Herren hørte deres bøn og gav dem sejr over kana’anæerne, så alle byerne og deres indbyggere blev udslettet. Stedet er siden kendt under navnet Horma.21,3 Det hebraiske ord betyder „udslettelse” og henviser til noget, som er overgivet til Herrens dom.

4Derfra vendte israelitterne tilbage til Hors bjerg, hvorefter de fortsatte ad vejen mod Det Røde Hav i en bue uden om Edom. Men undervejs blev de utålmodige, 5og de begyndte atter at kritisere både Gud og Moses. „Hvorfor førte du os ud af Egypten?” klagede de. „Var det for at lade os dø her i ørkenen? Her er jo hverken vand eller mad—og vi er trætte af den evindelige manna.”

6Da sendte Herren giftslanger imod dem, og mange blev bidt og døde.

7Nu kom folket til Moses og sagde: „Vi har syndet ved at gøre oprør mod dig og Herren. Bed Herren om at fjerne slangerne fra os.” Da gik Moses i forbøn for folket, 8og Herren sagde Moses: „Lav en slange af kobber21,8 Eller: „bronze”. Hebraisk brugte det samme ord for kobber og bronze. og hæng den op på en stang—så skal alle, som ser hen på den, leve, selvom de er blevet bidt af giftslangerne.”

9Så lavede Moses en kobberslange og satte den op på en stang. Og alle, som så hen på den, når de var blevet bidt af en slange, reddede livet.

Rejsen fortsætter uden om Edom gennem Moab

10Derefter rejste Israels folk videre og slog lejr ved Obot. 11Fra Obot tog de til Ijje-ha-Abarim i ørkenen umiddelbart øst for Moab, 12og videre til Zereddalen, hvor de igen slog lejr. 13Fra Zereddalen rejste de videre mod nord til det øde område på den anden side af Arnonfloden ved grænsen til amoritternes land. Arnonfloden danner grænse mellem moabitterne og amoritterne. 14„Bogen om Herrens krige” nævner byen Vaheb med dens bække i Sufaområdet i Arnonflodens kløft, 15som strækker sig langs grænsen til Moab helt til byen Ar.

16Derfra rejste israelitterne til Be’er.21,16 Det betyder: „brønd”. Det var ved dette vandsted, at Herren sagde til Moses: „Kald folket sammen, så vil jeg give dem vand.” 17-18Episoden står beskrevet i følgende sang:

„Du ældgamle brønd, hvor kilden fremsprang,

vi viser vor glæde ved at synge en sang.

Denne brønd lod stormænd grave,

fyrster med scepter og herskerstave.”

Så forlod de ørkenen og fortsatte gennem Mattana, 19Nahaliel og Bamot 20og videre gennem dalen i Moabs højland, hvorfra man kan se ørkenen og Pisgas bjergtinder længere borte.

Israelitterne besejrer kong Sihon og Kong Og

21Da sendte Israel følgende budskab til amoritterkongen Sihon: 22„Giv os tilladelse til at rejse igennem dit land. Vi lover, at vi ikke vil nedtrampe jeres marker og vingårde eller drikke jeres vand, men holde os på Kongevejen, så længe vi er i jeres land.”

23Men kong Sihon gav dem ikke lov. I stedet samlede han sin hær og rykkede ud mod israelitterne i ørkenen. Ved Jahatz mødtes de to hære, 24og Israel huggede amoritterne ned. Derefter besatte de området fra Arnonfloden i syd til Jabbokfloden mod nord og ud til ammonitternes område mod øst, men ikke længere, for ammonitternes grænse var stærkt befæstet.

25-26Israelitterne indtog således amoritternes byer, og de slog sig ned i disse byer, også i Heshbon, kong Sihons residensby, og i området op til Arnonfloden, der tidligere havde tilhørt moabitterne, men som kong Sihon havde erobret. 27-30Den gamle digter udtrykker det sådan:

„Kom til Heshbon, Sihons by

som nu bygges op på ny.

Ild fór ud fra Heshbon,

flammer skød frem fra Sihon.

Moabs byer gik op i røg,

Arnons fjelde, hver en høj.

Moabitter, nu er det forbi

med jeres Kemosh-afguderi.

Han sendte jo jer alle på flugt,

kvinder blev fanger—åh, hvor smukt!

Men vi erobred’ Heshbon,

indtog landet op til Dibon.

Vi dræbte dem helt til Nofa

som ligger tæt ved Medeba.”

31-32Mens Israels folk opholdt sig i amoritternes land, sendte Moses nogle spioner ud for at undersøge, hvordan han lettest kunne indtage byen Jazer. Derefter angreb de byen og de omkringliggende landsbyer, og amoritterne måtte flygte.

33Derefter satte de kursen nordpå mod Bashan, hvor kong Og straks mobiliserede sin hær og rykkede ud mod dem ved byen Edrei. 34Men Herren sagde til Moses: „Du skal ikke være bange. Jeg vil udlevere kongen og hans hær og hans land til dig. Du skal gøre med ham, som du gjorde med amoritternes kong Sihon af Heshbon.” 35Og ganske rigtigt: Israelitterne sejrede og dræbte kong Og, hans sønner og hans hær, så der ikke var en eneste overlevende tilbage. Således lykkedes det israelitterne at erobre hele området.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Numeri 21:1-35

A pa ìlú Aradi run

121.1: Nu 33.40.Nígbà tí ọba Aradi ará Kenaani, tí ń gbé ní gúúsù gbọ́ wí pé Israẹli ń bọ̀ wá ní ojú ọ̀nà Atarimu, ó bá Israẹli jà ó sì fi agbára mú díẹ̀ lára wọn. 2Nígbà náà ni Israẹli jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Olúwa pé: “Bí o bá lè fi àwọn ènìyàn yìí lé wa lọ́wọ́, gbogbo ìlú wọn ni a ó parun.” 3Olúwa gbọ́ ẹ̀bẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli, ó sì fi àwọn ará Kenaani lé wọn lọ́wọ́. Wọ́n pa wọ́n run pátápátá; torí náà ni a ṣe ń pe ibẹ̀ ní Horma.

Ejò idẹ

4Wọ́n rin ìrìnàjò láti òkè Hori lọ sí ọ̀nà tó lọ sí Òkun Pupa, láti kọjá yípo Edomu. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn bínú ní ojú ọ̀nà; 5wọ́n sì sọ̀rọ̀ lòdì sí Ọlọ́run àti Mose, wọ́n wí pé, “Èéṣe tí ìwọ fi mú wa jáde láti Ejibiti kí a ba le wá kú sí aginjù yìí? Kò sí oúnjẹ! Kò sì sí omi! Àwa sì kórìíra oúnjẹ tí kò dára yìí!”

6Nígbà náà ni Olúwa rán ejò olóró sí àárín wọn; wọ́n gé àwọn ènìyàn jẹ, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Israẹli sì kú. 7Àwọn ènìyàn sì wá sí ọ̀dọ̀ Mose wọn wí pé, “A ti dá ẹ̀ṣẹ̀ nígbà tí asọ̀rọ̀-òdì sí Olúwa àti sí ìwọ pẹ̀lú. Gba àdúrà pé kí Olúwa mú ejò náà kúrò lọ́dọ̀ wa.” Nígbà náà ni Mose gbàdúrà fún àwọn ènìyàn.

8Olúwa sọ fún Mose pé, “Rọ ejò, a ó sì gbé e kọ́ sókè lórí igi, ẹni tí ejò bá ti gé jẹ lè wò ó yóò sì yè.” 9Nígbà náà ni Mose sì rọ ejò onírin ó sì gbé e kọ́ sórí igi, Bí ejò bá sì bu ẹnikẹ́ni jẹ bí ó bá ti wò ó yóò sì yè.

Ìrìnàjò sí Moabu

10Àwọn ọmọ Israẹli tẹ̀síwájú wọ́n sì péjọ sí Obotu. 11Wọ́n gbéra ní Obotu wọ́n sì pa ibùdó sí Iye-Abarimu, ní aginjù tí ó kọjú sí Moabu ní ìdojúkọ ìlà-oòrùn. 12Láti ibẹ̀ ni wọ́n ti gbéra wọ́n sì pa ibùdó ní Àfonífojì Seredi. 13Láti ibẹ̀ lọ, wọn ṣí, wọ́n sì dó sí ìhà kejì Arnoni, tí ó wà ní aginjù tí ó wà ní agbègbè ilẹ̀ àwọn ọmọ Amori. Arnoni jẹ́ ààlà fún ilẹ̀ Moabu, láàrín Moabu àti Amori. 14Ìdí nìyìí tí ìwé ogun Olúwa se wí pé:

“…Wahebu ní Sufa, Òkun pupa àti

ní odò Arnoni 15àti ní ìṣàn odò

tí ó darí sí ibùjókòó Ari

tí ó sì fi ara ti ìpínlẹ̀ Moabu.”

16Láti ibẹ̀ ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ rìn dé Beeri, èyí ni kànga tí Olúwa sọ fún Mose, “Kó àwọn ènìyàn jọ èmi ó sì fún wọn ní omi.”

17Nígbà náà ni Israẹli kọ orin yìí pé:

“Sun jáde, ìwọ kànga!

Ẹ máa kọrin nípa rẹ̀,

18nípa kànga tí àwọn ọmọ-aládé gbẹ́,

nítorí àwọn ọlọ́lá ènìyàn ni ó gbẹ́ ẹ;

tí àwọn ọlọ́lá àwọn ènìyàn sì fi ọ̀pá aládé àti ọ̀pá oyè wọn gbẹ́.”

Nígbà náà wọ́n kúrò láti aginjù lọ sí Mattana, 19láti Mattana lọ sí Nahalieli, láti Nahalieli lọ sí Bamoti, 20àti láti Bamoti lọ sí àfonífojì ní Moabu níbi tí òkè Pisga, tí ó wà ní òkè ilé omi ti kọjú sí aginjù.

Ìṣẹ́gun Sihoni àti Ogu

2121.21-30: De 2.26-37.Israẹli rán oníṣẹ́ láti sọ fún Sihoni ọba àwọn ará Amori wí pé:

22“Jẹ́ kí a kọjá ní orílẹ̀-èdè rẹ. A kò ní kọjá sí inú oko pápá tàbí ọgbà àjàrà àbí mu omi láti inú kànga. A máa gba òpópónà náà ti ọba títí tí a ó fi la ilẹ̀ rẹ kọjá.”

23Ṣùgbọ́n Sihoni kò ní jẹ́ kí àwọn Israẹli kọjá ní ilẹ̀ wọn. Ó pe àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ jọ wọ́n sì wọ́de ogun lọ sí aginjù nítorí àwọn ọmọ Israẹli. Nígbà tí ó dé Jahasi, ó bá àwọn ọmọ Israẹli jà. 24Àmọ́, Israẹli ṣẹ́gun, wọn fi ojú idà pa wọ́n, wọ́n sì gba ilẹ̀ láti ọwọ́ Arnoni lọ dé Jabbok, títí tí ó fi dé ilẹ̀ àwọn ará Ammoni, nítorí pé ààlà wọn jẹ́ olódi. 25Israẹli sì gba gbogbo ìlú Amori wọ́n sì ń gbé ibẹ̀ pẹ̀lú Heṣboni, àti gbogbo ibùgbé ìlú tó yí i ká. 26Heṣboni ni ìlú Sihoni ọba àwọn ará Amori, ẹni tí ó bá ọba Moabu ti tẹ́lẹ̀ jà tí ó sì gba gbogbo ilẹ̀ rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀ títí dé Arnoni.

27Ìdí nìyìí tí akọrin sọ wí pé:

“Wá sí Heṣboni kí ẹ jẹ́ kí a tún un kọ́;

jẹ́ kí ìlú Sihoni padà bọ̀ sípò.

28“Iná jáde láti Heṣboni,

ọ̀wọ́-iná láti Sihoni.

Ó jó Ari àti Moabu run,

àti ìlú àwọn olùgbé ibi gíga Arnoni.

29Ègbé ní fún ọ, ìwọ Moabu!

Ẹ ti parun, ẹ̀yin ènìyàn Kemoṣi!

Ó ti fi ọmọ rẹ̀ ọkùnrin sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìsáǹsá

àti ọmọ rẹ̀ obìnrin gẹ́gẹ́ bí ìgbèkùn

fún Sihoni ọba àwọn Amori.

30“Ṣùgbọ́n àti bì wọ́n ṣubú;

A ti pa ìjẹgàba Heṣboni run, a pa wọ́n run títí dé Diboni.

A sì ti bì wọ́n lulẹ̀ títí dé Nofa,

tí ó sì fi dé Medeba.”

31Nígbà náà ni àwọn ọmọ Israẹli sì ń gbé ní ilẹ̀ Amori.

32Lẹ́yìn ìgbà tí Mose rán ayọ́lẹ̀wò lọ sí Jaseri, àwọn ọmọ Israẹli sì gba àwọn agbègbè tó yí wọn ká wọ́n sì lé àwọn Amori tó wà níbẹ̀ jáde. 3321.33-35: De 3.1-7.Nígbà náà wọ́n pẹ̀yìndà wọ́n sì gòkè lọ sí Baṣani, Ogu ọba ti Baṣani àti gbogbo àwọn ọmọ-ogun tí ó wọ́de ogun jáde láti pàdé wọn ní ojú ogun ní Edrei.

34Olúwa sọ fún Mose pé, “Má ṣe bẹ̀rù rẹ̀, nítorí tí mó tí fi òun lé ọ lọ́wọ́, àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀, àti ilẹ̀ rẹ̀. kí ìwọ kí ó ṣe sí i gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti ṣe sí Sihoni ọba Amori ẹni tí ó ń jẹ ọba ní Heṣboni.”

35Wọ́n sì pa á, pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ àti gbogbo àwọn ọmọ-ogun rẹ̀, wọn kò fi ku ẹnìkan fún un láàyè. Wọ́n sì gba ìní ilẹ̀ rẹ̀.