3. Mosebog 23 – BPH & YCB

Bibelen på hverdagsdansk

3. Mosebog 23:1-44

Israelitternes religiøse fester

1-2Herren bad Moses give israelitterne følgende instrukser: „Det følgende er mine hellige dage, hvor I skal komme sammen for at holde højtid for mig.

Hviledagen

3Ugens syvende dag skal være en fuldstændig hviledag, hvor I skal samles for at tilbede Herren. I kan udføre jeres arbejde på ugens øvrige seks dage, men sabbatsdagen skal være helliget mig, lige meget hvor I bor.

Påskedagen og de usyrnede brøds fest

4De følgende højtider skal I fejre hvert år på det fastsatte tidspunkt.

5Påskedagen falder på den 14. dag i den første måned, og påskemåltidet skal fejres efter solnedgang.

6De usyrnede brøds højtid begynder den 15. dag i den samme måned, og den skal vare i syv dage. Under den fest må I ikke spise brød, der er bagt med surdej. 7På festugens første dag skal folket mødes og tilbede mig, og I skal afholde jer fra alt hårdt arbejde. 8Det samme skal I gøre på festugens sidste dag, og hver eneste af de syv festdage skal I bringe ildofre til Herren.”

Festen for den første høst

9Herren fortsatte med at tale til Moses: 10„Når I kommer ind i det land, jeg vil give jer, og begynder at høste afgrøde fra jeres marker, skal I hvert år bringe det første neg fra jeres kornhøst til præsten. 11Det skal I gøre dagen efter sabbatsdagen,23,11 Dvs. den sabbat, som faldt under den ugelange usyrnede brøds fest. Da israelitternes kalender er fastsat ud fra månens skiften, faldt påsken ikke på samme ugedag hvert år, men festen for den første høst faldt således altid på den dag, vi kalder søndag, dagen efter sabbatten. og præsten skal så svinge det foran Herrens alter, så Herren kan tage imod jeres taknemmelighedsgave. 12Samme dag skal I ofre et etårs lam uden skavanker som et brændoffer til Herren. 13Offeret skal ledsages af et afgrødeoffer på fire liter fint mel rørt op i olivenolie. Det skal være et ildoffer til Herren sammen med et drikoffer bestående af en liter vin. 14I må hverken spise friske kerner, brød eller ristet korn fra jeres nye høst, før I har bragt denne gave til Herren. Denne lov skal altid gælde, hvor I end bor.

Festen for den store høst

15Fra dagen efter denne sabbat, den dag, hvor det første neg blev svunget for Herrens ansigt, skal I så tælle nøjagtig syv uger frem, 16indtil I når frem til dagen efter den syvende sabbat. I skal altså tælle 50 dage23,16 Da man i denne kultur talte inklusivt, dvs. man talte udgangspunktet med, vil den 50. dag falde nøjagtig 49 dage efter begyndelsesdagen eller 7 uger senere. I det Ny Testamente kaldes denne fest for „Pinsefesten” efter det græske ord for 50. frem, og så skal I bringe endnu et høstoffer til Herren.23,16 De to væsentligste kornsorter i Israel var byg og hvede. Den tidligere omtalte fest blev holdt i forbindelse med byghøsten, mens festen her blev holdt i forbindelse med hvedehøsten. 17I skal komme med to brød hjemmefra. Brødene skal bages af fire liter fint mel ved brug af surdej, og de skal svinges foran Herrens alter som en taknemmelighedsgave for høsten. 18Foruden dette afgrødeoffer og drikofferet skal I ofre syv etårs lam uden skavanker, en ung tyr og to væddere som et lifligt brændoffer. 19Dernæst skal I ofre en gedebuk som syndoffer og to etårs vædderlam som takoffer.

20Sammen med brødene, som repræsenterer jeres høst, skal præsten svinge disse offergaver foran Herrens alter. De er givet til Herren, men præsterne må spise dem. 21Denne dag skal udråbes til en hellig festdag for hele folket. Ingen må udføre hårdt arbejde den dag. Dette er en permanent forordning, som skal gælde fra slægt til slægt, hvor I end bor.

22Når I høster jeres marker, skal I lade noget af kornet langs kanten stå, og de få aks, som høstfolkene overser, skal I lade ligge på marken. Det er til føde for de fattige og fremmede, som ikke selv ejer jord. Jeg er Herren, jeres Gud.”

Nytårsfesten

23Herren fortsatte med at tale til Moses: 24„Den første dag i den syvende måned skal være en hvile- og højtidsdag, en mindedag, som indvarsles med lyden fra et vædderhorn.23,24 Den hebraiske tekst bruger et specielt ord (teruah), som betyder „alarm” og forbindes med blæsning i den tids signaltrompet, der var et langt vædderhorn—en shofar. Se 3.Mos. 25,9, hvor det samme ord følger efter ordet shofar. Ordet „minde” eller „huske” blev ofte brugt i forbindelse med Guds overnaturlige indgreb til frelse for sit folk. På denne nytårsdag skulle folket mindes de undere, Herren tidligere havde gjort og dem, han ville gøre i fremtiden. 25Ingen må udføre hårdt arbejde på den dag, men I skal bringe Herren ildofre.”

Forsoningsdagen

26Herren fortsatte sine instruktioner til Moses: 27„Den tiende dag i den syvende måned skal være forsoningsdagen. På den dag skal I faste23,27 Som tegn på anger over ens synder. og holde højtid for Herren med ildofre. 28I må ikke udføre normalt arbejde, for den dag er afsat til at skabe forsoning mellem jer og Herren, jeres Gud. 29Enhver, der undlader at faste på den dag, 30og enhver, som udfører normalt arbejde på den dag, skal dø. 31Dette er en permanent forordning, der skal gælde fra slægt til slægt, hvor I end bor. 32Det skal være en fuldkommen hviledag, hvor I skal undlade at spise noget. Forsoningsdagen begynder ved solnedgang den niende og varer til solnedgang næste dag.”

Løvhyttefesten

33Herren fortsatte: 34„På den 15. dag i den syvende måned skal I påbegynde løvhyttefesten for Herren, og festen skal vare i syv dage. 35På den første dag skal folket samles til højtid, og der må ikke udføres noget hårdt arbejde på den dag. 36På hver af festens syv dage skal I bringe ildofre til Herren. På den ottende dag skal folket samles igen til højtid og bringe ildofre til Herren. Heller ikke på den dag må der udføres hårdt arbejde.

37Dette er de hellige fester, hvor folket skal holde højtid og bringe ildofre til Herren, både brændofre og afgrødeofre, madofre og drikofre. 38Disse festdage er ekstra højtider ud over sabbatsdagene, og de ofre, I bringer ved disse fester, skal være i tilgift til jeres normale gaver og taknemmelighedsofre til Herren.

39Hvad løvhyttefesten angår, skal den vare i en hel uge. Når høsten er overstået, skal festen påbegyndes på den 15. dag i den syvende måned, og både den første dag og den ottende dag skal være hviledage. 40På den første dag skal I komme med de flotteste frugter, palmegrene, løvrige grene og pilegrene, og i syv dage skal I danse og juble for Herren. 41Husk, at festen skal være en tilbagevendende begivenhed, som I fejrer år efter år. 42I syv dage skal alle indfødte israelitter bo i løvhytter, 43for at de kommende generationer kan vide, hvordan det var, da jeg, Herren, jeres Gud, førte jer ud af Egypten og lod jer bo i løvhytter.”

44Da Herren var færdig med alle disse instruktioner om festerne, gav Moses dem videre til Israels folk.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Lefitiku 23:1-44

Ọdún àwọn ọmọ Israẹli

123.1-44: El 23.14-17; 34.22-24; De 16.1-17.Olúwa sọ fún Mose wí pé, 2“Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli, kí o sì wí fún wọn pé, ‘Ìwọ̀nyí ni àwọn àjọ̀dún tí a yàn, àwọn àjọ̀dún ti Olúwa èyí tí ẹ gbọdọ̀ kéde gẹ́gẹ́ bí àjọ̀dún tí a yàn.

Ọjọ́ ìsinmi

3“ ‘Ọjọ́ mẹ́fà ni ẹ le fi ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n ọjọ́ keje ni ọjọ́ ìsinmi. Ọjọ́ àjọ̀dún tí a yàn. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan, níbikíbi tí ẹ bá ń gbé. Ọjọ́ ìsinmi Olúwa ni.

Ọdún ìrékọjá àti àkàrà aláìwú

4“ ‘Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọdún tí Olúwa yàn, àjọ̀dún tí a yàn tí ẹ gbọdọ̀ kéde lákokò wọn. 5Àjọ ìrékọjá Olúwa bẹ̀rẹ̀ ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìn-ín-ní (Epiri). 6Ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù kìn-ín-ní, ni àjọ̀dún àkàrà àìwú (àkàrà tí kò ní ìwúkàrà) tí Olúwa bẹ̀rẹ̀ fún ọjọ́ méje ni ẹ gbọdọ̀ fi jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà. 7Ní ọjọ́ kìn-ín-ní kí àpéjọ mímọ́ kí ó wà; ẹ́yin kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ agbára kankan nínú rẹ̀. 8Ọjọ́ méje ni kí ẹ fi mú ọrẹ tí a fi iná ṣe wá fún Olúwa. Ní ọjọ́ keje, ẹ pe ìpàdé àjọ mímọ́, ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan.’ ”

Ọrẹ àkọ́so

9Olúwa sọ fún Mose pe 10“Sọ fún àwọn ará Israẹli, kí o sì wí fún wọn pé, ‘Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí èmi yóò fún yín, tí ẹ bá ń ṣe ìkórè, kí ẹ mú síírí ọkà àkọ́kọ́ tí ẹ kórè wá fún àlùfáà. 11Kí ó fi síírí ọkà náà níwájú Olúwa, kí ó le jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún yín: kí àlùfáà fì í ní ọjọ́ kejì ìsinmi. 12Ní ọjọ́ tí ẹ bá fi síírí ọkà náà, kí ẹ mú ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan láìní àbùkù rú ẹbọ sísun sí Olúwa. 13Pẹ̀lú ọrẹ ọkà rẹ tí ó jẹ́ ìdá méjì nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n efa (èyí jẹ́ lítà mẹ́rin ààbọ̀) ti ìyẹ̀fun, tí a fi òróró pò ọrẹ tí a fi iná ṣe fún Olúwa òórùn dídùn pẹ̀lú ọrẹ ohun mímu rẹ̀ tí í ṣe ìdámẹ́rin òṣùwọ̀n hínì (Èyí jẹ́ lítà kan). 14Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ àkàrà kankan tàbí kí ẹ sun ọkà tuntun títí di ọjọ́ tí ẹ fi mú ọrẹ yín wá fún Ọlọ́run yín. Èyí ni ìlànà ayérayé fún ìran tí ń bọ̀, níbikíbi tí ẹ bá ń gbé.

Ọdún àwọn ọ̀sẹ̀ Pentikosti

15“ ‘Ẹ ka ọ̀sẹ̀ méje gbangba, láti ọjọ́ kejì ọjọ́ ìsinmi, àní ọjọ́ tí ẹ mú ìdì ọkà fífì wá. 16Ẹ ka àádọ́ta (50) ọjọ́ títí dé ọjọ́ kejì ọ̀sẹ̀ méjèèje, kí ẹ sì mú ọrẹ ọkà tuntun wá fún Olúwa. 17Láti ibikíbi tí ẹ bá ń gbé, ẹ mú ìṣù àkàrà méjì tí a fi òṣùwọ̀n ìdá méjì nínú mẹ́wàá tí efa (Èyí jẹ́ lítà mẹ́rin ààbọ̀) ti ìyẹ̀fun, tí a fi ìwúkàrà ṣe, gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fífì àkọ́so sí Olúwa. 18Ẹ fi akọ ọ̀dọ́-àgùntàn méje ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan tí kò ní àbùkù, ọmọ màlúù kan àti àgbò méjì kún àkàrà yìí: wọn yóò jẹ́ ẹbọ sísun sí Olúwa, pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu wọn, àní ẹbọ tí a fi iná ṣe, olóòórùn dídùn ni sí Olúwa. 19Lẹ́yìn náà kí ẹ fi akọ ewúrẹ́ kan rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àti ọ̀dọ́-àgùntàn méjì ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan fún ọrẹ àlàáfíà. 20Kí àlùfáà fi ọ̀dọ́-àgùntàn méjèèjì náà níwájú Olúwa bí i ọrẹ fífì pẹ̀lú oúnjẹ àkọ́so wọn jẹ́ ọrẹ mímọ́ sí Olúwa fún àlùfáà. 21Ní ọjọ́ yìí náà ni kí ẹ kéde ìpàdé àjọ mímọ́: ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan. Èyí yóò jẹ́ ìlànà ayérayé fún àwọn ìran tí ń bọ̀ níbi yówù tí ẹ ń gbé.

2223.22: Le 19.9,10; De 24.20,21.“ ‘Nígbà tí ẹ bá kórè ilẹ̀ yín ẹ má ṣe kórè dé ìkangun oko yín, tàbí kí ẹ padà gé èyí tí ó ṣẹ́kù sílẹ̀ nínú ìkórè yín. Ẹ fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn tálákà àti àwọn àlejò: Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.’ ”

Ọdún ìfùnpè

23Olúwa sọ fún Mose pé 24“Sọ fún àwọn ará Israẹli: ‘Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù keje, kí ẹ ní ọjọ́ ìsinmi, ìpàdé àjọ mímọ́ tí a fi fèrè fífọn ṣe ìrántí 25Ẹ má ṣe ṣe iṣẹ́ ojúmọ́, ṣùgbọ́n ẹ mú ọrẹ tí a fi iná sun wá síwájú Olúwa.’ ”

Ọjọ́ ètùtù

26Olúwa sọ fún Mose pé, 27“Ọjọ́ kẹwàá oṣù keje yìí ni ọjọ́ ètùtù. Ẹ ni ìpàdé àjọ mímọ́, kí ẹ sì ṣẹ́ ara yín kí ẹ sì mú ọrẹ tí a fi iná ṣe wá fún Olúwa. 28Ẹ má ṣe ṣe iṣẹ́ kankan ní ọjọ́ náà, torí pé ọjọ́ ètùtù ni, nínú èyí tí a ń ṣe ètùtù fún yín níwájú Olúwa Ọlọ́run yín. 29Ẹnikẹ́ni tí kò bá ṣẹ́ ara rẹ̀ ní ọjọ́ náà ni a ó gé kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀. 30Èmi yóò pa ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣiṣẹ́kíṣẹ́ ní ọjọ́ náà run kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀. 31Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan rárá. Èyí yóò jẹ́ ìlànà ayérayé fún àwọn ìran tí ń bọ̀, níbikíbi tí ẹ bá ń gbé. 32Ọjọ́ ìsinmi ni fún un yín, ẹ gbọdọ̀ ṣẹ́ ara yín, láti ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹsànán oṣù náà, títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ tí ó tẹ̀lé e, ni kí ẹ fi sinmi.”

Ọdún àgọ́

3323.33-36: De 16.13-15.Olúwa sọ fún Mose pé, 34“Sọ fún àwọn ará Israẹli pé: ‘Ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù keje ni kí àjọ̀dún ọdún àgọ́ ti Olúwa bẹ̀rẹ̀ kí ó sì wà títí di ọjọ́ méje. 35Ọjọ́ kìn-ín-ní jẹ́ ọjọ́ ìpàdé mímọ́: Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ ojúmọ́. 36Ọjọ́ méje ni kí ẹ fi mú ọrẹ tí a fi iná ṣe wá, ní ọjọ́ kẹjọ, ẹ pe ìpàdé mímọ́ kí ẹ sì mú ọrẹ tí a fi iná ṣe wá fún Olúwa, èyí jẹ́ ìpàdé tí ó gbẹ̀yìn; ẹ má ṣe ṣe iṣẹ́ ojoojúmọ́.

37(“ ‘Ìwọ̀nyí ni àwọn àjọ̀dún tí Olúwa ti yàn tí ẹ gbọdọ̀ kéde gẹ́gẹ́ bí i àjọ̀dún tí a yàn fún mímu àwọn ọrẹ tí a fi iná ṣe sí Olúwa wá—ẹbọ sísun àti ọrẹ ọkà, ọrẹ ẹbọ àti ọrẹ ohun mímu, fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan: 38Àwọn ọrẹ wọ̀nyí wà ní àfikún pẹ̀lú àwọn ọrẹ ọjọ́ ìsinmi Olúwa, àti pẹ̀lú ẹ̀bùn yín àti ohunkóhun tí ẹ ti jẹ́ ẹ̀jẹ́ àti gbogbo ọrẹ àtinúwá yín fún Olúwa.)

39“ ‘Torí náà, bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù keje lẹ́yìn ìgbà tí ẹ ti kórè ilẹ̀ náà, ẹ ṣe àjọ̀dún yìí fún Olúwa ní ọjọ́ méje. Ọjọ́ kìn-ín-ní jẹ́ ọjọ́ ìsinmi, ọjọ́ kẹjọ pẹ̀lú si tún jẹ́ ọjọ́ ìsinmi. 40Ní ọjọ́ kìn-ín-ní, kí ẹ mú àṣàyàn èso láti orí igi dáradára, imọ̀ ọ̀pẹ, àti ẹ̀ka igi tó rúwé, àti igi wílò odò, kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú Olúwa Ọlọ́run yín fún ọjọ́ méje. 41Ẹ ṣe èyí ní àjọ̀dún sí Olúwa fún ọjọ́ méje lọ́dọọdún. Èyí yóò jẹ́ ìlànà ayérayé fún àwọn ìran tí ń bọ̀: Ẹ ṣe é ní oṣù keje. 42Ẹ gbé inú àgọ́ fún ọjọ́ méje. Kí gbogbo ọmọ bíbí Israẹli gbé nínú àgọ́. 43Kí àwọn ìran yín le mọ̀ pé mo mú kí Israẹli gbé nínú àgọ́, nígbà tí mo mú wọn jáde ní Ejibiti. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.’ ”

44Báyìí ni Mose kéde àwọn àjọ̀dún tí a yàn Olúwa fún àwọn ọmọ Israẹli.