3. Mosebog 21 – BPH & YCB

Bibelen på hverdagsdansk

3. Mosebog 21:1-24

Regler for præsterne

1Herren sagde endvidere til Moses: „Sig til præsterne, at de ikke må gøre sig selv urene ved at røre et lig, 2-3medmindre det drejer sig om en nær slægtning: en mor, en far, en søn, en datter, en bror eller en ugift søster, som han har ansvaret for, siden hun ikke har nogen mand. 4Som leder blandt sit folk skal han passe på ikke at gøre sig selv uren.21,4 Den hebraiske tekst er uklar.

5Præsterne må ikke klippe sig skaldede noget sted på hovedet eller barbere deres kindskæg af. De må heller ikke lave ridser i huden eller tatoveringer. 6I Guds øjne skal de være hellige, og de må ikke krænke ham eller bringe skam over hans navn. Det er jo dem, der er udvalgt til at bringe ildofre til Herren, og de ofre skal kunne accepteres af deres Gud. 7En præst må ikke gifte sig med en prostitueret eller med en kvinde, som ikke er jomfru. Han må heller ikke gifte sig med en fraskilt, for han er en indviet Guds tjener, 8som er udvalgt til at bringe jeres ofre frem for Gud. Han skal være hellig, for jeg, Herren, som gør jer hellige, er selv hellig. 9Hvis en præstedatter bliver prostitueret, har hun krænket sin fars hellighed, og hun skal brændes.

10Ypperstepræsten, der er salvet og indviet til en særlig tjeneste, og som har fået lov at bære den ypperstepræstelige dragt, må ikke tage sin hovedbeklædning af og lade håret hænge løst eller rive flænger i sin dragt.21,10 Som tegn på sorg eller vrede. 11Han må heller ikke røre en død person, ikke engang sin egen mor eller far. 12Han må ikke krænke helligdommen ved at forlade den for at deltage i en begravelse, for han er salvet og indviet til at tjene Gud. Jeg er Herren. 13Den kvinde, han gifter sig med, skal være jomfru. 14-15Han må ikke gifte sig med en enke, og heller ikke med en fraskilt eller en prostitueret. Hans tilkommende skal være en jomfru fra hans egen præsteslægt, ellers ville hans sønner ikke være værdige til at overtage hans embede. Jeg er Herren, som gør ham hellig.”

16Og Herren sagde til Moses: 17„Sig til Aron, at hvis nogen af hans efterkommere har en legemsfejl, må vedkommende ikke bringe ofre til Gud. 18Ingen, der er blind eller lam, har et misdannet ansigt, en legemsdel, der er for lang, 19eller en forkrøblet fod eller hånd, 20er pukkelrygget eller dværg, eller har en fejl ved øjnene eller har udslæt, bylder eller deforme testikler, 21må bringe ofre ved Herrens alter, selv om han er en efterkommer af Aron. 22Men han må gerne spise af den mad, som tilkommer præsterne i forbindelse med ofringerne. 23På grund af sin fysiske defekt må han aldrig komme i nærheden af forhænget i helligdommen eller komme nær alteret, for derved ville han krænke helligdommen, og det er mig, Herren, som har gjort den hellig.”

24Moses gav så alle reglerne videre til Aron og hans sønner og alle israelitterne.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Lefitiku 21:1-24

Òfin fún àwọn àlùfáà

121.1-3: El 44.25.Olúwa sọ fún Mose wí pe, “Bá àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Aaroni sọ̀rọ̀, kí o sì sọ fún wọn pé: ‘Ẹnikẹ́ni nínú wọn kò gbọdọ̀ sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́ nítorí àwọn ènìyàn wọn tí ó kù. 2Ṣùgbọ́n bí ó bá ṣe àwọn tí ó súnmọ́ ọn bí ìyá rẹ̀, baba rẹ̀, ọmọ rẹ̀ ọkùnrin tàbí obìnrin, àti arákùnrin rẹ̀. 3Tàbí fún arábìnrin rẹ̀ tí kò ì tí ì wọ ilé ọkọ tí ó ń gbé lọ́dọ̀ rẹ̀. Nítorí tí arábìnrin bẹ́ẹ̀, ó lè sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́. 4Nítorí tí ó jẹ́ olórí, òun kò gbọdọ̀ sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ ba ara rẹ̀ jẹ́ láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀.

521.5: Le 19.27; De 14.1.“ ‘Àlùfáà kò gbọdọ̀ fá irun orí rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ rẹ́ irùngbọ̀n rẹ̀. Kò gbọdọ̀ fi abẹ ya ara rẹ̀ láti fihàn pé òun wà ní ipò ọ̀fọ̀. 6Wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́ fún Ọlọ́run, kí wọ́n má ba à sọ orúkọ Ọlọ́run wọn di àìmọ́, nítorí pé àwọn ni wọ́n ń fi iná sun ẹbọ sí Olúwa wọn, ti ó jẹ oúnjẹ Ọlọ́run wọn. Nítorí náà wọn gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́.

7“ ‘Àwọn àlùfáà kò gbọdọ̀ fẹ́ panṣágà tàbí obìnrin tí ó ti fi ọkùnrin ba ara rẹ̀ jẹ́ tàbí obìnrin tí ọkọ rẹ̀ ti kọ̀sílẹ̀ nítorí pé àwọn àlùfáà jẹ́ mímọ́ sí Ọlọ́run wọn. 8Àwọn ènìyàn gbọdọ̀ máa kà wọ́n sí mímọ́, nítorí pé àwọn ni wọ́n ń rú ẹbọ oúnjẹ fún mi. Èmi ni Olúwa, mo jẹ́ mímọ́, mo sì ya àwọn ènìyàn mi sí mímọ́.

9“ ‘Bí ọmọbìnrin àlùfáà kan bá fi iṣẹ́ àgbèrè ba ara rẹ̀ jẹ́: ó dójútì baba rẹ̀, iná ni a ó dá sun ún.

10“ ‘Lẹ́yìn tí a ti fi òróró yan olórí àlùfáà láàrín àwọn arákùnrin rẹ̀, tí a sì ti fi ààmì òróró yàn án láti máa wọ aṣọ àlùfáà, ó gbọdọ̀ tọ́jú irun orí rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ fa aṣọ rẹ̀ ya láti fihàn pé òun wà ní ipò ọ̀fọ̀. 11Kí ó ma ṣe wọlé tọ òkú lọ, kí ó má ṣe sọ ará rẹ di àìmọ́ nítorí baba tàbí nítorí ìyá rẹ̀. 12Kò gbọdọ̀ kúrò ní ibi mímọ́ Ọlọ́run tàbí kí ó sọ ọ́ di aláìmọ́ torí pé a ti fi ìfòróróyàn Ọlọ́run yà á sí mímọ́. Èmi ni Olúwa.

13“ ‘Ọmọbìnrin tí yóò fẹ́ gbọdọ̀ jẹ́ ẹni tí kò mọ Ọkùnrin rí. 14Kò gbọdọ̀ fẹ́ opó tàbí ẹni tí a kọ̀sílẹ̀ tàbí obìnrin tí ó ti fi àgbèrè ba ara rẹ̀ jẹ́, ṣùgbọ́n kí ó fẹ́ obìnrin tí kò mọ ọkùnrin rí, láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀. 15Kí ó má ba à sọ di aláìmọ́ nínú àwọn ènìyàn rẹ̀. Èmi ni Olúwa tí ó sọ ọ́ di mímọ́.’ ”

16Olúwa sì bá Mose sọ̀rọ̀ pé, 17“Sọ fún Aaroni pé: ‘Ẹnikẹ́ni nínú irú-ọmọ rẹ̀ ní ìran-ìran wọn, tí ó bá ní ààrùn kan, kí ó má ṣe súnmọ́ tòsí láti rú ẹbọ ohun jíjẹ sí Ọlọ́run rẹ̀. 18Ẹnikẹ́ni tí ó bá ní àbùkù kò gbọdọ̀ súnmọ́ ibi ẹbọ náà. Kò gbọdọ̀ sí afọ́jú tàbí arọ, alábùkù ara tàbí àwọn tí ara wọn kò pé. 19Kò gbọdọ̀ sí ẹnikẹ́ni yálà ó rọ lápá lẹ́sẹ̀, 20tàbí tí ó jẹ́ abuké, tàbí tí ó ya aràrá tàbí tí ó ní àìsàn ojú tàbí tí ó ní egbò tàbí tí a ti yọ nǹkan ọmọkùnrin rẹ̀. 21Ẹnikẹ́ni tí ó ní àbùkù nínú irú-ọmọ Aaroni àlùfáà kò gbọdọ̀ súnmọ́ tòsí láti rú ẹbọ tí fi iná sun sí Olúwa. Nítorí pé ó jẹ́ alábùkù, kò gbọdọ̀ súnmọ́ tòsí láti rú ẹbọ àkàrà sí Ọlọ́run rẹ̀. 22Ó lè jẹ́ oúnjẹ Ọlọ́run rẹ̀ tàbí èyí tí ó mọ́ jùlọ, ṣùgbọ́n torí pé ó ní àbùkù kò gbọdọ̀ súnmọ́ ibi aṣọ títa tàbí pẹpẹ. 23Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò ba ibi mímọ́ mi jẹ́ torí pé, Èmi Olúwa ló ti sọ wọ́n di mímọ́.’ ”

24Wọ̀nyí ni àwọn ohun tí Mose sọ fún Aaroni, àwọn ọmọ Aaroni àti gbogbo ọmọ Israẹli.