3. Mosebog 20 – BPH & YCB

Bibelen på hverdagsdansk

3. Mosebog 20:1-27

Straffen for afgudsdyrkelse og andre synder

1-2Herren befalede Moses at give Israels folk følgende instrukser:

„Enhver indfødt israelit eller fremmed iblandt jer, som overgiver sit barn til dyrkelsen af afguden Molok, skal stenes til døde af sine landsmænd. 3En sådan person vil jeg selv kæmpe imod og sørge for, at han bliver udryddet, for han har gjort min helligdom uren og krænket mit hellige navn. 4Hvis hans landsmænd ser igennem fingre med hans synd og nægter at slå ham ihjel, 5vil jeg selv sørge for at udrydde ham og alle andre af mit folk, der dyrker Molok.

6Jeg vil kæmpe imod enhver, som søger kontakt med de døde og henvender sig til sandsigere i stedet for at søge hjælp hos mig. De skal fuldstændig udryddes. 7Stræb efter hellighed, for jeg er Herren, jeres Gud. 8I skal adlyde alle mine bud, for jeg er Herren, som gør jer hellige.

9Enhver, som forbander sin far eller mor, skal lide døden.

10Hvis en mand begår ægteskabsbrud med en anden mands kone, skal både manden og kvinden dømmes til døden. 11Og hvis en mand har samleje med sin fars kone, har han krænket sin far og skal lide døden sammen med kvinden. 12Hvis en mand har samleje med sin svigerdatter, skal de begge lide døden, for de har begået en skammelig handling og må bære straffen derfor. 13Hvis en mand har seksuelt samvær med en anden mand, som en mand har det med en kvinde, skal de begge straffes med døden, for det er en afskyelig handling, som de begge har ansvaret for. 14Hvis en mand har samleje med både en mor og hendes datter, har de begået en afskyelig forbrydelse. Alle tre skal brændes, for den slags skammelige handlinger må ikke finde sted iblandt jer.

15Hvis en mand har samleje med et dyr, skal han henrettes og dyret slås ihjel. 16Det samme gælder, hvis en kvinde har samleje med et dyr: Hun fortjener dødsstraf for sin synd.

17Hvis en mand har samleje med sin søster, hvad enten hun er en datter af hans far eller mor, har han begået en skammelig handling, og begge skal henrettes offentligt. En sådan mand må bære straffen for sin synd. 18Hvis en mand har samleje med en kvinde under hendes menstruation, skal de begge dø, for manden har blottet hendes blods kilde, og hun har tilladt ham at gøre det.

19Seksuelt samvær mellem en mand og hans faster eller moster er forbudt, for de er nære slægtninge. Derfor skal de bære deres straf. 20Hvis en mand har samleje med sin farbrors kone, har han krænket sin farbror. Både han og kvinden må bære deres straf og dø uden børn. 21Hvis en mand har samleje med sin brors20,21 Så længe broderen endnu er i live. Jf. 5.Mos. 25,5. kone, er det en uren handling. Han har krænket sin bror, og både han og kvinden skal dø uden børn.

22I skal overholde alle mine love og forskrifter, så det land, jeg vil føre jer ind i, ikke skal spytte jer ud igen. 23I må ikke gøre som de folkeslag, jeg driver bort foran jer. De begår alle den slags handlinger, jeg her har advaret jer imod. Derfor afskyr jeg dem 24og har lovet jer, at I skal få deres land i eje. Det er et land, som flyder med mælk og honning. Jeg er Herren, jeres Gud, og jeg har udskilt jer fra de andre folkeslag.

25Derfor skal I skelne imellem de dyr og fugle, jeg har givet jer tilladelse til at spise, og dem, som jeg har forbudt jer at spise. I må ikke gøre jer selv til genstand for min afsky ved at spise fugle eller dyr, som jeg har forbudt jer at spise. 26I skal være hellige i mine øjne, for jeg, Herren, er hellig, og jeg har udskilt jer fra de øvrige folkeslag, så I kan være mit folk.

27Hvis en mand eller en kvinde har en dødemaners ånd i sig eller en spådomsånd, skal de stenes til døde.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Lefitiku 20:1-27

Ìjìyà fún ẹ̀ṣẹ̀

1Olúwa sọ fún Mose pé, 220.2-5: Le 18.21.“Sọ fún àwọn ará Israẹli pé: ‘Ẹnikẹ́ni nínú àwọn ará Israẹli tàbí àwọn àlejò tí ń gbé láàrín Israẹli, tí ó bá fi èyíkéyìí nínú àwọn ọmọ rẹ̀ fún Moleki, kí wọ́n pa á, kí àwọn olùgbé ilẹ̀ náà sọ ọ́ ní òkúta pa. 3Èmi tìkára mi yóò bínú sí irú ẹni bẹ́ẹ̀, ń ó sì gé e kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀ fún òrìṣà Moleki ó ti ba ibi mímọ́ mi jẹ́ pẹ̀lú. 4Bí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà bá mójú kúrò lára irú ẹni bẹ́ẹ̀ tí ó fi ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀ fún òrìṣà Moleki tí wọn kò sì pa irú ẹni bẹ́ẹ̀. 5Èmi yóò bínú sí irú ẹni bẹ́ẹ̀ àti gbogbo ìdílé rẹ̀, èmi yóò sì ké wọn kúrò láàrín àwọn ènìyàn wọn: òun àti gbogbo àwọn tí ó jọ ṣe àgbèrè tọ òrìṣà Moleki lẹ́yìn.

620.6: Le 19.31.“ ‘Bí ẹnikẹ́ni bá tọ àwọn abókùúsọ̀rọ̀ àti àwọn ẹlẹ́mìí òkùnkùn lọ, tí ó sì ṣe àgbèrè tọ̀ wọ́n lẹ́yìn: Èmi yóò bínú sí irú ẹni bẹ́ẹ̀; Èmi yóò sì gé e kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀.

720.7: Le 11.44,45; 19.2; 20.26; 1Pt 1.16.“ ‘Torí náà ẹ ya ara yín sí mímọ́ kí ẹ sì jẹ́ mímọ́, torí pé, èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín. 8Ẹ máa kíyèsi àṣẹ mi, kí ẹ sì máa pa wọ́n mọ́: Èmi ni Olúwa tí ó sọ yín di mímọ́.

920.9: Ek 21.17; De 27.16.“ ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣépè lé baba tàbí ìyá rẹ̀ ni kí ẹ pa, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wà lórí ara rẹ̀ torí pé ó ti ṣépè lé baba àti ìyá rẹ̀.

1020.10: Ek 20.14; Le 18.20; De 5.18.“ ‘Bí ẹnikẹ́ni bá bá aya aládùúgbò rẹ̀ lòpọ̀: ọkùnrin àti obìnrin náà ni kí ẹ sọ ní òkúta pa.

1120.11: Le 18.7,8.“ ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá bá aya baba rẹ̀ lòpọ̀ ti tàbùkù baba rẹ̀. Àwọn méjèèjì ni kí ẹ pa. Ẹ̀jẹ̀ wọn yóò wà lórí wọn.

1220.12: Le 18.15.“ ‘Bí ọkùnrin kan bá bá arábìnrin ìyàwó rẹ̀ lòpọ̀, àwọn méjèèjì ni kí ẹ pa, wọ́n ti ṣe ohun tí ó lòdì, ẹ̀jẹ̀ wọn yóò wà lórí wọn.

1320.13: Le 18.22.“ ‘Bí ọkùnrin kan bá bá ọkùnrin mìíràn lòpọ̀ bí wọ́n ti í bá obìnrin lòpọ̀: àwọn méjèèjì ti ṣe ohun ìríra: pípa ni kí ẹ pa wọ́n, ẹ̀jẹ̀ wọn yóò wà lórí wọn.

1420.14: Le 18.17; De 27.23.“ ‘Bí ọkùnrin kan bá fẹ́ tìyátọmọ papọ̀: ìwà búburú ni èyí: iná ni kí ẹ fi sun wọ́n, òun àti àwọn méjèèjì, kí ìwà búburú má ba à gbilẹ̀ láàrín yín.

1520.15,16: Le 18.23.“ ‘Bí ọkùnrin kan bá bá ẹranko lòpọ̀, ẹ gbọdọ̀ pa ọkùnrin náà àti ẹranko náà.

16“ ‘Bí obìnrin kan bá súnmọ́ ẹranko tí ó sì bá a lòpọ̀ obìnrin náà àti ẹranko náà ni kí ẹ pa: ẹ̀jẹ̀ wọn yóò sì wà lórí ara wọn.

1720.17: Le 18.9.“ ‘Bí ọkùnrin kan bá fẹ́ arábìnrin rẹ̀ yálà ọmọbìnrin baba rẹ̀ tàbí ọmọbìnrin ìyá rẹ̀ tí ó sì bá a lòpọ̀, ohun ìtìjú ni èyí: Ẹ ó gé wọn kúrò lójú àwọn ènìyàn wọn: ó ti tàbùkù arábìnrin rẹ̀. Ẹ̀bi rẹ̀ yóò wá sórí rẹ̀.

1820.18: Le 15.24; 18.19.“ ‘Bí ọkùnrin kan bá súnmọ́ obìnrin, ní àkókò nǹkan oṣù rẹ̀ tí ó sì bá a lòpọ̀. Ó ti tú orísun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. Òun náà sì gbà á láààyè. Àwọn méjèèjì ni a ó gé kúrò láàrín àwọn ènìyàn wọn.

1920.19: Le 18.12,13.“ ‘Má ṣe bá arábìnrin baba tàbí ti ìyá rẹ lòpọ̀, nítorí o ti tú ìhòhò ìbátan rẹ: Ẹ̀yin méjèèjì ni yóò ru ẹ̀bi yín.

2020.20: Le 18.14.“ ‘Bí ọkùnrin kan bá bá aya arákùnrin baba rẹ̀ lòpọ̀ ó ti tàbùkù arákùnrin baba rẹ̀. A ó jẹ wọ́n ní ìyà; wọn yóò sì kú láìlọ́mọ.

2120.21: Le 18.16.“ ‘Bí ọkùnrin kan bá gba aya arákùnrin rẹ̀, ohun àìmọ́ ni èyí, ó ti tàbùkù arákùnrin rẹ̀, wọn ó wà láìlọ́mọ.

22“ ‘Kí ẹ pa gbogbo àṣẹ àti òfin mi mọ́, kí ẹ sì máa ṣe wọ́n. Kí ilẹ̀ náà tí èmi ó fi fún yín láti máa gbé má ba à pọ̀ yín jáde. 23Ẹ má ṣe tẹ̀lé àṣà àwọn orílẹ̀-èdè tí mo lé jáde níwájú yín torí pé gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni wọ́n ń ṣe, tí mo kórìíra wọn. 24Ṣùgbọ́n mo ti sọ fún yín pé, “Ẹ̀yin ni yóò jogún ilẹ̀ wọn; Èmi yóò sì fi fún yín láti jogún ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin.” Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín tí ó ti yà yín sọ́tọ̀ kúrò láàrín àwọn ènìyàn yòókù.

25“ ‘Ẹ gbọdọ̀ pààlà sáàrín ẹran tí ó mọ́ àti àwọn tí kò mọ́. Láàrín ẹyẹ tí ó mọ́ àti àwọn tí kò mọ́. Ẹ má ṣe sọ ara yín di àìmọ́ nípasẹ̀ àwọn ẹranko tàbí ẹyẹ tàbí ohunkóhun tí ń rìn lórí ilẹ̀: èyí tí mo yà sọ́tọ̀ fún yín gẹ́gẹ́ bí ohun àìmọ́. 2620.26: Le 20.7.Ẹ gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́ fún mi torí pé èmi Olúwa fẹ́ mímọ́. Mó sì ti yà yín kúrò nínú àwọn orílẹ̀-èdè yòókù kí ẹ le jẹ́ tèmi.

2720.27: Le 19.31; 20.6.“ ‘Ọkùnrin tàbí obìnrin tí ó jẹ́ abókùúsọ̀rọ̀ tàbí oṣó láàrín yín ni kí ẹ pa. Ẹ sọ wọ́n ní òkúta, ẹ̀jẹ̀ wọn yóò wà lórí wọn.’ ”