3. Mosebog 18 – BPH & YCB

Bibelen på hverdagsdansk

3. Mosebog 18:1-30

Forbud imod seksuelle perversiteter

1-2Herren befalede Moses at sige til Israels folk: „Jeg er Herren, jeres Gud! 3Derfor må I ikke opføre jer som egypterne, I engang boede iblandt, eller som kana’anæerne, der bor i det land, jeg vil føre jer ind i. I må ikke lade jer påvirke af deres livsførelse. 4I skal adlyde mine love og forskrifter, for jeg er Herren, jeres Gud. 5Den, der overholder alle disse love, vil få livet derved. Jeg er Herren!

6Ingen af jer må have seksuelt samvær med en nær slægtning, siger jeg, Herren. 7-8Det vil sige: Du må ikke have seksuelt samvær med din mor eller din stedmor. Derved vanærer du din far. 9-11Du må ikke have seksuelt samvær med din søster eller halvsøster, hvad enten din halvsøster er en datter af din far eller din mor, og hvad enten hun er opvokset sammen med dig eller et andet sted. Du må ikke have seksuelt samvær med dit barnebarn, hvad enten hun er datter af din søn eller af din datter. Hun er jo dit eget kød og blod. 12-14Det samme gælder din faster, din moster og din farbrors kone. De er nære slægtninge, og du må ikke have noget seksuelt forhold til nogen af dem.

15-16Du må heller ikke stå i seksuelt forhold til din søns kone eller din brors kone. 17Du må ikke gifte dig med både en mor og hendes datter eller barnebarn. De er nære slægtninge, og du begår en stor synd ved at have et seksuelt forhold til dem begge. 18Du må heller ikke gifte dig med to søstre og have et seksuelt forhold til dem begge. Først efter din kones død, kan du gifte dig med hendes søster.

19Du må ikke have seksuelt samvær med en kvinde under hendes menstruation. 20Du må ikke gøre dig selv uren ved at have et seksuelt forhold til en anden mands kone.

21Du må ikke overgive nogen af dine børn til dyrkelsen af afguden Molok, for derved krænker du Herren, din Gud.

22En mand må ikke have seksuelt samvær med en mand, som hvis det var en kvinde—det er en afskyelighed. 23En mand må ikke gøre sig uren ved at have seksuel omgang med et dyr. En kvinde må heller ikke hengive sig seksuelt til et dyr—det er perverst og afskyeligt.

24Pas på ikke at gøre jer selv urene ved nogen af disse ting. De folkeslag, jeg driver bort foran jer, gør den slags ting. 25Hele Kana’ans land er fuld af den slags perversiteter, og derfor vil jeg straffe befolkningen og landet selv skal spytte dem ud. 26I skal omhyggeligt adlyde alle mine love og forskrifter, så I ikke gør jer skyldige i nogen af de her afskyelige handlinger. Og mine love gælder både for de indfødte israelitter og de fremmede iblandt jer.

27De her afskyelige handlinger er længe blevet praktiseret af befolkningen i det land, jeg vil føre jer ind i, og derfor er landet blevet urent. 28Følg under ingen omstændigheder deres skræmmende eksempel, for hvis I gør det, vil landet også spytte jer ud, nøjagtig som det snart vil spytte de nuværende indbyggere ud. 29Enhver, som gør sådan noget, skal dø. 30Sørg derfor for at adlyde mine love, så I ikke optager nogen af den slags afskyelige skikke iblandt jer. Nej, gør jer ikke urene ved at handle som indbyggerne i det land, jeg vil føre jer ind i, for jeg er Herren, jeres Gud.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Lefitiku 18:1-30

Ìbálòpọ̀ tí kò bá òfin mu

1Olúwa sọ fún Mose pé: 2“Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé: ‘èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín. 3Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe bí wọ́n ti ń ṣe ní Ejibiti níbi tí ẹ ti gbé rí: bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe bí wọ́n ti ń ṣe ní ilẹ̀ Kenaani níbi tí èmi ń mú yín lọ. Ẹ kò gbọdọ̀ tẹ̀lé ìṣe wọn. 4Kí ẹ̀yin kí ó sì máa ṣe òfin mi, kí ẹ̀yin sì máa pa ìlànà mi mọ́, láti máa rìn nínú wọn, Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín. 518.5: Lk 10.28; Ro 10.5; Ga 3.12. Ẹ̀yin ó sì máa pa ìlànà mi mọ́ àti òfin mi; Ẹni tí ó ba ṣe, yóò yè nípa wọn: Èmi ni Olúwa.

6“ ‘Ẹnikẹ́ni nínú yín kò gbọdọ̀ súnmọ́ ìbátan rẹ̀ láti bá a lòpọ̀, èmí ni Olúwa.

718.7: Le 20.11.“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ tàbùkù baba rẹ nípa bíbá ìyá rẹ lòpọ̀, ìyá rẹ̀ ni, ìwọ kò gbọdọ̀ bá a lòpọ̀.

8“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ tàbùkù baba rẹ nípa bíbá ìyàwó baba rẹ lòpọ̀: nítorí ìhòhò baba rẹ ni.

918.9,11: Le 20.17; De 27.22.“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá arábìnrin rẹ tí ó jẹ́ ọmọ ìyá rẹ lòpọ̀, yálà a bí i nílé yín tàbí lóde.

10“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá ọmọbìnrin, ọmọ rẹ ọkùnrin lòpọ̀ tàbí ọmọbìnrin ọmọ rẹ obìnrin lòpọ̀ nítorí pé ìhòhò wọn, ìhòhò ìwọ fúnrarẹ̀ ni.

11“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá ọmọbìnrin aya baba rẹ lòpọ̀; èyí tí a bí fún baba rẹ nítorí pé arábìnrin rẹ ni.

1218.12: Le 20.19.“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá arábìnrin baba rẹ lòpọ̀ nítorí pé ìbátan baba rẹ ni.

13“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá arábìnrin màmá rẹ lòpọ̀ nítorí pé ìbátan ìyá rẹ ni.

1418.14: Le 20.20.“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ tàbùkù arákùnrin baba rẹ: nípa sísún mọ́ aya rẹ̀ láti bá a lòpọ̀ nítorí pé ìyàwó ẹ̀gbọ́n baba rẹ ni.

1518.15: Le 20.12.“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá ọmọ àna obìnrin rẹ lòpọ̀ nítorí pé aya ọmọ rẹ ni. Má ṣe bá a lòpọ̀.

1618.16: Le 20.21.“ ‘Má ṣe bá aya ẹ̀gbọ́n rẹ ọkùnrin lòpọ̀ nítorí pé yóò tàbùkù ẹ̀gbọ́n rẹ.

1718.17: Le 20.14.“ ‘Má ṣe bá ìyá àti ọmọ rẹ obìnrin lòpọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ bá ọmọbìnrin ọmọkùnrin rẹ tàbí ọmọbìnrin ọmọbìnrin rẹ lòpọ̀ nítorí pé ìbátan rẹ tímọ́tímọ́ ni: nítorí àbùkù ni.

18“ ‘Má ṣe fẹ́ àbúrò ìyàwó rẹ obìnrin ní aya gẹ́gẹ́ bí orogún tàbí bá a lòpọ̀, nígbà tí ìyàwó rẹ sì wà láààyè.

1918.19: Le 15.24; 20.18.“ ‘Má ṣe súnmọ́ obìnrin láti bá a lòpọ̀ nígbà tí ó bá ń ṣe nǹkan oṣù, nítorí àkókò àìmọ́ ni.

20“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá aya aládùúgbò rẹ lòpọ̀, kí ìwọ má ba à ba ara rẹ jẹ́ pẹ̀lú rẹ̀.

2118.21: Le 20.2-5.“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ fi èyíkéyìí nínú àwọn ọmọ rẹ rú ẹbọ lórí pẹpẹ sí òrìṣà Moleki, kí o sì tipa bẹ́ẹ̀ ba orúkọ Ọlọ́run rẹ jẹ́. Èmi ni Olúwa.

2218.22: Le 20.13; De 23.18.“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá ọkùnrin lòpọ̀ bí ìgbà tí ènìyàn ń bá obìnrin lòpọ̀: ìríra ni èyí jẹ́.

2318.23: Ek 22.19; Le 20.15,16; De 27.21.“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá ẹranko lòpọ̀ kí ìwọ má ba à ba ara rẹ jẹ́. Obìnrin kò sì gbọdọ̀ jọ̀wọ́ ara rẹ̀ sílẹ̀ fún ẹranko láti bá a lòpọ̀, ohun tó lòdì ni.

24“ ‘Má ṣe fi àwọn nǹkan wọ̀nyí ba ara rẹ jẹ́, torí pé nínú àwọn nǹkan wọ̀nyí ni àwọn orílẹ̀-èdè tí mo lé kúrò níwájú yín ti ba ara wọn jẹ́. 25Nítorí pé ilẹ̀ náà di àìmọ́ nítorí náà mo fi ìyà jẹ ẹ́ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Ilẹ̀ náà sì pọ àwọn olùgbé ibẹ̀ jáde. 26Ṣùgbọ́n kí ẹ máa pa àṣẹ àti òfin mi mọ́. Onílé tàbí àjèjì tó ń gbé láàrín yín kò gbọdọ̀ ṣe ọ̀kan nínú àwọn ohun ìríra wọ̀nyí. 27Nítorí pé gbogbo ohun ìríra wọ̀nyí ni àwọn ènìyàn tí wọ́n ti gbé ilẹ̀ náà ṣáájú yín ti ṣe tí ó sì mú kí ilẹ̀ náà di aláìmọ́. 28Bí ẹ bá sọ ilẹ̀ náà di àìmọ́ yóò pọ̀ yín jáde bí ó ti pọ àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ti wá ṣáájú yín jáde.

29“ ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe ohun ìríra wọ̀nyí, kí ẹ gé irú ẹni náà kúrò láàrín àwọn ènìyàn. 30Nítorí náà ẹ gbọdọ̀ ṣe ohun tí mo fẹ́, kí ẹ má sì lọ́wọ́ nínú àṣà ìríra wọ̀nyí, tí wọn ń ṣe kí ẹ tó dé. Ẹ má ṣe fi wọ́n ba ara yín jẹ́. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.’ ”