2. Samuelsbog 10 – BPH & YCB

Bibelen på hverdagsdansk

2. Samuelsbog 10:1-19

Davids sejr over ammonitterne og aramæerne

1Nogen tid efter døde ammonitternes konge, Nahash, og han blev efterfulgt af sønnen Hanun.

2„Ham vil jeg vise venlighed,” tænkte David, „for hans far viste venlighed mod mig.” Så sendte David nogle sendebud af sted for at kondolere i anledning af faderens død.

3Men de ammonitiske officerer sagde til Hanun: „De mænd er ikke kommet for at ære din fars minde! Nej, det er blot et påskud for at udspionere os, for i virkeligheden har David i sinde at angribe os.”

4Derfor lod Hanun Davids mænd pågribe, hvorefter man vanærede dem ved at barbere den ene side af deres skæg af. Samtidig blev deres tøj skåret af over bagdelen, og sådan blev de sendt hjem. 5Da David fik at vide, at hans sendebud var blevet så groft ydmyget, sendte han nogle af sine embedsmænd ud for at møde dem og give dem besked på at blive i Jeriko, indtil deres skæg var vokset ud igen.

6Ammonitterne blev klar over, at David var rasende på dem på grund af det, de havde gjort. Derfor hvervede de 20.000 aramæiske lejesoldater fra områderne ved Rehob og Zoba, 1000 mand fra kongen af Ma’aka og 12.000 mand fra Tob. 7Da David fik det at vide, sendte han straks Joab og Israels bedste styrker af sted imod dem. 8Ammonitterne tog opstilling foran byporten, mens mændene fra Zoba, Rehob, Tob og Ma’aka tog opstilling på den åbne slette. 9-10Derved blev Joab tvunget til at kæmpe på to fronter, så han delte styrkerne imellem sig selv og sin bror Abishaj. Selv tog han elitesoldaterne og rykkede ud mod aramæerne på sletten, mens han overlod resten af hæren til Abishaj, der skulle kæmpe imod ammonitterne foran byporten.

11„Hvis jeg får brug for hjælp mod aramæerne, må du komme med det samme!” beordrede Joab. „Og hvis det viser sig, at du får besvær med ammonitterne, kommer jeg dig til hjælp. 12Vær nu ved godt mod! Vi må være tapre, hvis vi skal gøre os håb om at redde vores folk og vores Guds byer. Herrens vilje ske!”

13Så gik Joab og hans krigere til angreb, og aramæerne flygtede. 14Da ammonitterne så det, flygtede de også og søgte tilflugt inden for bymuren. Derefter vendte Joab tilbage til Jerusalem med sin hær.

15Da aramæerne indså, at de ikke kunne stå sig mod israelitterne, søgte de forstærkning. 16Kong Hadadezer fik samlet en hær af aramæere fra den anden side af Eufratfloden, og de ankom til Helam, anført af Shobak, kong Hadadezers hærfører.

17Da David hørte det, samlede han hele Israels hær og gik i spidsen for den over Jordanfloden til Helam, hvor de blev angrebet af aramæerne. 18Aramæerne led store tab og måtte igen tage flugten. David og hans hær dræbte 70010,18 Der skulle nok have stået 7000, jf. 1.Krøn. 19,18. aramæiske vognkæmpere og 40.000 fodfolk, deriblandt hærføreren Shobak. 19Da Hadadezers vasalkonger så, at aramæerne var blevet slået, sluttede de fred med israelitterne og blev underlagt Israels herredømme. Fra da af turde aramæerne ikke længere hjælpe ammonitterne.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Samuẹli 10:1-19

Dafidi ṣẹ́gun Ammoni

110.1-19: 1Ki 19.1-19.Ó sì ṣe lẹ́yìn èyí, ọba àwọn ará Ammoni sì kú, Hanuni ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. 2Dafidi sì wí pé, “Èmi yóò ṣe oore fún Hanuni ọmọ Nahaṣi gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ sì ti ṣe oore fún mi.” Dafidi sì ránṣẹ́ láti tù Hanuni nínú láti ọwọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wá, nítorí ti baba rẹ̀.

Àwọn ìránṣẹ́ Dafidi sì wá sí ilé àwọn ọmọ Ammoni. 3Àwọn olórí àwọn ọmọ Ammoni sì wí fún Hanuni olúwa wọn pé, “Ǹjẹ́ o rò pé Dafidi ń bu ọlá fún baba rẹ nígbà tí ó rán ènìyàn wá láti bá ọ kẹ́dùn? Kò ha ṣe pé Dafidi rán àwọn ìránṣẹ́ sí ọ láti wo ìlú àti láti yọ́ ọ wò àti láti gbà ọ́.” 4Hanuni sì mú àwọn ìránṣẹ́ Dafidi ó fá apá kan irùngbọ̀n wọn, ó sì gé ààbọ̀ kúrò ní agbádá wọn, títí ó fi dé ìdí wọn, ó sì rán wọn lọ.

5Wọ́n sì sọ fún Dafidi, ó sì ránṣẹ́ lọ pàdé wọn, nítorí tí ojú ti àwọn ọkùnrin náà púpọ̀: ọba sì wí pé, “Ẹ dúró ní Jeriko títí irùngbọ̀n yín yóò fi hù, nígbà náà ni kí ẹ tó máa bọ̀.”

Àwọn ogun Siria àti Ammoni sá níwájú Israẹli

6Àwọn ará Ammoni sì ri pé, wọ́n di ẹni ìríra níwájú Dafidi, àwọn ọmọ Ammoni sì ránṣẹ́, wọ́n sì fi owó bẹ́ ogún àwọn ará Siria ti Beti-Rehobu; àti Siria-Soba, ẹgbàáwàá ẹlẹ́ṣẹ̀ àti ti ọba Maaka, ẹgbẹ̀rún ọkùnrin àti ti Tobu ẹgbàafà ọkùnrin lọ́wẹ̀.

7Dafidi sì gbọ́, ó sì rán Joabu, àti gbogbo ogún àwọn ọkùnrin alágbára. 8Àwọn ọmọ Ammoni sì jáde wá, wọ́n sì tẹ́ ogun ní ẹnu odi; ará Siria-Soba, àti ti Rehobu, àti Tobu, àti Maaka, wọ́n sì tẹ ogun ni pápá fún ara wọn.

9Nígbà tí Joabu sì rí i pé ogun náà dojúkọ òun níwájú àti lẹ́yìn, ó sì yàn nínú gbogbo àwọn akíkanjú ọkùnrin ní Israẹli, ó sì tẹ́ ogun kọjú sí àwọn ará Siria. 10Ó sì fi àwọn ènìyàn tí ó kù lé Abiṣai àbúrò rẹ̀ lọ́wọ́, kí ó lè tẹ ogun kọjú sí àwọn ọmọ Ammoni. 11Ó sì wí pé, “Bí agbára àwọn ará Siria bá pọ̀ ju èmi lọ, ìwọ yóò sì wá ràn mí lọ́wọ́: ṣùgbọ́n bí ọwọ́ àwọn ọmọ Ammoni bá sì pọ̀jù ọ́ lọ, èmi ó sì wá ràn ọ́ lọ́wọ́. 12Mú ọkàn lè, jẹ́ kí a ṣe onígboyà nítorí àwọn ènìyàn wa, àti nítorí àwọn ìlú Ọlọ́run wa; Olúwa yóò sì ṣe èyí tí ó dára lójú rẹ̀.”

13Joabu àti àwọn ènìyàn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ sì bá àwọn ará Siria pàdé ìjà: wọ́n sì sá níwájú rẹ̀. 14Nígbà tí àwọn ọmọ Ammoni sì rí i pé àwọn ará Siria sá, àwọn pẹ̀lú sì sá níwájú Abiṣai, wọ́n sì wọ inú ìlú lọ. Joabu sì padà kúrò lẹ́yìn àwọn ọmọ Ammoni, ó sì wá sí Jerusalẹmu.

Ìṣẹ́gun lórí ogun Ammoni àti Siria ní Helami

15Nígbà tí àwọn ará Siria sì rí i pé Àwọn ṣubú níwájú Israẹli: wọ́n sì kó ara wọn jọ 16Hadadeseri sì ránṣẹ́, ó sì mú àwọn Siria tí ó wà ní òkè odò Eufurate jáde wá: wọ́n sì wá sí Helami; Sobaki olórí ogun Hadadeseri sì ṣe olórí wọn.

17Nígbà tí a sọ fún Dafidi, ó sì kó gbogbo Israẹli jọ, wọ́n sì kọjá Jordani, wọ́n sì wá sí Helami, Àwọn ará Siria sì tẹ́ ogun kọjú sí Dafidi, wọ́n sì bá a jà. 18Àwọn ará Siria sì sá níwájú Israẹli, Dafidi sì pa nínú àwọn ará Siria ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin àwọn oníkẹ̀kẹ́, àti ọ̀kẹ́ méjì ẹlẹ́ṣin, wọ́n sì kọlu Sobaki olórí ogun wọn, ó sì kú níbẹ̀. 19Nígbà tí gbogbo àwọn ọba tí ó wà lábẹ́ Hadadeseri sì rí i pé wọ́n di bíbì ṣubú níwájú Israẹli, wọ́n sì bá Israẹli làjà, wọ́n sì ń sìn wọ́n.

Àwọn ará Siria sì bẹ̀rù láti máa ran àwọn ọmọ Ammoni lọ́wọ́ mọ́.