2. Mosebog 36 – BPH & YCB

Bibelen på hverdagsdansk

2. Mosebog 36:1-38

1Alle andre kunstnere og kunsthåndværkere med gudgivne evner skal hjælpe Betzalel og Oholiab med at konstruere og indrette helligdommen, sådan som Herren har befalet.”

2Moses samlede nu Betzalel, Oholiab og de øvrige kunstnere og kunsthåndværkere med gudgivne evner, som ønskede at være med til arbejdet, 3og han overlod dem alle de materialer, som folket havde givet til helligdommens opførelse. De frivillige gaver blev ved med at strømme ind, dag efter dag, 4og arbejdet gik godt fremad. En dag kom alle kunsthåndværkerne fra de forskellige arbejdsgrene 5til Moses og sagde: „Vi har rigeligt med materialer til arbejdet, men folk bliver ved med at komme med mere.” 6Så lod Moses bekendtgøre i hele lejren: „I skal ikke bringe flere materialer!” Så holdt folk op med at komme med flere gaver, 7og der var mere end nok til at fuldføre alt arbejdet.

Opførelsen af boligen

8De dygtige kunsthåndværkere begyndte med at lave de ti stofbaner af fintvævet linned med broderede keruber i blåt, violet og purpurrødt garn. 9De ti stofbaner havde alle samme mål, 12,6 m i længden og 1,8 m i bredden. 10De blev syet sammen fem og fem, så de dannede to store stykker teltdug. 11Så blev der lavet løkker af blåt garn i kanten af den sidste bane på hvert af de to sammensyede stykker, 1250 løkker på hvert stykke, så de sad over for hinanden. 13Derefter blev der lavet 50 guldkroge til at holde løkkerne sammen to og to, således at de to stykker dannede en enhed.

14Yderteltdugen blev lavet af 11 gedehårstæpper. 15Alle tæppestykkerne havde samme mål, 13,5 m i længden og 1,8 m i bredden. 16De fem af tæpperne blev syet sammen til ét stykke, og de seks andre til et andet stykke. 17Så blev der lavet 50 løkker på hver af de to stykkers yderbaner 18og 50 små bronzehægter til at holde løkkerne sammen, så de to stykker dannede en enhed. 19Ovenover blev der udspændt en presenning af rødfarvede vædderskind, og ovenpå igen en presenning af kraftigt læder.

20Til boligens sider blev der lavet moduler af akacietræ. 21Modulernes mål var 4,5 m i højden og 67 cm i bredden, 22og de havde hver to tapper forneden. 23Boligens sydside bestod af 20 moduler, 24som stod på 40 sølvsokler, to sokler under hvert modul. 25-26Nordsiden bestod også af 20 moduler på 40 sølvsokler, to sokler under hvert modul. 27Boligens vestside, som var bagsiden, bestod af seks moduler 28plus et særligt modul i hvert hjørne. 29Hjørnemodulerne blev holdt sammen med beslag forneden og med en ring foroven. 30Vestsiden bestod altså i alt af otte moduler med 16 sølvsokler nedenunder, to sokler for hvert modul.

31-32Der blev også lavet 15 sæt tværstænger af akacietræ til at holde modulerne sammen, fem sæt til hver af de tre sider af boligen. 33Den midterste af de fem tværstænger blev fastspændt halvvejs oppe på vægmodulerne og nåede fra det ene hjørne til det andet. 34Både moduler og tværstænger blev belagt med guld, og de ringe, stængerne sad fast i, blev støbt i rent guld.

35Teltets indre forhæng blev lavet af fintvævet linned med kunstnerisk broderede keruber i blåt, violet og purpurrødt garn. 36Der blev lavet fire stolper af akacietræ belagt med guld, som blev rejst på fire sokler af sølv. Foroven på hver stolpe var der en krog af guld, som forhænget blev hængt op på.

37Til sidst blev der lavet et forhæng til boligens indgang. Forhænget var lavet af fintvævet linned med blå, violette og purpurrøde broderier på. 38Det blev hængt op på fem stolper, som hver havde en krog foroven. Stolperne, deres hoveder og tværstænger blev belagt med guld, og deres fem sokler var støbt i bronze.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Eksodu 36:1-38

1Besaleli, Oholiabu àti olúkúlùkù ọlọ́gbọ́n ẹni tí Olúwa tí fún ní ọgbọ́n àti òye láti mọ bí a ti í ṣe gbogbo iṣẹ́ ibi mímọ́ ni kí wọn ṣe iṣẹ́ náà gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ.”

2Mose sì pe Besaleli àti Oholiabu àti gbogbo ọlọ́gbọ́n ènìyàn ẹni tí Olúwa ti fún ni agbára àti gbogbo ẹni tí ó fẹ́ láti wá sé iṣẹ́ náà. 3Wọ́n gba gbogbo ọrẹ tí àwọn ọmọ Israẹli ti mú wá lọ́wọ́ Mose fún kíkọ́ ibi mímọ́ náà. Àwọn ènìyàn sì ń mú ọrẹ àtinúwá wá ní àràárọ̀. 4Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn ọlọ́gbọ́n oníṣẹ́-ọnà tí wọn ń ṣe gbogbo iṣẹ́ ibi mímọ́ náà fi iṣẹ́ wọn sílẹ̀. 5Mose sì wí pé, “Àwọn ènìyàn mú púpọ̀ wá fún ṣíṣe iṣẹ́ náà ju bi Olúwa ti pa á láṣẹ láti ṣe lọ.”

6Mose sì pàṣẹ, wọ́n sì rán iṣẹ́ yìí sí gbogbo ibùdó: “Kí ọkùnrin tàbí obìnrin má ṣe ṣe ohun kankan bí ọrẹ fún ibi mímọ́ náà mọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni a dá àwọn ènìyàn lẹ́kun láti mú un wá sí i, 7nítorí ohun tí wọ́n ti ní ti ju ohun tí wọn fẹ́ fi ṣe gbogbo iṣẹ́ náà lọ.

Àgọ́ náà

836.8-19: Ek 26.1-14.Gbogbo àwọn ọlọ́gbọ́n ọkùnrin láàrín àwọn òṣìṣẹ́ ni wọ́n ṣe iṣẹ́ náà pẹ̀lú aṣọ títa mẹ́wàá ti ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára, tí aṣọ aláró, ti elése àlùkò àti ti òdòdó, pẹ̀lú àwọn kérúbù ṣe iṣẹ́ sí wọn nípa ọgbọ́n iṣẹ́ ọnà. 9Gbogbo aṣọ títa náà ni kí ó jẹ́ ìwọ̀n kan náà: ìgbọ̀nwọ́ méjì-dínlọ́gbọ̀n ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin ni fífẹ̀. 10Aṣọ títa márùn-ún ni kí a so papọ̀ mọ́ ara wọn, àti aṣọ títa márùn-ún ni kí a so papọ̀ mọ́ ara wọn. 11Ìwọ yóò ṣì ṣe ajábó aṣọ aláró sí aṣọ títa kan láti ìṣẹ́tí rẹ̀ wá níbi ìsopọ̀, àti bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ìwọ yóò ṣe ni etí ìkangun aṣọ títa kejì, ni ibi ìsopọ̀ kejì. 12Àádọ́ta ajábó ní ó pa lára aṣọ títa kan, àti àádọ́ta ajábó ni ó sì lò pa ní etí aṣọ títa tí ó wà ní ìsolù kejì, ajábó náà sì wà ní ọ̀kánkán ara wọn. 13Ó sì ṣe àádọ́ta ìkọ́ wúrà, ó sì lò ìkọ́ wọ̀n-ọn-nì láti fi aṣọ títa kan kọ́ èkejì, bẹ́ẹ̀ ó sì di odidi àgọ́ kan.

14Ìwọ ó sì ṣe aṣọ títa irun ewúrẹ́ láti fi ṣe ìbò sórí àgọ́ náà—aṣọ títa mọ́kànlá ni ìwọ ó ṣe é. 15Gbogbo aṣọ títa mọ́kọ̀ọ̀kànlá náà jẹ́ ìwọ̀n kan náà, ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin ní fífẹ̀. 16Ó so aṣọ títa márùn-ún pọ̀ mọ́ ara wọn se ọ̀kan, ó sì tún so mẹ́fà tókù mọ́ ara wọn se ọ̀kan. 17Ó sì pa àádọ́ta ajábó sí ìṣẹ́tí ìkangun aṣọ títa ní apá kan, wọ́n sì tún pa ajábó mìíràn sí ìṣẹ́tí ìkangun aṣọ títa ní apá kejì. 18Wọ́n ṣe àádọ́ta (50) ìkọ́ idẹ láti so àgọ́ náà pọ̀ kí o lè jẹ́ ọ̀kan. 19Ó sì ṣe ìbòrí awọ àgbò tí a rì ní pupa fún àgọ́ náà, àti ìbòrí awọ seali sórí rẹ̀.

2036.20-34: Ek 26.15-29.Ó sì ṣe pákó igi kasia tí ó dúró òró fún àgọ́ náà. 21Ọ̀kọ̀ọ̀kan pákó náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ní fífẹ̀, 22pẹ̀lú ìtẹ̀bọ̀ méjì tí ó kọjú sí ara wọn. Wọ́n ṣe gbogbo pákó àgọ́ náà bí èyí. 23Ó sì ṣe ogún pákó sí ìhà gúúsù àgọ́ náà. 24Ó sì ṣe ogójì (40) fàdákà ihò ìtẹ̀bọ̀ lọ sí ìsàlẹ̀ wọn ìtẹ̀bọ̀ méjì fún pákó kọ̀ọ̀kan, ọ̀kọ̀ọ̀kan ní ìsàlẹ̀ ìtẹ̀bọ̀. 25Fún ìhà kejì, ìhà àríwá àgọ́ náà, wọ́n ṣe ogún pákó 26àti ogójì ihò ìtẹ̀bọ̀ fàdákà méjì ní abẹ́ pákó kọ̀ọ̀kan. 27Ó ṣe pákó mẹ́fà sì ìkangun, ní ìkangun ìhà ìwọ̀-oòrùn àgọ́ náà, 28pákó méjì ni ìwọ ó ṣe fún igun àgọ́ náà ní ìhà ẹ̀yìn. 29Ní igun méjèèjì yìí, pákó méjì ni ó wà níbẹ̀ láti ìdí dé orí rẹ̀ wọ́n sì kó wọ́n sí òrùka kan; méjèèjì rí bákan náà. 30Wọ́n ó sì jẹ́ pákó mẹ́jọ, àti ihò ìtẹ̀bọ̀ fàdákà mẹ́rìnlélógún, méjì wà ní ìsàlẹ̀ ọ̀kọ̀ọ̀kan.

31Ó sì ṣe ọ̀pá igi kasia márùn-ún fún pákó ìhà kan àgọ́ náà, 32márùn-ún fún àwọn tí ó wà ní ìhà kejì, márùn-ún fún pákó tí ó wà ní ìhà ìwọ̀-oòrùn ní ìkangun àgọ́ náà. 33Wọ́n sì ṣe ọ̀pá àárín tí yóò fi jáde láti ìkangun dé ìkangun ní àárín àwọn pákó náà. 34Ó sì bo àwọn pákó pẹ̀lú wúrà, wọ́n sì ṣe àwọn òrùka wúrà láti gbá ọ̀pá náà mú. Wọ́n sì tún bo ọ̀pá náà pẹ̀lú wúrà.

3536.35-38: Ek 26.31-37.Ó ṣe aṣọ títa aláró, àti elése àlùkò, àti òdòdó, àti ọ̀gbọ̀ olókùn wẹ́wẹ́ tí í ṣe ọlọ́nà, tí òun ti àwọn kérúbù ni kí á ṣe é. 36Wọ́n sì ṣe òpó igi ṣittimu mẹ́rin fún un wọ́n sì bò wọ́n pẹ̀lú wúrà. Wọ́n sì ṣe àwọn ìkọ́ wúrà fún wọn, wọ́n sì dá ihò ìtẹ̀bọ̀ fàdákà mẹ́rin mẹ́rin fún wọn. 37Fún ẹnu-ọ̀nà àgọ́ náà wọ́n ṣe aṣọ títa ti aṣọ aláró, ti elése àlùkò, ti òdódó àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára tí a fi iṣẹ́ abẹ́rẹ́ ṣe; 38Ó sì ṣe òpó márùn-ún pẹ̀lú ìkọ́ wọn. Ó bo orí àwọn òpó náà àti ìgbànú wọn pẹ̀lú wúrà, ó sì fi idẹ ṣe ihò ìtẹ̀bọ̀ wọn márààrùn-ún.