2. Mosebog 18 – BPH & YCB

Bibelen på hverdagsdansk

2. Mosebog 18:1-27

Jetro besøger Moses

1Det varede ikke længe, før Jetro, Moses’ svigerfar, der var præst i Midjan, hørte om de fantastiske mirakler, Gud havde gjort, da han førte sit folk, israelitterne, ud af Egypten.

2Moses havde på et tidligere tidspunkt sendt sin kone Zippora og sine to sønner tilbage til Jetro. 3Moses’ ældste søn fik navnet Gershom,18,3 Det betyder: „udlænding”. for han sagde: „Jeg har levet som fremmed i udlandet.” 4Hans anden søn fik navnet Eliezer,18,4 Det betyder: „Gud er min hjælper”. for han sagde: „Mine forfædres Gud er blevet min hjælper ved at redde mig ud af Faraos kløer.” 5Jetro var nu på vej sammen med Zippora og de to sønner til Moses i ørkenen, hvor han havde slået lejr ved Guds bjerg.18,5 Det er Sinaibjerget, også kaldet Horebs bjerg.

6Han sendte en besked i forvejen til Moses: „Jeg, din svigerfar Jetro, er på vej med din kone og dine to sønner.” 7Moses gik straks sin svigerfar i møde, bøjede sig ærbødigt og kyssede ham på kinden til velkomst. Efter at have spurgt til hinandens helbred gik de ind i Moses’ telt for at tale sammen. 8Moses fortalte sin svigerfar om alle de undere, Herren havde gjort for at redde israelitterne fra Farao og egypterne. Han fortalte også om de problemer, der havde været undervejs, og om, hvordan Herren havde hjulpet folket igennem det alt sammen. 9Jetro var begejstret over at høre, hvad Herren havde gjort for Israels folk, og hvordan han havde ført dem ud af Egypten.

10„Lovet være Jahve,” sagde Jetro, „for han har reddet jer fra egypterne og Farao—ja, han har virkelig befriet jer fra slaveriet i Egypten. 11Nu ser jeg, at Jahve er større end nogen anden gud, for han har befriet sit folk fra de stolte og brutale egyptere.”

12Så ofrede Jetro brændofre og andre ofre til Gud, og Aron og Israels øvrige ledere kom for at spise offermåltid sammen med ham.

13Næste dag satte Moses sig som sædvanlig for at høre på folks klager og løse deres indbyrdes konflikter. De stod i kø omkring ham fra morgen til aften. 14Da hans svigerfar så, hvor tidkrævende et arbejde det var, sagde han: „Sikke meget arbejde du har med folket. Hvorfor er du alene om at klare den store opgave? Folk står jo i kø hele dagen for at få hjælp.”

15„Folket kommer til mig i håb om at få Guds svar på deres problemer,” forklarede Moses, 16„og når de har en retssag, er jeg deres dommer. Det er jo min opgave at undervise dem om Guds forordninger og instruktioner.”

17„Det er ikke en god måde at gøre det på,” svarede Jetro. 18„Både du selv og folket bliver jo ganske udmattede. Moses, den opgave er for tung en byrde, hvis du forsøger at gøre alting selv. 19Lyt til mit råd—så vil Gud være med dig. Du skal fortsat selv træde frem for Gud på folkets vegne og spørge ham til råds i de vanskelige sager. 20Og du skal også undervise folket om hans forordninger og instruktioner og lære dem principperne for gudsfrygt, og hvordan de bør leve. 21Men du bliver nødt til at finde nogle kvalificerede, ærlige og gudfrygtige mænd, der ikke vil tage imod bestikkelse.

Dem skal du indsætte som dommere og rådgivere, nogle med ansvar for 1000 mennesker, nogle med ansvar for 100 mennesker, og andre med ansvar for 50 eller ti personer. 22Overlad så ansvaret for lov og orden til dem. Hvis en sag er kompliceret eller særlig betydningsfuld, kan de henvende sig til dig. Men alle mindre sager kan de selv tage sig af. Det vil betyde en stor aflastning for dig, hvis du på den måde uddelegerer nogle af dine ansvarsfulde opgaver til andre. 23Hvis du følger mit råd, og hvis det er i overensstemmelse med Guds vilje, vil du undgå stress, og folket kan hurtigere få deres sager behandlet og derfor gå tilfredse hjem.”

24Moses fulgte sin svigerfars råd. 25Han udvalgte kvalificerede mænd fra alle de 12 stammer og udnævnte dem til dommere og ledere for henholdsvis 1000, 100, 50 og 10 personer. 26Disse mænd stod altid til rådighed, så retfærdigheden kunne ske fyldest. Alle mindre sager tog de sig af, og kun de mere komplicerede blev overladt til Moses.

27Kort efter tog Moses afsked med sin svigerfar, som vendte tilbage til sit land.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Eksodu 18:1-27

Jetro bẹ Mose wò

1Jetro, àlùfáà Midiani, àna Mose, gbọ́ gbogbo ohun tí Ọlọ́run ti ṣe fún Mose àti fún Israẹli àwọn ènìyàn rẹ̀, àti bí Olúwa ti mú àwọn ènìyàn Israẹli jáde láti Ejibiti wá.

2Nígbà náà ni Jetro mu aya Mose tí í ṣe Sippora padà lọ sọ́dọ̀ rẹ (Nítorí ó ti dá a padà sí ọ̀dọ̀ baba rẹ̀ tẹ́lẹ̀). 318.3,4: Ap 7.29.Òun àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ méjèèjì. Orúkọ Àkọ́bí ń jẹ́ Gerṣomu (àjèjì); nítorí Mose wí pé, “Èmi ń ṣe àlejò ni ilẹ̀ àjèjì.” 4Èkejì ń jẹ́ Elieseri (alátìlẹ́yìn); ó wí pé, “Ọlọ́run baba mi ni alátìlẹ́yìn mi, ó sì gbà mí là kúrò lọ́wọ́ idà Farao.”

5Jetro, àna Mose, òun àti aya àti àwọn ọmọ Mose tọ̀ ọ́ wá nínú aginjù tí ó tẹ̀dó sí, nítòsí òkè Ọlọ́run. 6Jetro sì ti ránṣẹ́ sí Mose pé, “Èmi Jetro, àna rẹ, ni mo ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, èmi àti aya àti àwọn ọmọkùnrin rẹ méjèèjì.”

7Mose sì jáde lọ pàdé àna rẹ̀, ó tẹríba fún un, ó sì fi ẹnu kò ó ni ẹnu. Wọ́n sì béèrè àlàáfíà ara wọn, wọ́n sì wọ inú àgọ́ lọ. 8Mose sọ fún àna rẹ̀ nípa ohun gbogbo ti Olúwa tí ṣe sí Farao àti àwọn ará Ejibiti nítorí Israẹli. Ó sọ nípa gbogbo ìṣòro tí wọn bá pàdé ní ọ̀nà wọn àti bí Olúwa ti gbà wọ́n là.

9Inú Jetro dùn láti gbọ́ gbogbo ohun rere ti Olúwa ṣe fún Israẹli, ẹni tí ó mú wọ́n jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti. 10Jetro sì wí pé, “Ìyìn ni fún Olúwa, ẹni tí ó gba yín là kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Ejibiti àti lọ́wọ́ Farao, ẹni tí ó sì gba àwọn ènìyàn là kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Ejibiti. 11Mo mọ nísinsin yìí pé Olúwa tóbi ju gbogbo àwọn òrìṣà lọ; nítorí ti ó gba àwọn ènìyàn rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìgbéraga àti ìkà àwọn ará Ejibiti.” 12Jetro, àna Mose, mú ẹbọ sísun àti ẹbọ wá fún Ọlọ́run. Aaroni àti gbogbo àgbàgbà Israẹli sì wá láti bá àna Mose jẹun ní iwájú Ọlọ́run.

13Ní ọjọ́ kejì, Mose jókòó láti máa ṣe ìdájọ́ fún àwọn ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀; àwọn ènìyàn sì dúró ti Mose fún ìdájọ́ wọn láti òwúrọ̀ títí di ìrọ̀lẹ́. 14Nígbà tí àna Mose rí bí àkókò ti èyí ń gba ti pọ̀ tó àti ti àwọn ènìyàn ti ń dúró pẹ́ tó, ó wí pé, “Kí ni èyí tí ìwọ ń ṣe sí àwọn ènìyàn? Èéṣe ti ìwọ nìkan jókòó gẹ́gẹ́ bí adájọ́, nígbà tí àwọn ènìyàn wọ̀nyí dúró yí ọ ká láti òwúrọ̀ di ìrọ̀lẹ́?”

15Mose dá a lóhùn pé, “Nítorí àwọn ènìyàn ń tọ̀ mí wá láti mọ́ ìfẹ́ Ọlọ́run. 16Nígbà tí wọ́n bá ní ẹjọ́, wọn a mú un tọ̀ mí wá, èmi a sì ṣe ìdájọ́ láàrín ẹnìkínní àti ẹnìkejì, èmi a sì máa mú wọn mọ òfin àti ìlànà Ọlọ́run.”

17Àna Mose dá a lóhùn pé, “Ohun tí o ń ṣe yìí kò dára. 18Ìwọ àti àwọn ènìyàn ti ń tọ̀ ọ́ wá yìí yóò dá ara yín ní agara; iṣẹ́ yìí pọ̀jù fún ọ, ìwọ nìkan kò lè dá a ṣe 19Nísinsin yìí, fetísílẹ̀ sí mi, èmi yóò sì gbà ọ́ ni ìmọ̀ràn, Ọlọ́run yóò sì wà pẹ̀lú rẹ. Ìwọ gbọdọ̀ jẹ́ aṣojú àwọn ènìyàn wọ̀nyí níwájú Ọlọ́run, ìwọ yóò sì mú èdè-àìyedè wá sí iwájú rẹ̀. 20Kọ́ wọn ní òfin àti ìlànà Ọlọ́run, fi ọ̀nà igbe ayé ìwà-bí-Ọlọ́run hàn wọ́n àti iṣẹ́ tí wọn yóò máa ṣe. 21Ṣa àwọn tí ó kún ojú òṣùwọ̀n nínú gbogbo àwọn ènìyàn: àwọn tó bẹ̀rù Ọlọ́run, ti wọ́n jẹ́ olóòtítọ́, tí wọ́n kórìíra ìrẹ́jẹ: yàn wọ́n ṣe olórí: lórí ẹgbẹ̀rún ẹgbẹ̀rún, ọgọ́rùn-ún-ọgọ́rùn-ún, àádọ́ta-dọ́ta àti mẹ́wàá mẹ́wàá. 22Jẹ́ kí wọn ó máa ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn ni gbogbo ìgbà, ṣùgbọ́n jẹ́ kí wọn mú ẹjọ́ tí ó bá nira fún wọn láti dá tọ̀ ọ́ wá; kí wọn kí ó máa dá ẹjọ́ kéékèèkéé. Èyí ni yóò mú iṣẹ́ rẹ rọrùn, wọn yóò sì máa ràn ọ́ lọ́wọ́ lórí ìdájọ́ ṣíṣe. 23Bí ìwọ bá ṣe èyí, bí Ọlọ́run bá sì fi àṣẹ sí i fún ọ bẹ́ẹ̀, àárẹ̀ kò sì ní tètè mu ọ, àwọn ènìyàn wọ̀nyí yóò sì padà lọ ilé wọn ni àlàáfíà.”

24Mose fetísílẹ̀ sí àna rẹ̀, ó sì ṣe ohun gbogbo tí ó wí fún un. 25Mose sì yan àwọn ènìyàn tí wọ́n kún ojú òṣùwọ̀n nínú gbogbo Israẹli; ó sì fi wọ́n jẹ olórí àwọn ènìyàn, olórí ẹgbẹẹ̀rún, olórí ọ̀rọ̀ọ̀rún, olórí àràádọ́ta, àti olórí mẹ́wàá mẹ́wàá. 26Wọ́n sì ń ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn ní ìgbà gbogbo. Wọ́n sì ń mú ẹjọ́ tó le tọ Mose wá; ṣùgbọ́n wọ́n ń dá ẹjọ́ tí kò le fúnrawọn.

27Mose sì jẹ́ kí àna rẹ̀ lọ ní ọ̀nà rẹ̀, Jetro sì padà sí ilẹ̀ ẹ rẹ̀.