2. Krønikebog 20 – BPH & YCB

Bibelen på hverdagsdansk

2. Krønikebog 20:1-37

Herren gav Juda sejr over Moab og Ammon

1Nogen tid senere gjorde tre folkeslag sig klar til at føre krig mod Juda. Det var moabitterne og ammonitterne, hjulpet af nogle af meunitterne.20,1 Meunitterne var et nomadefolk, der boede i Seirs bjerge i landet Edom. Jf. 26,7 og 1.Krøn. 4,41. 2Kong Joshafat fik at vide, at en mægtig hær havde samlet sig i Edom på den anden side af Det Døde Hav, og at den allerede var nået frem til Hatzetzon-Tamar. (Som nu kaldes En-Gedi.) 3Joshafat blev rystet over denne nyhed og besluttede at søge hjælp hos Herren. Derfor udråbte han en faste i hele Juda. 4Fra hele landet kom folk til Jerusalem for sammen med kongen at bede Herren om hjælp.

5Joshafat stod frem i den nye forgård i Herrens hus foran hele forsamlingen og bad denne bøn: 6„Herre, vores fædres Gud, du som regerer i Himlen og over alle jordens riger. Du har den højeste magt, og ingen kan besejre dig. 7Vi har hørt, hvordan du drev de andre folkeslag ud af dette land, dengang dit folk kom hertil. Vi ved, at du gav dette land til din ven Abrahams efterkommere for evigt. 8Her slog dit folk sig ned og byggede dette tempel for dig. 9Dengang sagde de: ‚Hvis der kommer en ulykke over os, hvad enten det er fjendehære, pest eller hungersnød, så vil vi komme til dette tempel, hvor du bor, og bede dig om hjælp, så du kan gribe ind og redde os.’

10Se nu! Vi bliver angrebet af en stor hær fra Ammon, Moab og Seirs bjerge. Det er de folkeslag, du ikke tillod vores forfædre at udrydde på vej op fra Egypten. Derfor gik de i en bue uden om dem og lod dem være. 11Se nu, hvad de gør til gengæld. De er kommet for at jage os ud af det land, du har givet os i eje. 12Åh, Gud, du må standse dem. Vi står magtesløse over for så mægtig en hær og ved ikke, hvad vi skal gøre, men vi stoler på din hjælp.”

13Alle Judas mænd stod foran Herrens tempel med deres koner og børn. 14Da kom Herrens Ånd over Jahaziel,20,14 Teksten tilføjer: „søn af Benaja, søn af Jeiel, søn af Mattanja.” en af levitterne fra Asafs slægt.

15„Lyt til mig, kong Joshafat og alle Judas og Jerusalems indbyggere,” råbte han. „Herren siger: Vær ikke bange! Lad jer ikke skræmme af denne mægtige hær, for det er ikke jeres kamp, men Guds! 16I morgen skal I rykke frem mod dem. De kommer ad vejen op til Zitz, og I vil kunne se dem for enden af dalen, der fører ud til Jeruels ørken. 17I skal ikke kæmpe mod dem, men blot tage opstilling og se på, at Herren giver sejr. Judas og Jerusalems indbyggere, vær ikke bange og tab ikke modet! I morgen skal I gå dem i møde—og Herren vil være med jer.”

18Ved disse ord faldt kong Joshafat på knæ med ansigtet mod jorden i tilbedelse, og Judas og Jerusalems indbyggere gjorde det samme. 19Derefter rejste levitterne af Kehats og Koras slægter sig og brød ud i en højlydt lovsang til Herren, Israels Gud.

20Tidligt næste morgen gjorde de klar til at drage ud i ørkenen i retning af Tekoa.20,20 Tekoa ligger knap 20 km syd for Jerusalem på vejen mod En-Gedi. Joshafat opmuntrede dem med følgende ord: „Lyt til mig, Judas og Jerusalems indbyggere! Stol på Herren jeres Gud, så skal det lykkes for jer! Stol på hans profeter, så vil det gå jer vel!”

21Efter at have rådført sig med folkets ledere besluttede Joshafat at lade sangerne gå foran soldaterne. De skulle lovprise Herren for hans hellighed og herlighed med ordene: „Lovet være Herren! Hans trofasthed varer til evig tid!”

22Under deres sang og lovprisning skabte Herren panik blandt fjendernes hære, så de begyndte at hugge hinanden ned. 23Først dræbte ammonitterne og moabitterne i fællesskab dem fra Seirs bjerge, hvorpå de begyndte at slå hinanden ihjel. 24Da judæerne nåede frem til udkigsposten oven for ørkenen, lå der døde kroppe så langt øjet rakte—ikke en eneste af fjenderne var undsluppet! 25Kong Joshafat og hans soldater gik ud for at samle byttet ind, og de fandt så meget i form af forsyninger, udstyr og kostbarheder, at det tog dem tre dage at samle det hele sammen. 26På den fjerde dag samledes de i dalen og lovpriste Herren for sejren. Derfor kaldes dalen den dag i dag for Berakadalen.20,26 Ordet betyder: „lovprisning” eller „velsignelse”.

27Derefter vendte judæerne med kong Joshafat i spidsen tilbage til Jerusalem—begejstrede over, at Herren havde givet dem sejr over deres fjender. 28Triumftoget gik gennem byen og nåede frem til templet akkompagneret af harper, lyrer og trompeter. 29Og da de omkringboende folk hørte, at Herren havde besejret Israels fjender, blev de grebet af frygt for Gud. 30Derefter var der ro i landet, for Gud gav Joshafat fred til alle sider.

Et sammendrag af Joshafats regeringstid

1.Kong. 22,41-50

31Joshafat var konge i Judas land. Han var 35 år, da han kom til magten, og han regerede i Jerusalem i 25 år. Hans mor hed Azuba og var datter af Shilhi. 32Han fulgte sin fars eksempel og adlød Herren, 33men det lykkedes ham ikke at udrydde offerstederne på højene rundt omkring i landet, ej heller at få folket til helhjertet at følge Herren, deres forfædres Gud.

34Hvad der ellers skete under hans regeringstid er beskrevet af profeten Jehu, søn af Hanani, og er optegnet i Israels kongers krønikebog.

35På et tidspunkt indgik kong Joshafat forbund med kong Ahazja af Israel, der var en ond konge. 36I fællesskab byggede de i Etzjon-Geber nogle store handelsskibe, der skulle sejle til Tarshish.20,36 Se noten til 1.Kong. 10,22. 37Men Eliezer fra Maresha, søn af Dodavahu, profeterede mod Joshafat: „Fordi du har allieret dig med kong Ahazja, vil Herren ødelægge det, du har bygget op!” Derfor forliste skibene og nåede aldrig frem til Tarshish.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Kronika 20:1-37

Jehoṣafati pa Moabu àti Amoni run

1Lẹ́yìn èyí, àwọn ọmọ Moabu àti àwọn ọmọ Ammoni àti díẹ̀ nínú àwọn ọmọ Mehuni wá láti gbé ogun ti Jehoṣafati.

2Àwọn díẹ̀ nínú àwọn ọkùnrin wá láti sọ fún Jehoṣafati, “Àwọn ọ̀pọ̀ ọ̀wọ́ ogun ń bọ̀ wá bá ọ láti apá kejì Òkun láti Siria. Ó ti wà ní Hasason Tamari náà” (èyí tí í ṣe, En-Gedi). 3Nípa ìró ìdágìrì, Jehoṣafati pinnu láti wádìí lọ́wọ́ Olúwa, ó sì kéde àwẹ̀ kíákíá fún gbogbo Juda. 4Àwọn ènìyàn Juda sì kó ara wọn jọ pọ̀ láti wá ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ Olúwa; pẹ̀lúpẹ̀lú, wọ́n wá láti gbogbo ìlú ní Juda láti wá a.

5Nígbà náà Jehoṣafati dìde dúró níwájú àpéjọ Juda àti Jerusalẹmu ní ilé Olúwa níwájú àgbàlá tuntun. 6O sì wí pé:

Olúwa, Ọlọ́run àwọn baba wa, ìwọ kì ha ṣe Ọlọ́run tí ń bẹ ní ọ̀run? Ìwọ ń ṣe alákòóso lórí gbogbo ìjọba àwọn orílẹ̀-èdè. Agbára àti ipá ń bẹ ní ọwọ́ rẹ, kò sì sí ẹnìkan tí ó lè kò ọ́ lójú. 720.7: Jk 2.23.Ìwọ ha kọ́ Ọlọ́run wa, tí o ti lé àwọn olùgbé ilẹ̀ yìí jáde níwájú àwọn ènìyàn Israẹli, tí o sì fi fún irú-ọmọ Abrahamu ọ̀rẹ́ rẹ láéláé? 8Wọ́n ti ń gbé nínú rẹ̀ wọ́n sì ti kọ́ sínú rẹ ibi mímọ́ fún orúkọ rẹ wí pé, 9‘Tí ibi bá wá sí orí wa, bóyá idà ìjìyà tàbí àjàkálẹ̀-ààrùn àwọn yóò dúró níwájú rẹ níwájú ilé yìí tí ń jẹ́ orúkọ rẹ, àwa yóò sì sọkún jáde, ìwọ yóò sì gbọ́ wa. Ìwọ yóò sì gbà wá là?’

10“Ṣùgbọ́n nísinsin yìí àwọn ọkùnrin nìyí láti Ammoni, Moabu àti òkè Seiri, agbègbè ibi ti ìwọ kò ti gba àwọn ọmọ Israẹli láyè láti gbóguntì nígbà tí wọn wá láti Ejibiti; Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n yípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ wọn, wọn kò sì pa wọ́n run. 11Sì kíyèsi i, bí wọ́n ti san án padà fún wa; láti wá lé wa jáde kúrò nínú ìní rẹ, tí ìwọ ti fi fún wa láti ní. 12Ọlọ́run wa, ṣé ìwọ kò ní ṣe ìdájọ́ fún wọn? Nítorí àwa kò ní agbára láti dojúkọ àwọn ọ̀pọ̀ ogun ńlá yìí tí ń bọ̀ wá kó wa. Àwa kò mọ̀ ohun tó yẹ ká ṣe, ṣùgbọ́n ojú wa wà ní ọ̀dọ̀ rẹ.”

13Gbogbo àwọn ọkùnrin Juda, pẹ̀lú àwọn aya wọn àti ọmọ wọn àti àwọn kéékèèkéé, dúró níbẹ̀ níwájú Olúwa.

14Nígbà náà, ẹ̀mí Olúwa sì bà lé Jahasieli ọmọ Sekariah, ọmọ Benaiah, ọmọ Jeieli, ọmọ Mattaniah ọmọ Lefi àti ọmọ Asafu, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe dìde dúró láàrín àpéjọ ènìyàn.

15Ó sì wí pé, “Ẹ tẹ́tí sílẹ̀, ọba Jehoṣafati àti gbogbo àwọn tí ń gbé ní Juda àti Jerusalẹmu! Èyí ní ohun tí Olúwa sọ wí pé kí a ṣe: ‘Ẹ má ṣe bẹ̀rù tàbí fòyà nítorí ọ̀pọ̀ ogun ńlá yìí. Nítorí ogun náà kì í ṣe tiyín, ṣùgbọ́n ti Ọlọ́run ni. 16Ní ọ̀la, ẹ sọ̀kalẹ̀ tọ̀ wọ́n lọ, wọn yóò gòkè pẹ̀lú, ẹ̀yin yóò sì rí wọn ní ìpẹ̀kun odò náà, níwájú aginjù Jerueli. 17Ẹ̀yin kò ní láti bá ogun yìí jà. Ẹ dúró ní ààyè yín; Ẹ dúró jẹ́ẹ́ kí ẹ sì rí ìgbàlà Olúwa tí yóò fi fún yín, ìwọ Juda àti Jerusalẹmu. Ẹ má ṣe bẹ̀rù; Ẹ má sì ṣe fòyà. Ẹ jáde lọ láti lọ dojúkọ wọ́n ní ọ̀la, Olúwa yóò sì wà pẹ̀lú yín.’ ”

18Jehoṣafati tẹ orí rẹ̀ ba sílẹ̀ pẹ̀lú ojú rẹ̀, àti gbogbo àwọn ènìyàn Juda àti Jerusalẹmu wólẹ̀ níwájú láti sin Olúwa. 19Nígbà náà díẹ̀ lára àwọn ọmọ Lefi àti àwọn ọmọ Kohati àti àwọn ọmọ Kora sì dìde dúró wọ́n sì sin Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, pẹ̀lú ohùn ariwo ńlá.

20Ní òwúrọ̀ kùtùkùtù wọ́n jáde lọ sí aginjù Tekoa. Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ń jáde lọ, Jehoṣafati dìde dúró ó sì wí pé, “Ẹ gbọ́ mi, Juda àti ènìyàn Jerusalẹmu! Ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú Olúwa Ọlọ́run yín ẹ̀yin yóò sì borí, ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn wòlíì rẹ̀ ẹ̀yìn yóò sì ṣe rere.” 21Lẹ́yìn ìgbà tí ó bá àwọn ènìyàn náà gbèrò tán, Jehoṣafati yàn wọ́n láti kọrin sí Olúwa àti láti fi ìyìn fún ẹwà ìwà mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ó tì ń jáde lọ sí iwájú ogun ńlá náà, wí pé:

“Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa,

nítorí àánú rẹ̀ dúró títí láéláé.”

22Bí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí kọrin àti ìyìn, Olúwa rán ogun ẹ̀yìn sí àwọn ọkùnrin Ammoni àti Moabu àti òkè Seiri tí ó ń gbógun ti Juda, wọ́n sì kọlù wọ́n. 23Àwọn ọkùnrin Ammoni àti Moabu dìde dúró sí àwọn ọkùnrin tí ń gbé òkè Seiri láti pa wọ́n run túútúú. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n sì ti pa àwọn ọkùnrin láti òkè Seiri, wọ́n sì ran ra wọn lọ́wọ́ láti pa ara wọn run.

24Nígbà tí àwọn ènìyàn Juda jáde sí ìhà ilé ìṣọ́ ní aginjù, wọn ń wo àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn, òkú nìkan ni wọ́n rí tí ó ṣubú sí ilẹ̀, kò sì sí ẹnìkan tí ó rí ààyè sá. 25Bẹ́ẹ̀ ni Jehoṣafati àti àwọn ènìyàn rẹ̀ lọ láti kó ìkógun wọn, wọ́n sì rí lára wọn ọ̀pọ̀ iyebíye ọrọ̀ púpọ̀, ó sì ju èyí tí wọ́n lè kó lọ. Ọ̀pọ̀ ìkógun sì wà níbẹ̀, èyí tí ó gbà wọ́n ní ọjọ́ mẹ́ta láti gbà pọ̀. 26Ní ọjọ́ kẹrin, wọn kó ara jọ pọ̀ ní Àfonífojì ìbùkún, níbi tí wọ́n ti ń fi ìbùkún fún Olúwa. Ìdí nìyí tí wọ́n fi ń pe ibẹ̀ ní Àfonífojì ìbùkún títí di òní.

27Nígbà náà wọ́n darí pẹ̀lú Jehoṣafati, gbogbo àwọn ènìyàn Juda àti Jerusalẹmu padà pẹ̀lú ayọ̀ sí Jerusalẹmu, nítorí Olúwa ti fún wọn ní ìdí láti yọ̀ lórí àwọn ọ̀tá wọn. 28Wọ́n sì wọ Jerusalẹmu, wọ́n sì lọ sí ilé Olúwa pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn àti dùùrù àti ìpè.

29Ìbẹ̀rù Ọlọ́run wá si orí gbogbo ìjọba ilẹ̀ náà nígbà tí wọ́n gbọ́ bí Olúwa ti bá àwọn ọ̀tá Israẹli jà. 30Bẹ́ẹ̀ ni ìjọba Jehoṣafati sì wà ní àlàáfíà, nítorí Ọlọ́run rẹ̀ ti fún un ni ìsinmi ní gbogbo àyíká.

Òpin ìjọba Jehoṣafati

3120.31-33: 1Ọb 22.41-43.Báyìí ni Jehoṣafati jẹ ọba lórí Juda. Ó sì jẹ́ ẹni ọdún márùn-dínlógójì. Nígbà tí ó di ọba Juda, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Asuba ọmọbìnrin Silihi. 32Ó sì rin ọ̀nà baba rẹ̀ Asa kò sì yà kúrò nínú rẹ̀, ó sì ṣe èyí tí ó tọ́ ní ojú Olúwa. 33Ní ibi gíga, pẹ̀lúpẹ̀lú, kò mu wọn kúrò, gbogbo àwọn ènìyàn náà kò sì fi ọkàn wọn fún Ọlọ́run àwọn baba wọn.

34Ìyókù iṣẹ́ ìjọba Jehoṣafati, láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin, ni a kọ sí inú ìwé ìtàn ti Jehu ọmọ Hanani, tí a kọ sí inú ìwé àwọn ọba Israẹli.

3520.35-37: 1Ọb 22.48,49.Nígbà tí ó yá, Jehoṣafati ọba Juda da ara rẹ̀ pọ̀ pẹ̀lú Ahasiah, ọba Israẹli, ẹni tí ó jẹ̀bi ìwà búburú. 36Ó sì gbà pẹ̀lú rẹ̀ láti kan ọkọ̀ láti lọ sí Tarṣiṣi, lẹ́yìn èyí wọ́n kan ọkọ̀ ní Esioni-Geberi. 37Elieseri ọmọ Dodafahu ti Meraṣa sọtẹ́lẹ̀ sí Jehoṣafati, wí pe, “Nítorí tí ìwọ ti da ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ Ahasiah, Olúwa yóò pa ohun ti ìwọ ti ṣe run.” Àwọn ọkọ̀ náà sì fọ́, wọn kò sì le lọ sí ibi ìtajà.