2. Krønikebog 18 – BPH & YCB

Bibelen på hverdagsdansk

2. Krønikebog 18:1-34

Profeten Mika advarer kong Ahab

1.Kong. 22,1-28

1Som sagt var Joshafat både rig og højt agtet. Han besluttede nu at indgå en alliance med kong Ahab af Israel ved at lade sin søn gifte sig med Ahabs datter.

2Nogle år senere rejste han til Samaria for at besøge Ahab. Til ære for Joshafat og hans ledsagere arrangerede Israels konge en fest og slagtede i den anledning et stort antal småkvæg og hornkvæg. Under festen søgte han at overtale Joshafat til at hjælpe sig med at erobre byen Ramot-Gilead. 3„Vil du hjælpe mig med at befri Ramot-Gilead?” spurgte han Joshafat. „Selvfølgelig!” svarede Joshafat. „Vi er jo forbundsfæller, du og jeg. Mine folk vil kæmpe sammen med dine.” 4Men så tilføjede han: „Vi bør dog først spørge Herren til råds.”

5Derpå tilkaldte kong Ahab sine 400 profeter og spurgte dem: „Skal jeg gå til angreb på Ramot-Gilead eller ej?” „Du skal gå til angreb,” svarede de. „Gud vil give dig sejr!”

6Men kong Joshafat var ikke tilfreds. „Er der ikke en af Herrens profeter, vi kan spørge til råds?” spurgte han. 7„Jo, en enkelt,” svarede Ahab, „men jeg bryder mig ikke om ham, for han profeterer altid ulykke for mig, aldrig noget godt. Manden hedder Mika, søn af Jimla.” „Sådan bør du ikke tale!” indvendte Joshafat. 8Kong Ahab gav derefter ordre til, at Mika straks skulle hentes.

9I mellemtiden fortsatte Ahabs profeter med at profetere for de to konger, der sad klædt i deres kongekåber på hver sin trone på tærskepladsen nær ved byporten. 10En af profeterne ved navn Zidkija, søn af Kena’ana, lavede nogle horn af jern og erklærede: „Herren siger: Du skal stange den aramæiske hær sønder og sammen med disse horn og udrydde den totalt!” 11De andre profeter sagde det samme. „Gå kun til angreb på Ramot-Gilead. Herren vil give dig sejr!”

12Kongens tjener, som var blevet sendt for at hente Mika, fortalte ham, hvad de andre profeter havde sagt, og opfordrede ham til at sige det samme. 13Men Mika svarede: „Så sandt Herren lever: Jeg kan ikke sige andet, end det min Gud fortæller mig!”

14Da Mika ankom, spurgte kong Ahab: „Mika, skal vi angribe Ramot-Gilead eller ej?” „Ja, tag endelig af sted!” svarede Mika. „Lykken er med dig. Herren vil give dig sejr!” 15„Hør nu her,” sagde Ahab. „Hvor mange gange skal jeg få dig til at sværge på, at du kun siger sandheden, når du taler i Herrens navn?”

16Så sagde Mika: „Jeg så Israels folk spredt ud over bjergene som får, der ingen hyrde har! Og Herren sagde: Kongen er død! Send folket hjem!” 17Kongen vendte sig beklagende til Joshafat. „Sagde jeg det ikke nok! Aldrig profeterer han noget godt. Evigt og altid kun dårlige budskaber.”

18„Så hør da Herrens ord!” afbrød Mika. „Jeg så Herren sidde på sin trone, og en hær af engle var samlet omkring ham. 19Så sagde Herren: ‚Hvem vil lokke Ahab i fælden, så han dør i Ramot-Gilead?’ Og efter at adskillige planer var blevet foreslået, 20trådte en af ånderne frem og sagde: ‚Det vil jeg gøre!’ ‚Men hvordan?’ spurgte Herren. 21Ånden svarede: ‚Jeg vil være en løgneånd i alle hans profeters mund!’ ‚Du kan klare opgaven,’ sagde Herren. ‚Gå bare i gang!’ ”

22Mika fortsatte: „Kong Ahab, kan du ikke gennemskue dine profeter? Herren har jo fyldt dem alle med en løgnens ånd, og i virkeligheden har han planer om at få ram på dig.”

23Ved de ord gik profeten Zidkija hen til Mika og gav ham en lussing. „Vil du måske påstå, at Herrens Ånd kun taler gennem dig og ikke gennem mig?” snerrede han. 24Mika svarede: „Svaret på det spørgsmål får du, den dag du rædselsslagen prøver at gemme dig i et baglokale i et hus.”

25Efter det ordskifte gav kong Ahab ordre til at arrestere Mika. „Før ham til Amon, byens borgmester, og til min søn Joash,” sagde han. 26„Giv dem besked om at kaste ham i fængsel og sætte ham på vand og brød, til jeg kommer uskadt tilbage fra slaget.” 27„Hvis du kommer tilbage, har Herren ikke talt gennem mig!” sagde Mika. „Har I hørt det alle sammen?”

Kong Ahabs død

1.Kong. 22,29-35

28Derefter førte kong Ahab af Israel og kong Joshafat af Juda deres hære mod Ramot-Gilead, 29men Ahab sagde til Joshafat: „Før jeg kaster mig ud i kampen, vil jeg forklæde mig som en menig soldat. Men behold du bare din kongelige rustning på.” Så forklædte kong Ahab sig og slaget begyndte.

30Den aramæiske konge havde imidlertid givet sine vognstyrere ordre til at være på udkig efter kong Ahab og koncentrere sig om at fælde ham. 31-32Da de fik øje på kong Joshafat, tænkte de: „Dér er han!” og vendte om for at få fat i ham. Men Joshafat råbte til Herren om hjælp, og Herren hjalp ham. Gud sørgede for, at de lod ham være, for da de forstod, at han ikke var Israels konge, trak de sig tilbage. 33Men en af bueskytterne skød en tilfældig pil af sted, og pilen borede sig ind mellem remmene i kong Ahabs brynje.

„Lad os komme væk fra fronten!” stønnede Ahab til sin vognstyrer. „Jeg er alvorligt såret.”

34Kampen trak i langdrag og blev mere og mere intens. Kong Ahab holdt øje med kampen på afstand, men kunne dårligt holde sig oprejst i vognen. Ved solnedgang døde han.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Kronika 18:1-34

Mikaiah sọtẹ́lẹ̀ lórí Ahabu

118.1-34: 1Ọb 22.1-35.Nísinsin yìí Jehoṣafati sì ní ọrọ̀ àti ọlá púpọ̀, ó sì dá àna pẹ̀lú Ahabu nípa fífẹ́ ọmọ rẹ̀. 2Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, ó sọ̀kalẹ̀ láti lọ bá Ahabu lálejò ní Samaria. Ahabu sì pa àgùntàn àti màlúù púpọ̀ fún àti àwọn ènìyàn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ ó sì rọ̀ ọ́ láti dojú ìjà kọ Ramoti Gileadi. 3Ahabu ọba Israẹli sì béèrè lọ́wọ́ ọba Jehoṣafati, ọba Juda pé, “Ṣé ìwọ yóò lọ pẹ̀lú mi sí Ramoti Gileadi?”

Jehoṣafati sì dá a lóhùn pé, “Èmi wà gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti ṣe wà, àti àwọn ènìyàn mi gẹ́gẹ́ bí ènìyàn rẹ àwa yóò pẹ̀lú rẹ nínú ogun naà”. 4Ṣùgbọ́n Jehoṣafati náà sì tún wí fún ọba Israẹli pé, “Kọ́kọ́ béèrè lọ́wọ́ Olúwa.”

5Bẹ́ẹ̀ ọba Israẹli kó àwọn wòlíì papọ̀, irínwó (4,000) ọkùnrin ó sì bi wọ́n pé, “Kí àwa kí lọ sí ogun Ramoti Gileadi tàbí kí èmi kí ó jọ̀wọ́ rẹ?”

“Lọ,” wọ́n dáhùn, “nítorí tí Ọlọ́run yóò fi lé ọba lọ́wọ́.”

6Ṣùgbọ́n Jehoṣafati béèrè pé, “Ṣé kò ha sí wòlíì Olúwa níbí ẹni tí àwa ìbá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀?”

7Ọba Israẹli dá Jehoṣafati lóhùn pé, “Ọkùnrin kan wà síbẹ̀ lọ́dọ̀ ẹni tí àwa ìbá tún béèrè lọ́wọ́ Olúwa, ṣùgbọ́n èmi kórìíra rẹ̀ nítorí kò jẹ́ sọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun rere kan nípa mi ṣùgbọ́n bí kò ṣe ohun búburú, ní gbogbo ìgbà òun náà ni Mikaiah ọmọ Imla.”

“Ọba kò gbọdọ̀ sọ bẹ́ẹ̀,” Jehoṣafati sì dá lóhùn.

8Bẹ́ẹ̀ ni ọba Israẹli pe ọ̀kan lára àwọn ìjòyè ó sì wí pé, “Ẹ mú Mikaiah ọmọ Imla kí ó yára wá.”

9Wọ́n wọ aṣọ Ìgúnwà wọn, ọba Israẹli àti Jehoṣafati ọba Juda wọ́n jókòó sórí ìtẹ́ wọ́n ní ìta ẹnu-bodè Samaria, pẹ̀lú gbogbo àwọn wòlíì tí ń sọtẹ́lẹ̀ níwájú wọn. 10Nísinsin yìí Sedekiah ọmọ Kenaana sì ti ṣe ìwo irin, ó sì wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa sọ: pẹ̀lú èyí ìwọ yóò kan àwọn ará Siria títí ìwọ ó fi pa wọ́n run.”

11Gbogbo àwọn wòlíì tí ó kù ni wọn ń sọtẹ́lẹ̀ ní àkókò kan náà, “Wọ́n sì wí pé, dojúkọ Ramoti Gileadi ìwọ yóò sì ṣẹ́gun,” wọ́n wí pé, “nítorí Olúwa yóò fi lé ọba lọ́wọ́.”

12Ìránṣẹ́ tí ó ti lọ pe Mikaiah sì wí fún un pé, “Ẹ wò ó, gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin kan àti òmíràn wòlíì fi ẹnu kan sọ rere fún ọba. Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ kí ó dàbí ọ̀kan nínú tiwọn, kí o sì sọ rere.”

13Ṣùgbọ́n Mikaiah wí pe, “Gẹ́gẹ́ bí ó ti dájú pé Olúwa ń bẹ láààyè, èmi yóò sọ ohun tí Ọlọ́run mi sọ.”

14Nígbà tí ó dé, ọba béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, “Mikaiah, ṣe kí àwa ki ó lọ sí ogun ti Ramoti Gileadi, tàbí kí àwa kí ó fàsẹ́yìn?”

“Ẹ dojúkọ wọ́n kí ẹ sì ṣẹ́gun.” Ó dáhùn, “nítorí a ó fi wọ́n lé yín lọ́wọ́.”

15Ọba sì wí fún un pé, “Ìgbà mélòó ni èmi ó fi ọ́ búra láti sọ ohun kan fún mi bí kò ṣe ọ̀rọ̀ òtítọ́ ní orúkọ Olúwa?”

1618.16: Nu 27.17; El 34.5; Mt 9.36; Mk 6.34.Mikaiah sì dáhùn pé, “Mo rí gbogbo Israẹli túká kiri lórí àwọn òkè bí àgùntàn tí kò ní olùṣọ́, Olúwa sì wí pé, ‘Àwọn wọ̀nyí kò ní olúwa. Jẹ́ kí olúkúlùkù padà sí ilé rẹ̀ ní àlàáfíà.’ ”

17Ọba Israẹli wí fún Jehoṣafati pé, “Ṣe èmi kò sọ fún ọ wí pé òun kò sọ àsọtẹ́lẹ̀ rere kankan nípa mi rí, ṣùgbọ́n búburú nìkan?”

18Mikaiah tẹ̀síwájú pé, “Nítorí náà, gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa: Mo rí Olúwa jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀ gbogbo ogun ọ̀run sì dúró lápá ọ̀tún àti lápá òsì. 19Olúwa sì wí pé, ‘Ta ni yóò tan Ahabu ọba Israẹli lọ sí Ramoti Gileadi kí ó sì lọ kú ikú rẹ̀ níbẹ̀?’

“Èkínní sì sọ tìhín, òmíràn sì sọ tọ̀hún. 20Ní ìparí, ni ẹ̀mí kan wá síwájú, ó dúró níwájú Olúwa ó sì wí pé, ‘Èmi yóò tàn án.’

“ ‘Nípa ọ̀nà wo?’ Olúwa béèrè.

21“ ‘Èmi yóò lọ láti lọ di ẹ̀mí èké ní ẹnu gbogbo àwọn wòlíì.’

“ ‘Ìwọ yóò sì borí nínú ìtànjẹ rẹ̀ báyìí,’ ni Olúwa wí. ‘Lọ kí ó sì ṣe bẹ́ẹ̀.’

22“Bẹ́ẹ̀ ni nísinsin yìí Olúwa ti fi ẹ̀mí èké sí ẹnu àwọn wòlíì rẹ. Olúwa sì ti sọ ibi sí ọ.”

23Nígbà náà Sedekiah ọmọ Kenaana lọ sókè ó sì gbá Mikaiah ní ojú. Ó sì béèrè pé, “Ní ọ̀nà wo ni ẹ̀mí Olúwa gbà kọjá lọ kúrò lọ́dọ̀ mi láti bá ọ sọ̀rọ̀?”

24Mikaiah sì dáhùn pé, “ìwọ yóò ṣe ìwádìí ní ọjọ́ tí ìwọ yóò sápamọ́ sínú ìyẹ̀wù.”

25Ọba Israẹli pa á láṣẹ pé, “Mú Mikaiah kí o sì ran padà sí Amoni olórí ìlú àti sí Joaṣi ọmọ ọba, 26Ó sì wí pé ‘Èyí ni ohun tí ọba sọ: ẹ fi ènìyàn yìí sínú túbú kí ẹ má sì ṣe fún un ní ohunkóhun ṣùgbọ́n àkàrà àti omi títí tí èmi yóò fi dé ní àlàáfíà.’ ”

27Mikaiah sì wí pe, “Tí ìwọ bá padà ní àlàáfíà, Olúwa kò sọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ mi.” Nígbà náà, ó sì fi kún un pé, “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn!”

A pa Ahabu ní Ramoti Gileadi

28Bẹ́ẹ̀ ni ọba Israẹli àti Jehoṣafati ọba Juda lọ sókè ní Ramoti Gileadi. 29Ọba Israẹli sọ fún Jehoṣafati pé, “Èmi yóò lọ sí ojú ìjà, ṣùgbọ́n ìwọ wọ aṣọ ìgúnwà rẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni ọba Israẹli pa aṣọ rẹ̀ dà, ó sì lọ sí ojú ìjà.

30Nísinsin yìí ọba Siria ti pàṣẹ fún àwọn olórí kẹ̀kẹ́ tí ó wà ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, “Ẹ má ṣe jà pẹ̀lú ẹnìkankan, èwe tàbí àgbà àyàfi ọba Israẹli.” 31Nígbà tí àwọn olórí kẹ̀kẹ́ rí Jehoṣafati, wọ́n rò wí pé, “Èyí ní ọba Israẹli.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì yípadà láti bá a jà. Ṣùgbọ́n Jehoṣafati kégbe sókè, Olúwa sì ràn án lọ́wọ́. Ọlọ́run sì lé wọn kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, 32Ó sì ṣe, nígbà tí olórí kẹ̀kẹ́ rí i wí pé kì í ṣe ọba Israẹli, wọ́n sì dáwọ́ lílé rẹ̀ dúró.

33Ṣùgbọ́n ẹnìkan fa ọrun rẹ̀ láì pète, ó sì bá ọba Israẹli láàrín ìpàdé ẹ̀wù irin, ọba sì sọ fún olùtọ́jú kẹ̀kẹ́ rẹ̀ pé, “Yí ọwọ́ rẹ padà, kí o sì wà mí jáde kúrò lójú ìjà. Nítorí èmi ti gbọgbẹ́.” 34Ní ọjọ́ pípẹ́, ìjà náà sì ń pọ̀ sí i, ọba Israẹli dúró nínú kẹ̀kẹ́ rẹ̀ kọjú sí àwọn ará Siria títí ó fi di àṣálẹ́. Lẹ́yìn náà ní àkókò ìwọ oòrùn, ó sì kú.