1. Samuelsbog 5 – BPH & YCB

Bibelen på hverdagsdansk

1. Samuelsbog 5:1-12

Arken hos filistrene

1Imidlertid bragte filistrene Guds Ark fra slagmarken ved Eben-Ezer til byen Ashdod 2og ind i deres afgudstempel, hvor den blev stillet ved siden af statuen af deres afgud, som hed Dagon. 3Næste morgen kom byens indbyggere til templet for at se arken. Men dér lå Dagon næsegrus på jorden foran Guds Ark. De skyndte sig at stille ham på plads igen, 4men næste morgen lå Dagon igen næsegrus på jorden foran Guds Ark. Hovedet og hænderne var tilmed brækket af og lå på dørtærskelen, kun kroppen var tilbage. 5(Det er grunden til, at Dagons præster og de, som dyrker ham, den dag i dag undgår at træde på dørtærsklen til Dagons tempel i Ashdod.)

6Herrens straf kom over indbyggerne i Ashdod. Han sendte en frygtelig plage over dem, så der udbrød en epidemi af bylder både i Ashdod og i de omliggende landsbyer. 7Da folk blev klar over sammenhængen, udbrød de: „Vi vil ikke have Israels Guds Ark her i byen længere. Han er imod os og vil gøre det af med både os og vores gud, Dagon.” 8Så sammenkaldte de filisterbyernes fem konger til rådslagning. „Hvad skal vi gøre ved Israels Guds Ark?” spurgte de. „Lad os flytte den til Gat,” var der nogen der foreslog.

9Men da arken ankom til Gat, sendte Herren den samme plage over indbyggerne der. Både unge og gamle fik bylder, og de blev grebet af rædsel. 10Derfor sendte de arken videre til Ekron.

Da indbyggerne i Ekron så arken komme, protesterede de: „Nu bringer de Israels Guds Ark til os for at slå os ihjel!” 11Byens ledere sendte straks bud til filisterkongerne og bad dem om at sørge for at få arken sendt tilbage til israelitterne, for ellers ville de alle blive udryddet. Byldeplagen var allerede begyndt i Ekron, og indbyggerne var rædselsslagne. 12Nogle døde, mens resten blev dækket af bylder, og deres klageråb lød overalt.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Samuẹli 5:1-12

Àpótí ẹ̀rí Olúwa ní Aṣdodu àti Ekroni

1Lẹ́yìn ìgbà tí àwọn Filistini ti gba àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run lọ, wọ́n gbé e láti Ebeneseri sí Aṣdodu. 2Nígbà tí àwọn Filistini gbé àpótí Ọlọ́run náà lọ sí tẹmpili Dagoni, wọ́n gbé e kalẹ̀ sí ẹ̀bá Dagoni. 3Nígbà tí àwọn ará Aṣdodu jí ní òwúrọ̀ kùtùkùtù ní ọjọ́ kejì, Dagoni ṣubú, ó dojúbolẹ̀ níwájú àpótí Olúwa, wọ́n sì gbé Dagoni, wọ́n tún fi sí ààyè rẹ̀. 4Ṣùgbọ́n ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì nígbà tí wọ́n dìde, Dagoni ṣì wá, ó ṣubú ó dojúbolẹ̀ níwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa. Orí àti ọwọ́ rẹ̀ sì ti gé kúrò, ó sì dùbúlẹ̀ ní orí ìloro ẹnu-ọ̀nà, ara rẹ̀ nìkan ni ó kù. 5Ìdí nìyìí títí di òní tí ó fi jẹ́ pé àlùfáà Dagoni tàbí àwọn mìíràn tí ó wọ inú tẹmpili Dagoni ní Aṣdodu fi ń tẹ orí ìloro ẹnu-ọ̀nà.

6Ọwọ́ Olúwa wúwo lára àwọn ènìyàn Aṣdodu àti gbogbo agbègbè rẹ̀: ó mú ìparun wá sórí wọn, ó sì pọ́n wọn lójú pẹ̀lú ààrùn oníkókó. 7Nígbà tí àwọn ọkùnrin Aṣdodu rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, wọ́n wí pé, “Àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run ti Israẹli kò gbọdọ̀ dúró níbí yìí pẹ̀lú wa, nítorí ọwọ́ rẹ̀ wúwo lára wa àti lára Dagoni ọlọ́run wá.” 8Nígbà náà ni wọ́n pè gbogbo àwọn olórí Filistini jọ wọ́n sì bi wọ́n pé, “Kí ni a ó ṣe pẹ̀lú àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run àwọn Israẹli?”

Wọ́n dáhùn pé, “Ẹ jẹ́ kí á gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run àwọn Israẹli lọ sí Gati.” Wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run Israẹli.

9Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti gbé e, ọwọ́ Olúwa sì wá sí ìlú náà, ó mú jìnnìjìnnì bá wọn. Ó sì pọ́n àwọn ènìyàn ìlú náà lójú, ọmọdé àti àgbà, pẹ̀lú àjàkálẹ̀-ààrùn oníkókó. 10Wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run lọ sí Ekroni.

Bí àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run ṣe wọ Ekroni, àwọn ará Ekroni fi igbe ta pé, “Wọ́n ti gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run Israẹli tọ̀ wá wá láti pa wá àti àwọn ènìyàn wa.” 11Nígbà náà ni wọ́n pe gbogbo àwọn olórí àwọn Filistini jọ wọ́n sì wí pé, “Ẹ gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run àwọn Israẹli lọ: ẹ jẹ́ kí ó padà sí ààyè rẹ̀, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ yóò pa wá àti àwọn ènìyàn wa.” Ikú ti mú jìnnìjìnnì bá àwọn ará ìlú: ọwọ́ Ọlọ́run sì wúwo lára wọn. 12Àwọn tí kò kú wọ́n pọ́n wọn lójú pẹ̀lú ààrùn oníkókó, ẹkún ìlú náà sì gòkè lọ sí ọ̀run.