1. Samuelsbog 24 – BPH & YCB

Bibelen på hverdagsdansk

1. Samuelsbog 24:1-23

1Derefter tog David ophold i klippehulerne ved En-Gedi.

David skåner Sauls liv

2Da Saul vendte tilbage fra slaget mod filistrene, fik han at vide, at David var flygtet ud i En-Gedis ørken. 3Så tog han 3000 elitesoldater med sig og gik ud for at lede efter ham ved Stenbukkeklipperne. 4På det sted, hvor vejen løber forbi nogle fårefolde, gik Saul ind i en hule for at forrette sin nødtørft. Men det var tilfældigvis den hule, hvor David og nogle af hans mænd havde gemt sig længere inde.

5„Nu har du dit livs chance!” hviskede mændene til David. „Det er det her øjeblik, du har ventet på, lige siden den dag Herren sagde til dig: ‚Jeg vil udlevere din fjende til dig, så du kan gøre med ham, som du vil.’ ” Da krøb David frem fra hulens indre og skar forsigtigt det nederste af Sauls kappe af, uden at Saul lagde mærke til det. 6Men bagefter fik han dårlig samvittighed over det, han havde gjort. 7„Må Gud bevare mig fra at gøre min herre noget ondt,” sagde han til sine mænd. „Jeg kan ikke slå Herrens salvede konge ihjel.” 8Og David irettesatte sine mænd og tillod dem ikke at dræbe Saul.

Da Saul havde forladt hulen og var gået videre, 9kom David ud og råbte efter ham: „Min herre og konge!” Og da Saul vendte sig om, bøjede David sig for ham. 10-11„Hvorfor lader du dig narre af dem, der påstår, at jeg er ude på at gøre dig fortræd?” fortsatte han. „I dag har du fået bevis for, at det ikke er sandt. Skønt du var i min hule hånd, og nogle af mine mænd ville have mig til at slå dig ihjel, skånede jeg dit liv og lovede, at jeg ikke ville gøre dig noget ondt, for du er Herrens salvede. 12Se her, hvad jeg har i hånden. Det er kanten af din kappe, som jeg skar af, men jeg slog dig ikke ihjel. Er det ikke nok til at overbevise dig om, at jeg ikke har i sinde at gøre dig fortræd? Jeg ønsker ikke at forsynde mig imod dig, selvom du truer mig på livet.”

13David fortsatte: „Lad Herren dømme imellem os! Han vil straffe dig for, hvad du har gjort imod mig. Men jeg vil ikke tage sagen i min egen hånd. 14Som ordsproget siger: ‚Ondskab er den ondes værk’. Men uanset hvor meget ondskab, du udviser, vil jeg ikke hævne mig på dig. 15I øvrigt synes jeg, du skulle overveje, hvem det er, du forfølger. Bør Israels konge spilde sin tid med at jage en, der er lige så ubetydelig som en død hund eller en loppe? 16Må Herren dømme imellem os og straffe den skyldige. Han er min Forsvarer, og han vil redde mig fra dine angreb.”

17-18Saul råbte tilbage med grådkvalt stemme: „Min søn, David! Er det virkelig dig? David, du har gengældt min ondskab med godhed. Du er et bedre menneske end jeg. 19Det har du klart bevist i dag, da Herren udleverede mig til dig, og du havde chancen for at slå mig ihjel. 20Hvem andre kunne finde på at lade sin fjende undslippe på den måde? Må Herren belønne dig for det. 21Nu indser jeg, at du bliver konge over Israel. 22Sværg da ved Herren, at du ikke vil gøre min familie fortræd og udrydde min slægt, efter at du er blevet konge.”

23Det gjorde David, og Saul vendte hjem, mens David og hans mænd gik tilbage til klippehulen.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Samuẹli 24:1-22

Dafidi da ẹ̀mí Saulu sí

1Nígbà tí Saulu padà kúrò lẹ́yìn àwọn Filistini a sì sọ fún un pé, “Wò ó, Dafidi ń bẹ́ ni aginjù En-Gedi.” 2Saulu sì mú ẹgbẹ̀ẹ́dógún akọni ọkùnrin tí a yàn nínú gbogbo Israẹli ó sì lọ láti wá Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ lórí òkúta àwọn ewúrẹ́ igbó.

3Ó sì dé ibi àwọn agbo àgùntàn tí ó wà ní ọ̀nà, ihò kan sì wà níbẹ̀, Saulu sì wọ inú rẹ̀ lọ láti bo ẹsẹ̀ rẹ̀, Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì ń bẹ lẹ́bàá ihò náà. 4Àwọn ọmọkùnrin Dafidi sì wí fún un pé, “Wò ó, èyí ni ọjọ́ náà tí Olúwa wí fún ọ pé, ‘Wò ó, èmi fi ọ̀tá rẹ lé ọ lọ́wọ́, ìwọ ó sì ṣe sí i gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́ lójú rẹ.’ ” Dafidi sì dìde, ó sì yọ́ lọ gé etí aṣọ Saulu.

5Ó sì ṣe lẹ́yìn èyí, àyà já Dafidi nítorí tí ó gé etí aṣọ Saulu. 6Òun sì wí fún àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ pé, “Èèwọ̀ ni fún mi láti ọ̀dọ́ Olúwa wá bí èmi bá ṣe nǹkan yìí sí ẹni tí a ti fi ààmì òróró Olúwa yàn, láti nawọ́ mi sí i, nítorí pé ẹni ààmì òróró Olúwa ni.” 7Dafidi sì fi ọ̀rọ̀ wọ̀nyí dá àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ dúró, kò sì jẹ́ kí wọn dìde sí Saulu, Saulu sì dìde kúrò ní ihò náà, ó sì bá ọ̀nà rẹ̀ lọ.

8Dafidi sì dìde lẹ́yìn náà, ó sì jáde kúrò nínú ihò náà ó sì kọ sí Saulu pé, “Olúwa mi, ọba!” Saulu sì wo ẹ̀yìn rẹ̀. Dafidi sì dojú rẹ́ bo ilẹ̀ ó sì tẹríba fún un. 9Dafidi sì wí fún Saulu pé, “Èéha ti ṣe tí ìwọ fi ń gbọ́ ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn pé, ‘Wò ó, Dafidi ń wa ẹ̀mí rẹ́’? 10Wò ó, ojú rẹ́ rí i lónìí, bí Olúwa ti fi ìwọ lé mi lọ́wọ́ lónìí nínú ihò; àwọn kan ní kí èmi ó pa ọ; ṣùgbọ́n èmi dá ọ sí; ‘Èmi sì wí pé, èmi kì yóò nawọ́ mi sí olúwa mi, nítorí pé ẹni ààmì òróró Olúwa ni òun jẹ́.’ 11Pẹ̀lúpẹ̀lú, baba mi, wò ó, àní wo etí aṣọ rẹ lọ́wọ́ mi; nítorí èmi gé etí aṣọ rẹ, èmi kò sì pa ọ́, sì wò ó, kí o sì mọ̀ pé kò sí ibi tàbí ẹ̀ṣẹ̀ lọ́wọ́ mi, èmi kò sì ṣẹ̀ ọ̀, ṣùgbọ́n ìwọ ń dọdẹ ẹ̀mí mi láti gbà á. 12Olúwa ṣe ìdájọ́ láàrín èmi àti ìwọ, àti kí Olúwa ó gbẹ̀san mi lára rẹ; ṣùgbọ́n, ọwọ́ mi kì yóò sí lára rẹ. 13Gẹ́gẹ́ bí òwe ìgbà àtijọ́ ti wí, ìwà búburú a máa ti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn búburú jáde wá; ṣùgbọ́n ọwọ́ mi kì yóò sí lára rẹ.

14“Nítorí ta ni ọba Israẹli fi jáde? Ta ni ìwọ ń lépa? Òkú ajá, tàbí eṣinṣin? 15Olúwa ó ṣe onídàájọ́, kí ó sì dájọ́ láàrín èmi àti ìwọ, kí ó sì gbèjà mi, kí ó sì gbà mí kúrò lọ́wọ́ rẹ.”

16Ó sì ṣe, nígbà tí Dafidi sì dákẹ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún Saulu, Saulu sì wí pé, “Ohùn rẹ ni èyí bí, Dafidi ọmọ mi?” Saulu sì gbé ohùn rẹ̀ sókè, ó sọkún. 17Ó sì wí fún Dafidi pé, “Ìwọ ṣe olódodo jù mí lọ; nítorí pé ìwọ ti fi ìre san án fún mi, èmi fi ibi san án fún ọ. 18Ìwọ sì fi oore tí ìwọ ti ṣe fún mi hàn lónìí: nígbà tí ó jẹ́ pé, Olúwa ti fi ẹ̀mí mi lé ọ lọ́wọ́, Ìwọ kò sì pa mí. 19Nítorí pé bí ènìyàn bá rí ọ̀tá rẹ̀, ó lè jẹ́ kí ó lọ ní àlàáfíà bí? Olúwa yóò sì fi ìre san èyí ti ìwọ ṣe fún mi lónìí. 20Wò ó, èmi mọ̀ nísinsin yìí pé, nítòótọ́ ìwọ ó jẹ ọba, àti pé ìjọba Israẹli yóò sì fi ìdí múlẹ̀ ní ọwọ́ rẹ. 21Sì búra fún mi nísinsin yìí ní orúkọ Olúwa, pé, ìwọ kì yóò gé irú-ọmọ mi kúrò lẹ́yìn mi, àti pé, ìwọ kì yóò pa orúkọ mi run kúrò ní ìdílé baba mi.”

22Dafidi sì búra fún Saulu. Saulu sì lọ sí ilé rẹ̀; ṣùgbọ́n Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì gòkè lọ sí ihò náà.