1. Samuelsbog 16 – BPH & YCB

Bibelen på hverdagsdansk

1. Samuelsbog 16:1-23

Samuel salver David til konge

1Efter nogen tid sagde Herren til Samuel: „Jeg har jo forkastet Saul som konge i Israel! Hvor længe endnu vil du gå og sørge over ham? Fyld hellere dit horn med olivenolie og gå til Betlehem. Dér skal du opsøge en mand ved navn Isaj, for jeg har udvalgt en af hans sønner til at være Israels nye konge.”

2„Hvordan skal jeg kunne gøre det?” indvendte Samuel. „Hvis Saul får det at vide, slår han mig ihjel.”

„Tag en kvie med dig,” svarede Herren, „og sig, at du er kommet for at ofre til Herren. 3Så skal du invitere Isaj til at deltage i ofringen, og jeg vil vise dig, hvem af hans sønner du skal salve til konge.”

4Samuel gjorde nu, som Herren havde sagt, og han ankom til Betlehem. Men byens ledere blev bange, da de så ham. „Er der noget galt?” spurgte de. „Hvad er grunden til dit besøg?”

5Samuel svarede: „Der er ikke noget galt. Jeg er kommet for at ofre til Herren. Rens jer og kom så til offerfesten.”

Samuel sørgede for at Isaj og hans sønner gennemgik renselsesritualet og indbød dem til ofringen. 6Da de kom, og Samuel så Isajs søn Eliab, tænkte han: „Det må være ham!” 7Men Herren svarede: „Nej, det er ikke ham! Bedøm ikke en mand efter hans udseende og højde. Mennesker bedømmer hinanden efter det ydre, men Herren ser på hjertet.”

8Derefter præsenterede Isaj sin næste søn, Abinadab, for Samuel, men Herren sagde: „Det er heller ikke ham.”

9Så præsenterede Isaj sin næste søn, Shamma, men Herren sagde: „Det er heller ikke ham.” 10På samme måde gik det med de fire næste sønner.

„Det er ikke nogen af de syv, Herren har udvalgt,” sagde Samuel til Isaj. 11„Er det alle de sønner, du har?”

„Nej. Der er en mere, den yngste, han vogter får ude på marken,” svarede Isaj.

„Send straks bud efter ham,” befalede Samuel. „Vi sætter os ikke til bords, før han kommer.”

12Så sendte Isaj bud efter David. Han var en rask og rødmosset dreng med et godt udseende og kønne øjne, og Herren sagde: „Det er ham, du skal salve til konge!”

13Da hældte Samuel olivenolien ud over Davids hoved og salvede ham for øjnene af hans brødre, og Herrens Ånd kom over ham og blev over ham fra den dag af. Så vendte Samuel tilbage til Rama.

David kommer i tjeneste hos Saul

14Men Herrens Ånd havde forladt Saul, og i stedet blev han plaget af en ond ånd fra Herren. 15-16„Det er en ond ånd fra Gud, som plager dig,” sagde Sauls tjenere. „Hvis du synes om det, vil vi finde en, der kan spille på lyre16,15-16 Det fleste fortolkere mener i dag, at det hebraiske ord kinnur svarer til en lyre snarere end en harpe. for dig, når den onde ånd plager dig, så du falder til ro og får det bedre.”

17„Ja, find en mand som er dygtig til at spille, og bring ham til mig,” svarede Saul.

18En af tjenerne sagde: „Jeg kender en ung mand i Betlehem, en søn af Isaj. Han er ikke bare dygtig til at spille, han er også en modig kriger. Han taler kloge ord, og ser godt ud. Herren er med ham!”

19Så sendte Saul bud til Isaj: „Send mig din søn, David, ham, som vogter dine får.” 20Isaj læssede derpå et æsel med brød, en lædersæk med vin og et gedekid og sendte David af sted med denne gave til Saul. 21Sådan gik det til, at David kom i tjeneste hos Saul, som kom til at holde af ham og gjorde ham til sin våbendrager. 22Så sendte Saul igen bud til Isaj og sagde: „Lad David blive i min tjeneste, for jeg er godt tilfreds med ham.”

23Når Saul blev plaget af den onde ånd fra Gud, tog David sin lyre og spillede for ham. Så forlod den onde ånd Saul, og han følte sig meget bedre tilpas.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Samuẹli 16:1-23

Samuẹli fi òróró yan Dafidi

1Olúwa sọ fún Samuẹli pé, “Yóò ha ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò máa dárò Saulu, nígbà tí ó jẹ́ pé mo ti kọ̀ ọ́ ní ọba lórí Israẹli? Rọ òróró kún inú ìwo rẹ, kí o sì mú ọ̀nà rẹ pọ̀n, Èmi rán ọ sí Jese ará Bẹtilẹhẹmu. Èmi ti yan ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ láti jẹ ọba.”

2Ṣùgbọ́n Samuẹli wí pé; “Báwo ni èmi yóò ṣe lọ? Bí Saulu bá gbọ́ nípa rẹ̀, yóò pa mi.”

Olúwa wí pé, “Mú abo ẹgbọrọ màlúù kan pẹ̀lú rẹ, kí o sì wí pé, ‘Èmi wá láti wá rú ẹbọ sí Olúwa.’ 3Pe Jese wá sí ibi ìrúbọ náà, Èmi yóò sì fi ohun tí ìwọ yóò ṣe hàn ọ́. Ìwọ yóò fi òróró yàn fún mi, ẹni tí èmi bá fihàn ọ́.”

4Samuẹli ṣe ohun tí Olúwa sọ. Nígbà tí ó dé Bẹtilẹhẹmu, àyà gbogbo àgbàgbà ìlú já, nígbà tí wọ́n pàdé rẹ̀. Wọ́n béèrè pé, “Ṣé àlàáfíà ní ìwọ bá wá?”

5Samuẹli sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni àlàáfíà ni; mo wá láti wá rú ẹbọ sí Olúwa. Ẹ ya ara yín sí mímọ́, kí ẹ sì wá rú ẹbọ pẹ̀lú mi.” Nígbà náà ni ó sì ya Jese sí mímọ́ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀, ó sì pè wọ́n wá sí ibi ìrúbọ náà.

6Nígbà tí wọ́n dé, Samuẹli rí Eliabu, ó rò nínú ara rẹ̀ pé lóòótọ́ ẹni òróró Olúwa dúró níbí níwájú Olúwa.

7Ṣùgbọ́n Olúwa sọ fún Samuẹli pé, “Má ṣe wo ti ìrísí rẹ̀ tàbí ti gíga rẹ̀, nítorí èmi ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Olúwa kì í wo ohun tí ènìyàn máa ń wò. Ènìyàn máa ń wo òde ara ṣùgbọ́n Olúwa máa ń wo ọkàn.”

8Nígbà náà ni Jese pe Abinadabu, ó sì jẹ́ kí ó rìn kọjá ní iwájú Samuẹli. Ṣùgbọ́n Samuẹli wí pé, “Olúwa kò yan ẹni yìí.” 9Jese sì jẹ́ kí Ṣamma rìn kọjá ní iwájú Samuẹli, ṣùgbọ́n Samuẹli wí pé, “Olúwa kò yan ẹni yìí náà.” 10Jese jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ̀ méje rìn kọjá ní iwájú Samuẹli ṣùgbọ́n Samuẹli sọ fún un pé, “Olúwa kò yan àwọn wọ̀nyí.” 11Nígbà náà ni ó béèrè lọ́wọ́ Jese pé, “Ṣé èyí ni gbogbo àwọn ọmọ rẹ?”

Jese dáhùn pé, “Ó ku àbíkẹ́yìn wọn, ó ń tọ́jú agbo àgùntàn.”

Samuẹli sì wí pé, “Rán ìránṣẹ́ lọ pè é wá; àwa kò ní jókòó títí òun yóò fi dé.”

12Ó sì ránṣẹ́ sí i, wọ́n sì mú un wọlé wá, ó jẹ́ ẹni tó mọ́ra, àwọ̀ ara rẹ̀ dùn ún wò, ó jẹ́ arẹwà gidigidi.

Nígbà náà ni Olúwa wí pé, “Dìde kí o sì fi òróró yàn án, òun ni ẹni náà.”

13Nígbà náà ni Samuẹli mú ìwo òróró, ó sì ta á sí i ní orí ní iwájú àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀, láti ọjọ́ náà lọ, Ẹ̀mí mímọ́ Olúwa wá sí orí Dafidi nínú agbára. Samuẹli sì lọ sí Rama.

Dafidi nínú iṣẹ́ ẹ Saulu

14Nísinsin yìí, ẹ̀mí Olúwa ti kúrò lára Saulu, ẹ̀mí búburú láti ọ̀dọ̀ Olúwa sì ń yọ ọ́ lẹ́nu.

15Àwọn ìránṣẹ́ Saulu sì wí fún un pé, “Wò ó, ẹ̀mí búburú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá ń yọ ọ́ lẹ́nu. 16Jẹ́ kí olúwa wa pàṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ó wà níhìn-ín láti wa ẹnìkan tí ó lè fi dùùrù kọrin. Yóò sì ṣe é nígbà tí ẹ̀mí búburú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bá bà lé ọ, ìwọ yóò sì sàn.”

17Nígbà náà ni Saulu wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ wá ẹnìkan tí ó lè kọrin dáradára kí ẹ sì mú u wá fún mi.”

18Ọ̀kan nínú ìránṣẹ́ náà dáhùn pé, “Èmi ti ri ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Jese ti Bẹtilẹhẹmu tí ó mọ orin kọ, ó jẹ́ alágbára àti ológun. Ó ní ọgbọ́n ọ̀rọ̀ òun sì dára ní wíwò. Olúwa sì wà pẹ̀lú u rẹ̀.”

19Saulu sì rán oníṣẹ́ sí Jese wí pé, “Rán Dafidi ọmọ rẹ sí mi, ẹni tí ó ń ṣọ́ àgùntàn.” 20Jese sì mú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ti a di ẹrù lé àti ìgò ọtí wáìnì àti ọmọ ewúrẹ́; ó sì rán wọn nípa ọwọ́ Dafidi ọmọ rẹ̀ sí Saulu.

21Dafidi sì tọ Saulu lọ, ó sì dúró níwájú rẹ̀: òun sì fẹ́ ẹ gidigidi, Dafidi sì wá di ọ̀kan nínú àwọn tí ń ru ìhámọ́ra rẹ̀. 22Nígbà náà ni Saulu ránṣẹ́ sí Jese pé, “Jẹ́ kí Dafidi dúró níwájú mi, nítorí tí ó wù mí.”

23Ó sì ṣe, nígbà tí ẹ̀mí búburú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá bá dé sí Saulu, Dafidi a sì fi ọwọ́ rẹ̀ kọrin lára dùùrù: a sì san fún Saulu, ara rẹ̀ a sì dá; ẹ̀mí búburú náà a sì fi sílẹ̀.