1. Kongebog 3 – BPH & YCB

Bibelen på hverdagsdansk

1. Kongebog 3:1-28

Salomon beder om visdom

1Salomon gik derefter i forbund med Egypten ved at gifte sig med en datter af den egyptiske konge. Han førte hende til Davidsbyen og boede med hende der, indtil Herrens hus, hans eget palads og bymuren blev færdigbygget.

2Da Herrens hus endnu ikke var bygget, udførte folket deres ofringer rundt omkring på landets offerhøje. 3Salomon elskede Herren og fulgte nøje de anvisninger, hans far havde givet ham, men han fortsatte dog med at ofre dyr og brænde røgelse på de gamle offerhøje.

4En dag tog Salomon til Gibeon for at ofre, for det store alter3,4 Ifølge 2.Krøn. 1,3-6 stod åbenbaringsteltet på Gibeonhøjen på dette tidspunkt, mens pagtens ark stod i Jerusalem. fandtes der, og han bragte tusind brændofre på alteret. Mens han var i Gibeon, 5viste Herren sig for ham i en drøm om natten og sagde: „Bed om hvad du vil, og jeg vil give det til dig!”

6Salomon svarede: „Du har været umådelig god imod min far, fordi han var både trofast, retskaffen og oprigtig i sit forhold til dig. At du gav ham en søn til at følge ham på tronen er et udtryk for din trofasthed imod ham. 7Herre, min Gud, nu har du gjort mig til konge i min fars sted, men jeg er ung og uerfaren. 8Det forventes af mig, at jeg skal regere dit udvalgte folk—et folk så stort, at det ikke kan tælles. 9Giv mig derfor et lydhørt hjerte, så jeg kan lede dit folk, så jeg kan skelne mellem, hvad der er rigtigt og forkert. For hvem kan magte at regere over dit mægtige folk?”

10Herren syntes godt om Salomons ønske 11og svarede: „Fordi du bad om evne til at træffe de rigtige beslutninger og ikke om rigdom til dig selv, et langt liv, eller død over dine fjender, 12vil jeg opfylde din bøn: Jeg vil give dig større visdom end nogen anden nogen sinde har haft eller vil få. 13Men jeg vil også give dig, hvad du ikke bad om—nemlig rigdom og berømmelse. Så længe du lever, vil ingen af alle verdens konger kunne måle sig med dig. 14Og hvis du adlyder mine love og forordninger, sådan som din far gjorde, vil jeg give dig et langt liv i tilgift.”

15Så vågnede Salomon og blev klar over, at han havde drømt; og han vendte tilbage til Jerusalem og gik ind i teltet med Herrens Ark. Foran arken ofrede han brændofre og takofre til Gud, og bagefter holdt han en fest for alle sine embedsmænd.

Et eksempel på Salomons visdom

16En dag søgte to prostituerede audiens hos kongen. De ville have ham til at fælde dom i en bestemt sag.

17„Herre,” sagde den første, „vi to bor i samme hus, og for nylig fødte jeg et barn, mens hun var til stede. 18To dage senere fødte hun også et barn. Der var ingen andre end os i huset, så der var ingen vidner. 19Men hendes dreng døde midt om natten, fordi hun kom til at ligge på ham. 20Mens jeg stadig lå og sov, stod hun op og tog min søn, som lå ved min side, og lagde ham over i sin egen seng. Derefter anbragte hun sin egen døde søn hos mig. 21Tidligt om morgenen stod jeg op for at amme mit barn, men så opdagede jeg, at drengen var død! Men da jeg så nøje på ham, kunne jeg se, at den døde dreng slet ikke var min søn.”

22„Det passer ikke!” protesterede den anden kvinde. „Det er min søn, der lever, og din, der er død!”

„Nej,” svarede den første kvinde, „den døde dreng er din, og den levende er min!” Sådan blev de ved med at skændes et stykke tid.

23Da sagde kongen: „I kan åbenbart ikke blive enige. 24Hent mig lige et sværd!” Så blev der hentet et sværd, 25og kongen gav følgende ordre: „Tag det levende barn og hug det midt over, så kan hver af kvinderne få halvdelen!”

26Men hende, der var mor til barnet, holdt jo af det og råbte: „Åh nej, herre, dræb ikke barnet! Så giv det hellere til hende!” Men den anden kvinde sagde: „Nej, hvis ingen af os kan få barnet, er det bedre at hugge det midt over!”

27Da faldt kongens dom: „Slå ikke barnet ihjel,” befalede han, „men giv det til den kvinde, som ønskede at skåne det; for det er hende, der er mor til barnet.”

28Rygtet om kongens kloge dom spredtes hurtigt ud over landet, og det skabte respekt omkring ham, for alle var forbløffet over den visdom, Gud havde givet Salomon.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Ọba 3:1-28

Solomoni béèrè fún ọgbọ́n

1Solomoni sì bá Farao ọba Ejibiti dá àna, ó sì fẹ́ ọmọbìnrin rẹ̀ ní ìyàwó. Ó sì mú un wá sí ìlú Dafidi títí tí ó fi parí kíkọ́ ààfin rẹ̀ àti tẹmpili Olúwa, àti odi tí ó yí Jerusalẹmu ká. 2Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn ènìyàn ṣì ń rú ẹbọ ní ibi gíga, nítorí a kò tí ì kọ́ ilé fún orúkọ Olúwa títí di ìgbà náà 3Solomoni sì fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn sí Olúwa nípa rírìn gẹ́gẹ́ bí òfin Dafidi baba rẹ̀, àti pé, ó rú ẹbọ, ó sì fi tùràrí jóná ní ibi gíga.

43.4-15: 2Ki 1.3-13.Ọba sì lọ sí Gibeoni láti rú ẹbọ, nítorí ibẹ̀ ni ibi gíga tí ó ṣe pàtàkì jù, Solomoni sì rú ẹgbẹ̀rún ọrẹ ẹbọ sísun lórí pẹpẹ. 5Ní Gibeoni, Olúwa fi ara han Solomoni lójú àlá ní òru, Ọlọ́run sì wí pé, “Béèrè fún ohunkóhun tí o bá ń fẹ́ kí èmi ó fi fún ọ.”

6Solomoni sì dáhùn wí pé, “O ti fi inú rere oore ńlá hàn sí ìránṣẹ́ rẹ, Dafidi baba mi, nítorí ó jẹ́ olóòtítọ́ sí ọ àti olódodo àti ẹni tí ó ní ọkàn ìdúró ṣinṣin. Ìwọ sì tẹ̀síwájú nínú oore ńlá yìí fún un, ìwọ sì ti fún un ní ọmọkùnrin láti jókòó lórí ìtẹ́ rẹ ní gbogbo ọjọ́.

7“Nísinsin yìí, Olúwa Ọlọ́run mi, o ti mú ìránṣẹ́ rẹ jẹ ọba ní ipò Dafidi baba mi. Ṣùgbọ́n ọmọ kékeré ni mí, èmi kò sì mọ jíjáde àti wíwọlé mi. 8Ìránṣẹ́ rẹ nìyí láàrín àwọn ènìyàn tí o ti yàn, àwọn ènìyàn ńlá, wọ́n pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí a kò sì lè kà wọ́n tàbí mọye wọn. 9Nítorí náà fi ọkàn ìmòye fún ìránṣẹ́ rẹ láti le ṣàkóso àwọn ènìyàn rẹ àti láti mọ ìyàtọ̀ láàrín rere àti búburú. Nítorí ta ni ó lè ṣe àkóso àwọn ènìyàn ńlá rẹ yìí?”

10Inú Olúwa sì dùn pé Solomoni béèrè nǹkan yìí. 11Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún un pé, “Nítorí tí ìwọ ti béèrè fún èyí, tí kì í ṣe ẹ̀mí gígùn tàbí ọrọ̀ fún ara rẹ, tàbí béèrè fún ikú àwọn ọ̀tá rẹ, ṣùgbọ́n fún òye láti mọ ẹjọ́ dá, 12èmi yóò ṣe ohun tí ìwọ ti béèrè. Èmi yóò fún ọ ní ọgbọ́n àti ọkàn ìmòye, tó bẹ́ẹ̀ tí kò fi ní sí ẹnìkan tí ó dàbí rẹ ṣáájú rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kì yóò dìde tí yóò dàbí rẹ lẹ́yìn rẹ. 13Síwájú sí i, èmi yóò fi ohun tí ìwọ kò béèrè fún ọ: ọrọ̀ àti ọlá ní gbogbo ayé rẹ, tí kì yóò sí ẹnìkan nínú àwọn ọba tí yóò dàbí rẹ. 14Àti bí ìwọ bá rìn ní ọ̀nà mi, tí o sì pa òfin àti àṣẹ mi mọ́ bí Dafidi baba rẹ ti ṣe, èmi yóò fún ọ ní ẹ̀mí gígùn.” 15Solomoni jí: ó sì mọ̀ pé àlá ni.

Ó sì padà sí Jerusalẹmu, ó sì dúró níwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa, ó sì rú ẹbọ sísun àti ẹbọ àlàáfíà. Nígbà náà ni ó ṣe àsè fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.

Ìdájọ́ ọgbọ́n

16Lẹ́yìn náà ni àwọn obìnrin alágbèrè méjì wá sọ́dọ̀ ọba, wọ́n sì dúró níwájú rẹ̀. 17Ọ̀kan nínú wọn sì wí pé, “Olúwa mi, èmi àti obìnrin yìí ń gbé nínú ilé kan. Èmi sì bí ọmọ ní ilé pẹ̀lú rẹ̀. 18Ní ọjọ́ kẹta lẹ́yìn ìgbà tí mo bímọ tan, obìnrin yìí sì bímọ pẹ̀lú. A sì nìkan dá wà; kò sí àlejò ní ilé bí kò ṣe àwa méjèèjì nìkan.

19“Ní òru, ọmọ obìnrin yìí kú nítorí tí ó sùn lé e. 20Nígbà náà ni ó sì dìde ní ọ̀gànjọ́, ó sì gbé ọmọ tèmi lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi, nígbà tí èmi ìránṣẹ́ rẹ̀ ti sùn lọ. Ó sì tẹ́ ẹ sí àyà rẹ̀, ó sì tẹ́ òkú ọmọ tirẹ̀ sí àyà mi. 21Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, mo sì dìde láti fi ọmú fún ọmọ mi: ó sì ti kú! Ṣùgbọ́n, nígbà tí mo sì wò ó fín ní òwúrọ̀, mo sì rí i pé kì í ṣe ọmọ mi tí mo bí.”

22Obìnrin kejì sì wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́! Èyí alààyè ni ọmọ mi, èyí òkú ni ọmọ tirẹ̀.” Èyí òkú ni tirẹ̀; èyí alààyè ni tèmi.

Ṣùgbọ́n èyí àkọ́kọ́ tún wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́! Èyí òkú ni tìrẹ; èyí alààyè ni tèmi.” Báyìí ni wọ́n sì ń jiyàn níwájú ọba.

23Ọba sì wí pé, “Ẹni yìí wí pé, ‘Ọmọ mi ni ó wà láààyè, ọmọ tirẹ̀ ni ó kú,’ nígbà tí ẹni èkejì náà ń wí pé, ‘Bẹ́ẹ̀ kọ́! Ọmọ tirẹ̀ ni ó kú, ọmọ tèmi ni ó wà láààyè.’ ”

24Nígbà náà ni ọba wí pé, “Ẹ mú idà fún mi wá.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì mú idà wá fún ọba. 25Ọba sì pàṣẹ pé: “Ẹ gé alààyè ọmọ sí méjì, kí ẹ sì mú ìdajì fún ọ̀kan, àti ìdajì fún èkejì.”

26Obìnrin tí ọmọ tirẹ̀ wà láààyè sì kún fún àánú fún ọmọ rẹ̀, ó sì wí fún ọba pé, “Jọ̀wọ́, olúwa mi, ẹ fún un ní alààyè ọmọ! Ẹ má ṣe pa á!”

Ṣùgbọ́n obìnrin èkejì sì wí pé, “Kì yóò jẹ́ tèmi tàbí tìrẹ. Ẹ gé e sí méjì!”

27Nígbà náà ni ọba dáhùn, ó wí pé, “Ẹ fi alààyè ọmọ fún obìnrin àkọ́kọ́. Ẹ má ṣe pa á: òun ni ìyá rẹ̀.”

28Nígbà tí gbogbo Israẹli gbọ́ ìdájọ́ tí ọba ṣe, wọ́n sì bẹ̀rù níwájú ọba, nítorí wọ́n ti rí í pé ó ní ọgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run láti ṣe ìdájọ́.