Ezéchiel 27 – BDS & YCB

La Bible du Semeur

Ezéchiel 27:1-36

La chute d’une puissance

1L’Eternel m’adressa la parole en ces termes : 2Fils d’homme, entonne une complainte sur la cité de Tyr. 3Dis donc à Tyr qui est assise aux portes de la mer et qui commerce avec tant de peuplades de nombreuses îles et régions côtières : voici ce que déclare le Seigneur, l’Eternel :

Toi, ô Tyr, tu as dit :

« Ma beauté est parfaite ! »

4Ton territoire ╵se trouve au cœur des mers,

et ceux qui t’ont construite ╵ont rendu ta beauté parfaite.

5Ils ont bâti tous tes bordages

en cyprès de Senir27.5 Nom amoréen pour le mont Hermon. Tyr est comparée à un bateau.,

ils t’ont donné pour mât ╵un cèdre du Liban.

6Ils ont pris pour tes rames ╵des chênes du Basan,

ton pont est en ivoire

incrusté dans du bois, ╵dans du cyprès ╵importé des îles de Chypre.

7Du lin brodé d’Egypte ╵te servait de voilure :

c’était ton pavillon.

Tu avais pour tentures

la pourpre et l’écarlate ╵des îles d’Elisha27.7 Ville sur la côte est de Chypre. Certains pensent aux îles du Péloponnèse..

8Les habitants d’Arvad ╵et de Sidon27.8 Deux ports de la côte phénicienne proches de Tyr (voir Gn 10.18-19).

te servaient de rameurs,

et les plus habiles chez toi, ô Tyr

étaient tes matelots.

9Tu employais chez toi ╵les artisans ╵expérimentés de Byblos27.9 Port célèbre situé entre Arvad et Sidon.,

pour effectuer tes réparations.

Tous les bateaux des mers ╵avec leurs matelots ╵se rencontraient chez toi

pour négocier tes marchandises.

10Les Perses et ceux de Loud ╵comme de Pouth27.10 Loud et Pouth: voir Gn 10.6, 22 et notes.

entraient dans ton armée.

C’étaient tes gens de guerre.

Ils suspendaient chez toi ╵leurs boucliers, leurs casques,

et assuraient ta gloire.

11Les gens d’Arvad et leur armée

étaient sur tes murailles

tout autour de la ville,

les hommes de Gammad27.11 Gammad: soit au nord de l’Asie Mineure, soit une ville côtière près d’Arvad. ╵étaient dans tes donjons.

Ils suspendaient leurs armes ╵aux murs d’enceinte

et rendaient ta beauté parfaite.

Une commerçante prestigieuse

12Tarsis27.12 Port d’Espagne, colonie phénicienne. échangeait avec toi des biens de toutes sortes en abondance ; elle te donnait de l’argent, du fer, de l’étain et du plomb contre tes marchandises. 13Yavân, Toubal, Méshek27.13 Yavân désigne les îles grecques. Toubal et Méshek: en Asie Mineure. commerçaient avec toi, ils donnaient des esclaves et des objets de bronze en échange de tes marchandises. 14Ceux de Beth-Togarma27.14 Beth-Togarma: probablement l’Arménie. pourvoyaient tes marchés de chevaux pour la guerre et de chevaux de trait ainsi que de mulets. 15Les gens de Dedân27.15 Voir 25.13 et note. commerçaient avec toi, tes marchés s’étendaient jusqu’aux nombreuses îles et régions côtières qui te payaient ton dû en défenses d’ivoire et avec de l’ébène. 16La Syrie27.16 D’après la plupart des manuscrits hébreux. Quelques manuscrits hébreux et l’ancienne version grecque ont : les Edomites. La différence est due à la confusion entre deux lettres hébraïques très ressemblantes. t’achetait des produits de tous genres, te payant en retour en pierres d’escarboucle, en tissus écarlates, en belles broderies, en tissus de fin lin, en corail et rubis. 17Juda et Israël commerçaient avec toi, te donnant en échange du froment de Minnith27.17 Ville ammonite, réputée pour ses céréales, située au nord de Heshbôn., du biscuit et du miel, de l’huile et du baume. 18La ville de Damas commerçait avec toi, elle était attirée par tes nombreux produits, et tes biens abondants, te livrant en paiement le vin de Helbôn27.18 Ville au nord de Damas, réputée pour son vin. et la laine de Tsahar. 19Vedân, Yavân et Meouzal27.19 Peut-être des tribus arabes. pourvoyaient tes marchés, en fer forgé, en casse et en roseau aromatique contre tes marchandises. 20Dedân te fournissait des étoffes de selle. 21Les peuplades arabes et tous les princes de Qédar27.21 Région du désert de l’Arabie (voir Es 21.13-17). négociaient avec toi, pourvoyant ton marché d’agneaux, de béliers et de boucs. 22Les marchands de Saba et ceux de Raema27.22 Régions de l’Arabie du Sud (cf. Gn 10.7). commerçaient avec toi payant tes marchandises des meilleurs aromates, de gemmes de tous genres et d’or. 23Harân, Kanné, Eden, les marchands de Saba, d’Assur et de Kilmad27.23 Villes et contrées de la Mésopotamie. commerçaient avec toi. 24Ils faisaient le commerce d’objets de luxe, de manteaux teints de pourpre et finement brodés, de tissus27.24 Autre traduction : tapis. de couleur, de forts cordons tressés pour tes négoces.

Une chute retentissante

25Les vaisseaux au long cours27.25 Voir note 2 Ch 20.37. ╵assuraient le transport ╵de tes produits.

Oui, tu étais remplie ╵et lourdement chargée ╵de marchandises

au cœur des mers27.25 Pour les v. 25-36, voir Ap 18.11-19..

26Mais sur les grandes eaux ╵où t’avaient amenée ╵ceux qui maniaient tes rames,

tu as été brisée ╵par le vent de l’orient ╵au cœur des mers27.26 Vent très violent (Ps 48.8 ; Jb 1.19). Ici, il symbolise peut-être les armées de Nabuchodonosor (17.10 ; 19.12).

27et tes richesses, ╵tes marchandises, ╵les articles de ton commerce,

tes marins et tes matelots,

les ouvriers ╵qui réparent tes avaries,

et tes marchands,

tous les hommes de guerre ╵qui sont chez toi,

toute la multitude ╵qui remplit ton navire,

tous tomberont ╵au cœur des mers

au jour de ton naufrage.

28Au cri que pousseront ╵tes matelots,

les régions de la côte ╵se mettront à trembler.

29Alors tous les rameurs,

les matelots, tous les marins ╵qui sillonnent la mer ╵quitteront leurs navires

et se tiendront sur terre,

30ils se lamenteront sur toi

et pousseront des cris amers ;

ils répandront ╵de la poussière sur leur tête,

et se rouleront dans la cendre.

31Ils se raseront la tête à cause de toi,

ils mettront un habit ╵fait de toile de sac,

plongés dans l’affliction ╵ils pleureront sur toi

et avec amertume, ╵ils se lamenteront.

32Dans leur douleur, ╵ils chanteront sur toi ╵une élégie funèbre.

Voici ce qu’ils diront ╵dans leur complainte :

« Qui était comme Tyr,

désormais silencieuse27.32 maintenant silencieuse. Autre traduction : comme la citadelle. ╵au milieu de la mer ? »

33Lorsque tes marchandises ╵arrivaient par les mers,

tu comblais les besoins ╵de peuples innombrables.

Par la surabondance ╵de tes produits

et de tes marchandises, ╵tu enrichissais les rois de la terre.

34Mais te voilà brisée ╵par les flots de la mer,

jetée au fond des eaux profondes !

Toute ta cargaison ╵et tout ton équipage

ont sombré avec toi.

35Les habitants des îles ╵sont frappés de stupeur

à cause de ton sort,

leurs rois sont secoués ╵d’un frisson d’épouvante

et la consternation ╵se lit sur leurs visages.

36Ceux qui commercent ╵parmi les peuples ╵sifflent d’horreur ╵à ton sujet,

ton sort inspire l’épouvante,

et pour toujours, ╵toi, tu ne seras plus !

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Esekiẹli 27:1-36

Ìpohùnréré ẹkún fún Tire

1Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé: 2“Ọmọ ènìyàn, pohùnréré ẹkún fún Tire. 3Sọ fún Tire, tí a tẹ̀dó sí ẹnu-bodè Òkun, oníṣòwò àwọn orílẹ̀-èdè fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ erékùṣù. ‘Èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí:

“ ‘Ìwọ Tire wí pé

“Ẹwà mi pé.”

4Ààlà rẹ wà ní àárín Òkun;

àwọn ọ̀mọ̀lé rẹ ti mú ẹwà rẹ pé.

5Wọn ṣe gbogbo pákó rẹ

ní igi junifa láti Seniri;

wọ́n ti mú igi kedari láti Lebanoni wá

láti fi ṣe òpó ọkọ̀ fún ọ.

6Nínú igi óákù ti Baṣani

ní wọn ti fi gbẹ́ ìtukọ̀ ọ̀pá rẹ̀;

ìjókòó rẹ ni wọn fi eyín erin ṣe pẹ̀lú

igi bokisi láti erékùṣù Kittimu wá

7Ọ̀gbọ̀ dáradára aṣọ iṣẹ́ ọnà abẹ́rẹ́ láti Ejibiti wá

ni èyí tí ìwọ ta láti fi ṣe àsíá ọkọ̀ rẹ;

aṣọ aláró àti elése àlùkò

láti erékùṣù ti Eliṣa

ni èyí tí a fi bò ó

8Àwọn ará ìlú Sidoni àti Arfadi ni àwọn atukọ̀ rẹ̀

àwọn ọlọ́gbọ́n ẹ̀rọ rẹ, ìwọ Tire,

ni àwọn atukọ̀ rẹ.

9Àwọn àgbàgbà Gebali,

àti àwọn ọlọ́gbọ́n ibẹ̀,

wà nínú ọkọ̀ bí òṣìṣẹ́ atukọ̀ rẹ,

gbogbo ọkọ̀ ojú Òkun

àti àwọn atukọ̀ Òkun

wá pẹ̀lú rẹ láti dòwò pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.

10“ ‘Àwọn ènìyàn Persia, Ludi àti Puti

wà nínú jagunjagun rẹ

àwọn ẹgbẹ́ ọmọ-ogun rẹ.

Wọ́n gbé asà àti àṣíborí wọn ró

sára ògiri rẹ,

wọn fi ẹwà rẹ hàn.

11Àwọn ènìyàn Arfadi àti Heleki

wà lórí odi rẹ yíká;

àti àwọn akọni Gamadi,

wà nínú ilé ìṣọ́ rẹ.

Wọ́n fi àwọn asà wọn kọ ara odi rẹ;

wọn ti mú ẹwà rẹ pé.

12“ ‘Tarṣiṣi ṣòwò pẹ̀lú rẹ torí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ tí ó ní; wọn ṣe ìpààrọ̀ fàdákà, irin idẹ àti òjé fún ọjà títà rẹ̀.

13“ ‘Àwọn ará Giriki, Tubali, Jafani àti Meṣeki, ṣòwò pẹ̀lú rẹ: wọ́n fi ẹrù àti ohun èlò idẹ ṣe pàṣípàrọ̀ fún ọrọ̀ rẹ.

14“ ‘Àwọn ti ilé Beti-Togarma ṣe ìpààrọ̀ ẹṣin-ìṣiṣẹ́, ẹṣin ogun àti ìbáaka ṣòwò ní ọjà rẹ.

15“ ‘Àwọn ènìyàn Dedani ni àwọn oníṣòwò rẹ, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ erékùṣù ni wọ́n jẹ́ oníbàárà rẹ̀; wọ́n mú eyín erin àti igi eboni san owó rẹ.

16“ ‘Aramu ṣòwò pẹ̀lú nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ òwò rẹ̀; wọn ṣe ìpààrọ̀ (turikuoṣe) òkúta iyebíye, òwú elése àlùkò, aṣọ iṣẹ́ ọnà abẹ́rẹ́, aṣọ ọ̀gbọ̀ dáradára, ìlẹ̀kẹ̀ iyùn pupa fún ọjà títà rẹ.

17“ ‘Juda àti Israẹli, àwọn ni oníṣòwò rẹ; wọn ṣe ìpààrọ̀ ọkà, Minniti, àkàrà àdídùn; pannagi, oyin, epo àti ìkunra olóòórùn dídùn ni wọ́n fi ná ọjà rẹ.

18“ ‘Damasku, ni oníṣòwò rẹ, nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ọjà tí ó ṣe àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀; ní ti ọtí wáìnì tí Helboni, àti irun àgùntàn funfun láti Sahari, 19àti ìdẹ̀ ọtí wáìnì láti Isali, ohun wíwọ̀: irin dídán, kasia àti kálàmù ni àwọn ohun pàṣípàrọ̀ fún ọjà rẹ.

20“ ‘Dedani ni oníṣòwò rẹ ní aṣọ ìjókòó-lẹ́sin fún ẹṣin-gígùn.

21“ ‘Àwọn ará Arabia àti gbogbo àwọn ọmọ-aládé Kedari àwọn ni àwọn oníbàárà rẹ: ní ti ọ̀dọ́-àgùntàn, àgbò àti ewúrẹ́, nínú ìwọ̀nyí ni wọ́n ti jẹ́ oníbàárà rẹ.

22“ ‘Àwọn oníṣòwò ti Ṣeba àti Raama, àwọn ni oníṣòwò rẹ; wọ́n ta onírúurú tùràrí olóòórùn dídùn dáradára ní ọjà rẹ, àti àwọn òkúta iyebíye àti wúrà.

23“ ‘Harani àti Kanneh àti Edeni, àwọn oníṣòwò Ṣeba, Asiria àti Kilmadi, ni àwọn oníṣòwò rẹ. 24Wọ̀nyí ní oníbàárà rẹ ní onírúurú nǹkan: aṣọ aláró, àti oníṣẹ́-ọnà àti àpótí aṣọ olówó iyebíye, tí a fi okùn dì, tí a sì fi igi Kedari ṣe, nínú àwọn ilé-ìtajà rẹ.

25“ ‘Àwọn ọkọ̀ Tarṣiṣi ní èrò

ní ọjà rẹ

a ti mú ọ gbilẹ̀

a sì ti ṣe ọ́ lógo

ní àárín gbùngbùn Òkun

26Àwọn atukọ̀ rẹ ti mú ọ

wá sínú omi ńlá.

Ṣùgbọ́n afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn yóò fọ́ ọ sí wẹ́wẹ́

ní àárín gbùngbùn Òkun.

27Ọrọ̀ rẹ, ọjà rẹ àti àwọn ohun títà rẹ,

àwọn ìṣúra rẹ, òṣìṣẹ́ ìtukọ̀ rẹ.

Àwọn oníbàárà rẹ àti gbogbo àwọn

jagunjagun rẹ, tí ó wà nínú rẹ

àti nínú gbogbo ẹgbẹ́ rẹ

tí ó wà ní àárín rẹ

yóò rì sínú àárín gbùngbùn Òkun

ní ọjọ́ ìparun rẹ.

28Ilẹ̀ etí Òkun yóò mì

nítorí ìró igbe àwọn atukọ̀ rẹ.

29Gbogbo àwọn alájẹ̀,

àwọn atukọ̀ Òkun

àti àwọn atọ́kọ̀ ojú Òkun;

yóò sọ̀ kálẹ̀ kúrò nínú ọkọ̀ wọn,

wọn yóò dúró lórí ilẹ̀.

30Wọn yóò jẹ́ kí a gbọ́ ohùn wọn lòdì sí ọ

wọn yóò sì sọkún kíkorò lé ọ lórí

wọn yóò ku eruku lé orí ara wọn

wọn yóò sì yí ara wọn nínú eérú.

31Wọn yóò fá irun orí wọn nítorí rẹ

wọn yóò wọ aṣọ yíya

wọn yóò pohùnréré ẹkún pẹ̀lú

ìkorò ọkàn nítorí rẹ

pẹ̀lú ohùn réré ẹkún kíkorò.

32Àti nínú arò wọn ni wọn yóò sì pohùnréré ẹkún fún ọ

wọn yóò sì pohùnréré ẹkún sórí rẹ, wí pé:

“Ta ni ó dàbí Tire

èyí tí ó parun ní àárín Òkun?”

33Nígbà tí ọjà títà rẹ ti Òkun jáde wá

ìwọ tẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè lọ́rùn

ìwọ fi ọrọ̀ tí ó pọ̀ àti àwọn ọjà títà rẹ

sọ àwọn ọba ayé di ọlọ́rọ̀.

34Ní ìsinsin yìí tí Òkun fọ ọ túútúú

nínú ibú omi;

nítorí náà òwò rẹ àti gbogbo ẹgbẹ́ rẹ

ní àárín rẹ,

ni yóò ṣubú.

35Ẹnu yóò ya gbogbo àwọn ti ń gbé

ní erékùṣù náà sí ọ

jìnnìjìnnì yóò bo àwọn ọba wọn,

ìyọnu yóò sì han ní ojú wọn.

36Àwọn oníṣòwò láàrín àwọn orílẹ̀-èdè dún bí ejò sí ọ

ìwọ yóò sì jẹ́ ẹ̀rù

ìwọ kì yóò sì ṣí mọ́ láéláé.’ ”