Exode 6 – BDS & YCB

La Bible du Semeur

Exode 6:1-30

Dieu annonce son intervention

1L’Eternel dit à Moïse : Maintenant, tu vas voir ce que je vais faire au pharaon. Sous l’emprise d’une main puissante, non seulement il laissera partir le peuple, mais il le chassera lui-même de son pays. 2Puis Dieu ajouta : Je suis l’Eternel. 3Je me suis révélé à Abraham, à Isaac et à Jacob comme le Dieu tout-puissant, mais je n’ai pas été connu par eux sous mon nom : l’Eternel6.3 Voir 3.14-15 et notes. Le nom Eternel est proche du verbe hébreu serai, suis. Voir v. 7.. 4Je me suis engagé par mon alliance avec eux à leur donner le pays de Canaan, ce pays où ils étaient étrangers et où ils ont mené une vie errante. 5De plus, j’ai entendu les gémissements des Israélites réduits à l’esclavage par les Egyptiens, et je me suis souvenu de mon alliance. 6C’est pourquoi dis-leur de ma part : « Je suis l’Eternel ! Je vous soustrairai aux corvées auxquelles les Egyptiens vous soumettent : je vous libérerai de l’esclavage qu’ils vous imposent, et je vous délivrerai par la force de mon bras et en exerçant de terribles jugements. 7Je vous prendrai pour mon peuple, et je serai votre Dieu. Ainsi vous saurez que je suis l’Eternel votre Dieu qui vous affranchis des corvées que les Egyptiens vous imposent. 8Puis je vous ferai entrer dans le pays que j’ai juré de donner à Abraham, à Isaac et à Jacob ; je vous le donnerai pour qu’il vous appartienne, moi, l’Eternel. »

9Moïse répéta ces paroles aux Israélites, mais ils ne l’écoutèrent pas parce qu’ils étaient démoralisés, à cause de leur dur esclavage.

10L’Eternel parla à Moïse et lui dit : 11Va demander au pharaon, roi d’Egypte, de laisser partir les Israélites de son pays.

12Mais Moïse lui répondit : Même les Israélites ne m’ont pas écouté. Comment le pharaon m’écouterait-il, moi qui n’ai pas la parole facile ?

13L’Eternel parla à Moïse et à Aaron et leur ordonna d’aller trouver les Israélites et le pharaon, roi d’Egypte, pour faire sortir les Israélites d’Egypte.

Les généalogies des tribus de Ruben, Siméon et Lévi

14Voici les noms des chefs des groupes familiaux israélites : Fils de Ruben, premier-né d’Israël : Hénok, Pallou, Hetsrôn et Karmi. Telles sont les familles de la tribu de Ruben6.14 Dans cette généalogie, seuls les trois premiers fils de Jacob sont mentionnés puisque Moïse et Aaron faisaient partie du troisième groupe familial..

15Les fils de Siméon furent : Yemouel, Yamîn, Ohad, Yakîn, Tsohar et Saül, fils de la Cananéenne. Telles sont les familles de la tribu de Siméon.

16Voici les noms des fils de Lévi – qui vécut cent trente-sept ans6.16 Reprend la liste de Gn 46.8-11. Pour les v. 16-19, voir Nb 3.17-20 ; 26.57-58 ; 1 Ch 6.1-4. – et de leur lignée : Guershôn, Qehath et Merari. 17Fils de Guershôn : Libni et Shimeï, ancêtres de leurs familles. 18Fils de Qehath, qui vécut cent trente-trois ans : Amram, Yitsehar, Hébron et Ouzziel. 19Fils de Merari : Mahli et Moushi. Telles sont les familles de la tribu de Lévi, selon leurs lignées.

20Amram prit pour femme Yokébed, sa tante, et elle lui donna Aaron et Moïse. Amram vécut cent trente-sept ans.

21Fils de Yitsehar : Qoré, Népheg et Zikri.

22Fils d’Ouzziel : Mishaël, Eltsaphân et Sitri.

23Aaron prit pour femme Elishéba, fille d’Amminadab et sœur de Nahshôn, et elle lui donna Nadab, Abihou, Eléazar et Itamar.

24Fils de Qoré : Assir, Elqana, Abiasaph. Telles sont les familles des Qoréites.

25Eléazar, fils d’Aaron, prit pour femme une des filles de Poutiel qui lui donna Phinéas. Tels sont les chefs des groupes familiaux des lévites selon leurs différentes familles. 26C’est à Aaron et à Moïse dont il vient d’être question que l’Eternel ordonna : « Faites sortir d’Egypte les Israélites, comme une armée en bon ordre. » 27Ce sont eux qui allèrent trouver le pharaon, roi d’Egypte, pour faire sortir les Israélites de son pays.

28Voici ce qui arriva le jour où l’Eternel s’adressa à Moïse en Egypte. 29L’Eternel dit à Moïse : Je suis l’Eternel. Répète au pharaon, roi d’Egypte, tout ce que je te dis.

30Mais Moïse répondit à l’Eternel : Je n’ai pas la parole facile, comment le pharaon consentira-t-il à m’écouter ?

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Eksodu 6:1-30

16.1,6: Ap 13.17.Nígbà náà ní Olúwa sọ fún Mose pé, “Ní ìsin yìí, ìwọ yóò rí ohun tí èmi yóò ṣe sí Farao pẹ̀lú ọwọ́ agbára ńlá mi ni yóò fi jẹ́ kí wọn lọ; pẹ̀lú ọwọ́ agbára ńlá mi, òun yóò lé wọn jáde kúrò ní orílẹ̀-èdè rẹ̀.”

26.2,3: Gẹ 17.1; 28.3; 35.11; Ek 3.13-15.Ọlọ́run sì tún sọ fún Mose pé, “Èmi ni Olúwa. 3Mo fi ara hàn Abrahamu, Isaaki àti Jakọbu bí Ọlọ́run alágbára (Eli-Ṣaddai) ṣùgbọ́n nípa orúkọ mi Olúwa, Èmi kò fi ara Mi hàn wọ́n. 4Èmí sì tún fi ìdí májẹ̀mú mi múlẹ̀ pẹ̀lú wọn láti fún wọn ní ilẹ̀ Kenaani, ilẹ̀ tí wọn gbé gẹ́gẹ́ bí àjèjì. 5Èmi sì ti tún gbọ́ kíkùn àwọn ọmọ Israẹli àwọn tí àwọn ará Ejibiti mú gẹ́gẹ́ bí ẹrú, àti pé èmi sì ti rántí májẹ̀mú Mi.

6“Sọ fún àwọn ará ilé Israẹli: ‘Èmi ni Olúwa, Èmi yóò sọ yín di òmìnira kúrò nínú àjàgà àwọn ará Ejibiti. Èmi yóò sì gbà yín sílẹ̀ kúrò ní oko ẹrú wọn. Èmi yóò dá a yín sílẹ̀ pẹ̀lú apá nínà (àwọn iṣẹ́ ìyanu) àti pẹ̀lú ìdájọ́ ńlá. 7Èmi yóò mú un yín bí ènìyàn mi, èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run yín. Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín, ẹni tí ó mú un yín jáde kúrò nínú àjàgà àwọn ará Ejibiti. 8Èmi yóò mú un yín wá ilẹ̀ náà ti èmi ti búra pẹ̀lú ìgbọ́wọ́sókè láti fi fún Abrahamu. Isaaki àti Jakọbu. Èmi yóò fi fún un yín bí ohun ìní, Èmi ni Olúwa.’ ”

9Mose sì sọ èyí fún àwọn ará Israẹli, ṣùgbọ́n wọn kò fi etí sílẹ̀ sí Mose nítorí ọkàn wọn tó rẹ̀wẹ̀sì àti nítorí ìgbèkùn búburú bí ohun tí ó ti kọ́ sọ kó wọn sí ní oko ẹrú wọn.

10Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose. 11“Lọ, sọ fún Farao ọba Ejibiti pé kí ó jẹ́ kí àwọn ará Israẹli lọ kúrò ní orílẹ̀-èdè rẹ̀.”

12Ṣùgbọ́n Mose sọ fún Olúwa pé, “Nígbà ti àwọn ará Israẹli tó jẹ́ ènìyàn mi kó fetí sí ọ̀rọ̀ mi, báwo ni Farao yóò ṣe fetí sí ọ̀rọ̀ mi, nígbà ti mo jẹ́ akólòlò?”

Àkọsílẹ̀ ìdílé Mose Àti Aaroni

13Olúwa bá ìran Mose àti Aaroni sọ̀rọ̀ nípa àwọn ará Israẹli àti Farao ọba Ejibiti, ó pàṣẹ fún wọn pé kí wọn kó àwọn Israẹli jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti.

14Wọ̀nyí ni olórí ìran wọn:

Àwọn ọmọ Reubeni àkọ́bí Israẹli ni:

Hanoku, Pallu, Hesroni àti Karmi.

Àwọn wọ̀nyí ni ìdílé Reubeni.

15Àwọn ọmọ Simeoni ní:

Jemueli, Jamini, Ohadi, Jakini, Sohari àti Saulu ọmọ obìnrin Kenaani.

Àwọn wọ̀nyí ni ìran Simeoni.

166.16-19: Nu 3.17-20; 26.57,58; 1Ki 6.16-19.Ìwọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọ Lefi gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn:

Gerṣoni, Kohati àti Merari.

Lefi lo ẹ̀tàndínlógóje (137) ọdún láyé.

17Àwọn ọmọ Gerṣoni ni ìran wọn ni:

Libni àti Ṣimei.

18Àwọn ọmọ Kohati ni:

Amramu, Isari, Hebroni àti Usieli.

Kohati lo ẹ̀tàléláádóje (133) ọdún láyé.

19Àwọn ọmọ Merari ni:

Mahili àti Muṣi.

Ìwọ̀nyí ni ìran Lefi gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn.

206.20-23: Nu 26.58-60.Amramu sì fẹ́ Jokebedi arábìnrin baba rẹ̀ ní ìyàwó. Jokebedi sì bí Aaroni àti Mose fún un.

Amramu lo ẹ̀tàdínlógóje (137) ọdún láyé.

21Àwọn ọmọ Isari ni:

Kora, Nefegi àti Sikri.

22Àwọn ọmọ Usieli ni:

Miṣaeli, Elsafani àti Sitiri.

23Aaroni fẹ́ Eliṣeba ọmọbìnrin Amminadabu tí í ṣe arábìnrin Nahiṣoni, ó sì bí Nadabu, Abihu, Eleasari àti Itamari.

24Àwọn ọmọ Kora ni:

Asiri, Elkana àti Abiasafu.

Ìwọ̀nyí ni ìran Kora.

25Eleasari ọmọ Aaroni fẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọbìnrin Putieli ní ìyàwó, ó sì bí Finehasi fún un.

Ìwọ̀nyí ni olórí àwọn Lefi ni ìdílé ìdílé.

26Aaroni àti Mose yìí kan náà ni Olúwa sọ fún pé, “Ẹ kó àwọn ará Israẹli jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti ní ìsọ̀rí ìsọ̀rí.” 27Àwọn ni ó bá Farao ọba Ejibiti sọ̀rọ̀ nípa kíkó àwọn ará Israẹli jáde kúrò ni Ejibiti, àní Mose àti Aaroni yìí kan náà ni.

Aaroni di agbẹnusọ fún Mose

28Nígbà tí Olúwa bá Mose sọ̀rọ̀ ni Ejibiti, 29Olúwa sì sọ fún Mose pé, “Èmi ni Olúwa. Sọ ohun gbogbo ti mo ti sọ fún ọ fún Farao ọba Ejibiti.”

30Ṣùgbọ́n Mose sì wí ní iwájú Olúwa pé, “Níwọ́n ìgbà ti mo jẹ́ akólòlò, ọ̀nà dà ti Farao yóò ṣe fi etí sí mi?”