1 Chroniques 25 – BDS & YCB

La Bible du Semeur

1 Chroniques 25:1-31

Les groupes de chanteurs

1David, assisté des chefs du corps des fonctionnaires du culte, détacha certains descendants d’Asaph, d’Hémân et de Yedoutoun qui prophétisaient en s’accompagnant de lyres, de luths et de cymbales. Voici la liste de ceux qui furent affectés à ce service :

2Pour Asaph, les fils d’Asaph : Zakkour, Joseph, Netania et Asareéla étaient sous la direction de leur père, qui chantait sous la direction du roi des cantiques inspirés. 3Pour Yedoutoun, les six fils de Yedoutoun : Guedalia, Tseri, Esaïe, Shiméï25.3 D’après un manuscrit hébreu, certains manuscrits de l’ancienne version grecque, 1 Ch 25.17, et à cause du nombre six indiqué ici. Ce nom manque dans les autres manuscrits hébreux., Hashabia et Mattitia étaient sous la direction de leur père, qui prophétisait par le chant en s’accompagnant de la lyre, pour célébrer et louer l’Eternel. 4Pour Hémân, les fils d’Hémân : Bouqqiya, Mattania, Ouzziel, Shebouel, Yerimoth, Hanania, Hanani, Eliata, Guiddalti, Romamti-Ezer, Yoshbeqasha, Malloti, Hotir, Mahazioth. 5Tous ceux-là étaient les fils d’Hémân, le prophète du roi, qui recevait des paroles de Dieu pour exalter sa puissance. Outre ses quatorze fils, Dieu avait donné trois filles à Hémân. 6Ils chantaient tous sous la direction de leur père dans le temple de l’Eternel en s’accompagnant des cymbales, des luths et des lyres, et accomplissaient ainsi leur service pour le Temple. Asaph25.6 Autre traduction : …des lyres. Pour accomplir leur service dans le temple, Asaph…, Yedoutoun et Hémân étaient sous la direction du roi. 7Le nombre des lévites formés et passés maîtres dans l’art de louer l’Eternel par le chant était de deux cent quatre-vingt-huit. 8Leur ordre de service fut déterminé par tirage au sort, sans faire de différence entre ceux de rang élevé et ceux de rang peu important, ou entre maîtres et disciples. 9Le premier sort échut pour Asaph à Joseph, de la famille d’Asaph. 10-31Ensuite, dans l’ordre résultant du tirage au sort, voici la liste des chefs de groupe, chaque groupe comprenant douze hommes, soit le chef, ses fils et des hommes de sa parenté. Le deuxième sort échut à Guedalia. Puis vinrent : Zakkour, Yitseri, Netania, Bouqqiya, Yesareéla, Esaïe, Mattania, Shimeï, Azaréel, Hashabia, Shoubaël, Mattitia, Yerémoth, Hanania, Yoshbeqasha, Hanani, Malloti, Eliyata, Hotir, Guiddalti, Mahazioth, Romamti-Ezer.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Kronika 25:1-31

Àwọn akọrin

1Pẹ̀lúpẹ̀lú Dafidi àti àwọn olórí àwọn ọmọ-ogun, ó sì yà díẹ̀ sọ́tọ̀ lára àwọn ọmọ Asafu, Hemani àti Jedutuni fún ìsìn àsọtẹ́lẹ̀, pẹ̀lú dùùrù, ohun èlò orin olókùn àti kimbali. Èyí sì ní àwọn iye àwọn ọkùnrin ẹni tí ó ṣe oníṣẹ́ ìsìn yìí:

2Nínú àwọn ọmọ Asafu:

Sakkuri, Josẹfu, Netaniah àti Asarela, àwọn ọmọ Asafu ni wọ́n wà lábẹ́ ìbojútó Asafu, ẹni tí ó sọtẹ́lẹ̀ lábẹ́ ìbojútó ọba.

3Gẹ́gẹ́ bí ti Jedutuni, nínú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀:

Gedaliah, Seri, Jeṣaiah, Ṣimei, Haṣabiah àti Mattitiah, mẹ́fà nínú gbogbo wọn, lábẹ́ ìbojútó baba wọn Jedutuni, ẹni tí ó sọtẹ́lẹ̀, ẹni tí ó lo dùùrù láti dúpẹ́ àti láti yin Olúwa:

4Gẹ́gẹ́ bí ti Hemani, nínú àwọn ọmọ rẹ̀:

Bukkiah, Mattaniah, Usieli, Ṣubueli àti Jerimoti; Hananiah, Hanani, Eliata, Giddalti, àti Romamtieseri, Joṣbekaṣa, Malloti, Hotiri, Mahasiotu. 5Gbogbo àwọn wọ̀nyí sì ni ọmọ Hemani àti wòlíì ọba. Wọ́n sì fi wọ́n fún nípa ìlérí Ọlọ́run láti máa gbé ìwo sókè. Ọlọ́run sì fún Hemani ní ọmọkùnrin mẹ́rìnlá àti àwọn ọmọbìnrin mẹ́ta.

6Gbogbo àwọn ọkùnrin yìí ni wọ́n wà lábẹ́ ìbojútó àwọn baba wọn fún ohun èlò orin ilé Olúwa, pẹ̀lú kimbali, ohun èlò orin olókùn àti dùùrù, fún ìsìn ilé Olúwa.

Asafu, Jedutuni àti Hemani sì wà lábẹ́ ọba. 7Àwọn ìdílé wọn pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó mòye àti àwọn tí a kọ́ ní ohun èlò orin fún Olúwa, iye wọn sì jẹ́ ọ̀rìnlélúgba ó-lé-mẹ́jọ (288). 8Kékeré àti àgbà bákan náà, olùkọ́ àti gẹ́gẹ́ bí ti akẹ́kọ̀ọ́, ṣẹ́ kèké fún iṣẹ́ wọn.

9Kèké èkínní èyí tí ó jẹ́ ti Asafu, jáde sí Josẹfu, àwọn ọmọ rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀ jẹ́, méjìlá

èkejì sì ni Gedaliah, òun àti àwọn ìdílé rẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀, méjìlá

10ẹlẹ́kẹta sí Sakkuri, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ìdílé, méjìlá

11ẹlẹ́kẹrin sí Isiri, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ìdílé rẹ̀ jẹ́, méjìlá

12ẹlẹ́karùnún sí Netaniah, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ìdílé rẹ̀ jẹ́, méjìlá

13ẹlẹ́kẹfà sí Bukkiah, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ìdílé rẹ̀ jẹ́, méjìlá

14ẹlẹ́keje sí Jasarela, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ìdílé rẹ̀ jẹ́, méjìlá

15ẹlẹ́kẹjọ sí Jeṣaiah, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ìdílé rẹ̀ jẹ́, méjìlá

16ẹlẹ́kẹsànán sí Mattaniah, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ìdílé rẹ̀ jẹ́, méjìlá

17ẹlẹ́kẹwàá sí Ṣimei, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ìdílé rẹ̀ jẹ́, méjìlá

18ẹlẹ́kọkànlá sí Asareeli, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ìdílé rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá

19ẹlẹ́kẹjìlá sí Haṣabiah, àwọn ọmọ rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá

20ẹlẹ́kẹtàlá sí Ṣubueli, àwọn ọmọ rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá

21ẹlẹ́kẹrìnlá sí Mattitiah, àwọn ọmọ rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá

22ẹlẹ́kẹdógún sí Jerimoti, àwọn ọmọ rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá

23ẹlẹ́kẹrìn-dínlógún sí Hananiah, àwọn ọmọ rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá

24ẹlẹ́kẹtà-dínlógún sí Joṣbekaṣa, àwọn ọmọ rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá

25ẹlẹ́kejì-dínlógún sí Hanani, àwọn ọmọ rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá

26ẹlẹ́kọkàndínlógún sí Malloti, àwọn ọmọ rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá

27ogún sí Eliata, àwọn ọmọ rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá

28ẹlẹ́kọkànlélógún sí Hotiri, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ìdílé rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá

29ẹlẹ́kejìlélógún sí Giddalti, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ìdílé rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá

30ẹlẹ́kẹtàlélógún sí Mahasiotu, àwọn ọmọ rẹ àti ìdílé rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá

31ẹlẹ́kẹrìnlélógún sí Romamtieseri àwọn ọmọ rẹ̀, àti àwọn ìdílé rẹ̀, sì jẹ́, méjìlá.