Jeremias 11 – APSD-CEB & YCB

Ang Pulong Sa Dios

Jeremias 11:1-23

Wala Tumana sa Juda ang Kasabotan

1Unya miingon ang Ginoo kang Jeremias, 2“Pahinumdomi ang mga taga-Juda ug taga-Jerusalem sa mga lagda sa among kasabotan. 3Ingna sila nga ako, ang Ginoo, ang Dios sa Israel, nagaingon nga tunglohon ko ang tawo nga dili motuman sa lagda niini nga kasabotan. 4Kini nga mga lagda gipatuman ko sa inyong mga katigulangan sa dihang gipagawas ko sila gikan sa Ehipto, ang dapit nga daw hurnohan nga tunawan sa puthaw. Miingon ako kanila, ‘Kon tumanon ninyo ako ug ang tanan kong mga sugo, mahimo ko kamong katawhan ug ako mahimong inyong Dios. 5Unya tumanon ko ang akong gipanaad sa inyong mga katigulangan nga hatagan ko silag maayo ug mabungahon nga yuta11:5 maayo… yuta: sa Hebreo, yuta nga nagaagas ang gatas ug dugos.—ang yuta nga inyong gipanag-iyahan karon.’ ”

Mitubag ako, “Hinaut pa, Ginoo.”

6Miingon pag-usab ang Ginoo kanako, “Ipahibalo kini nga mga mensahe ngadto sa mga lungsod sa Juda ug sa mga kadalanan sa Jerusalem: ‘Hinumdomi ninyo ug tumana ang mga lagda niini nga kasabotan. 7Gikan pa sa panahon nga gipagawas ko ang inyong mga katigulangan gikan sa Ehipto hangtod karon, gibalik-balik ko ang pagpasidaan kanila nga tumanon ako. 8Apan wala gayod sila maminaw o manumbaling kanako. Nagmagahi hinuon sila ug gisunod nila ang tinguha sa ilang daotan nga kasingkasing. Gisugo ko sila nga tumanon ang kasabotan, apan wala gayod nila kini tumana. Busa gipadad-an ko sila sa tanang tunglo nga nahisulat niini nga kasabotan.’ ”

9Miingon pa gayod ang Ginoo kanako, “Adunay nagplano batok kanako diha sa mga lumulupyo sa Jerusalem ug sa ubang bahin sa Juda. 10Mibalik na usab sila sa paghimo sa mga sala nga gihimo sa ilang mga katigulangan kaniadto, nga dili gayod maminaw sa akong mga pulong. Nagsimba sila sa ubang mga dios. Managsamang gilapas sa katawhan sa Israel ug sa Juda ang kasabotan nga gihimo ko ngadto sa ilang mga katigulangan. 11Busa ako, ang Ginoo, nagaingon nga padad-an ko silag katalagman nga dili nila maikyasan. Bisan ug mangayo pa sila kanakog tabang, dili ko sila paminawon. 12Unya mangadto sila sa mga dios nga ilang gisunogan ug insenso ug magpakitabang, apan dili gayod kini makatabang kanila kon moabot na ang katalagman.

13“O mga taga-Juda, pagkadaghan sa inyong mga dios, sama kadaghan sa inyong mga lungsod. Ug kon unsa kadaghan ang inyong mga dalan sa Jerusalem mao usab kadaghan ang mga halaran nga gitukod ninyo aron sunogan sa insenso alang sa makauulaw nga dios nga si Baal.

14“Busa Jeremias, ayaw pag-ampo alang niining mga tawhana. Ayaw pagpakilooy kanako alang kanila kay dili ko sila paminawon kon manawag sila kanako sa panahon sa ilang kalisod. 15Ang katawhan nga akong gihigugma naghimog daghang daotan nga mga butang. Nan, unsa may ilang katungod sa pag-adto sa akong templo? Makapugong ba ang ilang mga halad sa pag-abot sa kalaglagan diha kanila? Gakalipay man gani sila sa paghimog daotan!”

16Kaniadto gipakasama sila sa Ginoo sa labong nga kahoyng olibo nga nindot ug mga bunga. Apan uban sa gadahunog nga dilaab sa kalayo laglagon sila sa Ginoo ug ang ilang mga sanga dili na mapuslan. 17Ang Ginoo nga Makagagahom maoy nagtukod sa Juda ug Israel, apan karon nagmando siya nga laglagon kini tungod sa daotan ninyong binuhatan. Gipalagot ninyo siya pinaagi sa pagsunog ug insenso ngadto kang Baal.

Ang Plano Batok kang Jeremias

18Gisultihan ako sa Ginoo sa plano sa mga kaaway batok kanako. 19Sama ako sa usa ka maaghop nga karnero nga wala masayod nga ginadala na diay siya sa ihawanan. Wala ako masayod nga may plano diay sila sa pagpatay kanako. Miingon sila, “Patyon nato siya sama sa pagputol sa kahoy uban sa iyang mga bunga, aron mahanaw siya sa kalibotan ug dili na hinumdoman pa.”

20Apan nagaampo ako, “O Ginoo nga Makagagahom, matarong ang imong paghukom, ug nasayod ka sa hunahuna ug kasingkasing sa tawo. Pakit-a ako nga imo silang panimaslan, kay gitugyan ko na kanimo ang akong reklamo.”

21Gusto sa katawhan sa Anatot nga patyon ako kon dili ako moundang sa pagsugilon sa mensahe sa Ginoo. 22Busa mao kini ang gisulti sa Ginoo nga Makagagahom, “Silotan ko gayod sila. Mangamatay sa gubat ang ilang mga batan-ong lalaki, ug mangamatay sa kagutom ang ilang mga kabataan. 23Wala gayoy mahibiling buhi sa mga taga-Anatot, kay padad-an ko sila ug katalagman sa panahon nga silotan ko sila.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Jeremiah 11:1-23

1Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Jeremiah wá: 2“Fetísílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ májẹ̀mú yìí, kí o sì sọ wọ́n fún àwọn ènìyàn Juda, àti gbogbo àwọn tó ń gbé ni Jerusalẹmu. 3Sọ fún wọn wí pé èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli wí: ‘Ègbé ni fún ẹni náà tí kò pa ọ̀rọ̀ májẹ̀mú yìí mọ́. 4Àwọn májẹ̀mú tí mo pàṣẹ fún àwọn baba ńlá yín, nígbà tí mo mú wọn jáde láti Ejibiti, láti inú iná alágbẹ̀dẹ wá.’ Mo wí pé, ‘Ẹ gbọ́ tèmi, kí ẹ sì ṣe ohun gbogbo tí mo pàṣẹ fún un yín. Ẹ̀yin ó sì jẹ́ ènìyàn mi: Èmi ó sì jẹ́ Ọlọ́run yín 5Nígbà náà ni Èmi ó sì mú ìlérí tí mo búra fún àwọn baba ńlá yín ṣẹ; láti fún wọn ní ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti fún oyin,’ ilẹ̀ tí ẹ ní lónìí.”

Mo sì dáhùn wí pé, “Àmín, Olúwa.”

6Olúwa wí fún mi pé, “Kéde gbogbo ọ̀rọ̀ yìí ní àwọn ìlú Juda àti ní gbogbo òpópónà ìgboro Jerusalẹmu pé, ‘Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ májẹ̀mú yìí, kí ẹ sì se wọn. 7Láti ìgbà tí mo ti mú àwọn baba yín jáde láti ilẹ̀ Ejibiti wá títí di òní, mo kìlọ̀ fún wọn lọ́pọ̀ ìgbà wí pé, “Ẹ gbọ́ tèmi.” 8Ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò kọbi ara sí i dípò èyí wọ́n tẹ̀síwájú ni agídí ọkàn wọn. Mo sì mú gbogbo ègún inú májẹ̀mú tí mo ti ṣèlérí, tí mo sì ti pàṣẹ fún wọn láti tẹ̀lé, tí wọn kò tẹ̀lé wa sórí wọn.’ ”

9Olúwa sì wí fún mi pé, “Ọ̀tẹ̀ kan wà láàrín àwọn ará Juda àti àwọn tí ń gbé ní Jerusalẹmu. 10Wọ́n ti padà sí ìdí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba ńlá wọn tí wọn kọ̀ láti tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ mi, wọ́n ti tẹ̀lé àwọn ọlọ́run mìíràn láti sìn wọ́n. Ilé Israẹli àti ilé Juda ti ba májẹ̀mú tí mo dá pẹ̀lú àwọn baba ńlá wọn jẹ́. 11Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa wí: ‘Èmi yóò mu ibi tí wọn kò ní le è yẹ̀ wá sórí wọn, bí wọ́n tilẹ̀ ké pè mí èmi kì yóò fetí sí igbe wọn. 12Àwọn ìlú Juda àti àwọn ará Jerusalẹmu yóò lọ kégbe sí àwọn òrìṣà tí wọ́n ń sun tùràrí sí; àwọn òrìṣà náà kò ní ràn wọ́n lọ́wọ́ ní ìgbà tí ìpọ́njú náà bá dé. 13Ìwọ Juda, bí iye àwọn ìlú rẹ, bẹ́ẹ̀ iye àwọn òrìṣà rẹ; bẹ́ẹ̀ ni iye pẹpẹ tí ẹ̀yin ti tẹ́ fún sísun tùràrí Baali ohun ìtìjú n nì ṣe pọ̀ bí iye òpópónà tí ó wà ní Jerusalẹmu.’

14“Má ṣe gbàdúrà fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí tàbí kí o bẹ̀bẹ̀ fún wọn, nítorí pé, Èmi kì yóò dẹtí sí wọn nígbà tí wọ́n bá ké pè mí ní ìgbà ìpọ́njú.

15“Kí ni olùfẹ́ mi ní í ṣe ní tẹmpili mi,

bí òun àti àwọn mìíràn ṣe ń hu oríṣìíríṣìí ìwà àrékérekè?

Ǹjẹ́ ẹran tí a yà sọ́tọ̀ lè mú ìjìyà kúrò lórí rẹ̀?

Nígbà tí ó bá ń ṣe iṣẹ́ búburú rẹ̀,

nígbà náà jẹ́ kí inú rẹ̀ kí ó dùn.”

16Olúwa pè ọ́ ní igi olifi

pẹ̀lú èso rẹ tí ó dára ní ojú.

Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ìjì líle

ọ̀wọ́-iná ni yóò sun ún

tí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ yóò sì di gígé kúrò.

17Olúwa àwọn ọmọ-ogun tí ó dá ọ ti kéde ibi sí ọ, nítorí ilé Israẹli àti Juda ti ṣe ohun ibi, wọ́n sì ti mú inú bí mi, wọ́n ti ru ìbínú mi sókè nípa sísun tùràrí si Baali.

Ọ̀tẹ̀ sí Jerusalẹmu

18Nítorí Ọlọ́run fi ọ̀tẹ̀ wọn hàn mí mo mọ̀ ọ́n; nítorí ní àsìkò náà ó fi ohun tí wọ́n ń ṣe hàn mí. 19Mo ti dàbí ọ̀dọ́-àgùntàn jẹ́ẹ́jẹ́ tí a mú lọ fún pípa; N kò mọ̀ pé wọ́n ti gbìmọ̀ búburú sí mi wí pé:

“Jẹ́ kí a run igi àti èso rẹ̀;

jẹ́ kí a gé e kúrò ní orí ilẹ̀ alààyè,

kí a má lè rántí orúkọ rẹ̀ mọ́.”

20Ṣùgbọ́n ìwọ Olúwa àwọn ọmọ-ogun,

tí ó ń ṣe ìdájọ́ òdodo,

tí ó ń ṣe àyẹ̀wò ẹ̀mí àti ọkàn,

jẹ́ kí n rí ẹ̀san rẹ lórí wọn;

nítorí ìwọ ni mo fi ọ̀rọ̀ mi lé lọ́wọ́.

21“Nítorí náà, èyí ni ohun tí Ọlọ́run sọ nípa àwọn arákùnrin Anatoti tí wọ́n ń lépa ẹ̀mí rẹ̀, tí wọ́n ń wí pé, ‘Má ṣe sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ Olúwa, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ ìwọ ó kú láti ọwọ́ wa.’ 22Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ pé, ‘Èmi yóò fì ìyà jẹ wọ́n, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wọn yóò tipasẹ̀ idà kú, ìyàn yóò pa àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn. 23Kò ní ṣẹ́kù ohunkóhun sílẹ̀ fún wọn nítorí èmi yóò mú ibi wá sórí àwọn ènìyàn Anatoti ní ọdún ìbẹ̀wò wọn.’ ”