Amplified Bible

John 18

Judas Betrays Jesus

1Having said these things, Jesus left with His disciples and went across the [a]ravine of the Kidron. There was a garden there, which He and His disciples entered. Now Judas, who was betraying Him, knew the place, because Jesus had often met there with His disciples. So Judas, having obtained the Roman [b]cohort and some officers from the high priests and the Pharisees, came there with lanterns and torches and weapons. Then Jesus, knowing all that was about to happen to Him, went to them and asked, “Whom do you want?” They answered Him, “Jesus the Nazarene.” Jesus said, “I am He.” And Judas, who was betraying Him, was also standing with them. When Jesus said, “I am He,” they drew back and fell to the ground. Again He asked them, “Whom do you want?” And they said, “Jesus the Nazarene.” Jesus answered, “I told you that I am He; so if you want Me, let these men go on their way.” This was to fulfill and verify the words He had spoken, “Of those whom You have given Me, I have not lost even one.” 10 Then Simon Peter, who had a sword, drew it and struck the high priest’s servant, cutting off his right ear. The servant’s name was Malchus. 11 So Jesus said to Peter, “Put the sword [back] in its sheath! Shall I not drink the cup which My Father has given Me?”

Jesus before Annas and Caiaphas

12 So the cohort and their commander and the officers of the Jews arrested Jesus and bound Him, 13 and led Him to [c]Annas first; for he was the father-in-law of Caiaphas, who was high priest that year. 14 It was Caiaphas who had advised the Jews that it was expedient for one man to die on behalf of the people.

15 Simon Peter and [d]another disciple were following Jesus. Now that disciple was known to the high priest, so he went with Jesus into the courtyard of the [residence of the] high priest; 16 but Peter was standing outside at the door. So the other disciple (John), who was known to the high priest, went out and spoke to the doorkeeper, and brought Peter inside. 17 Then the servant girl who kept the door said to Peter, “You are not one of this Man’s disciples, are you?” He said, “I am not.” 18 Now the servants and the officers had made a fire of coals, because it was cold, and they were standing and warming themselves. And Peter was with them, standing and warming himself.

19 Then the high priest questioned Jesus about His disciples and about His teaching. 20 Jesus answered him, “I have spoken openly to the world. I always taught in a synagogue and in the temple [area], where all the Jews habitually congregate; and I said nothing in secret. 21 Why question Me? Question those who have heard what I said to them. They know what I said.” 22 But when He said this, one of the officers who was standing nearby [e]struck Jesus [in the face], saying, “Is that how You answer the high priest?” 23 Jesus replied, “If I have said anything wrong, make a formal statement about the wrong; but if [I spoke] properly, why did you strike Me?” 24 So Annas sent Him bound to Caiaphas the high priest.

Peter’s Denial of Jesus

25 Now Simon Peter was [still] standing and warming himself. So they said to him, “You are not one of His disciples, are you?” He denied it and said, “I am not.” 26 One of the high priest’s servants, a relative of the one whose ear Peter cut off, said, “Did I not see you with Him in the garden?” 27 So Peter denied it again, and immediately a rooster crowed.

Jesus before Pilate

28 Then the Jews led Jesus from Caiaphas to the Praetorium (governor’s palace). Now it was early and the Jews did not enter the Praetorium so that they would not be [ceremonially] unclean, but might [be able to] eat [and participate in the Feast of Unleavened Bread which began after] the [f]Passover [supper]. 29 So Pilate came out to them and asked, “What accusation do you bring against this Man?” 30 They answered, “If He were not a criminal, we would not have handed Him over to you [for judgment].” 31 Then Pilate said to them, “Take Him yourselves and judge Him according to your own law.” The Jews said, “We are not permitted to put anyone to death.” 32 This was to fulfill the word which Jesus had spoken to indicate by what manner of death He was going to die.

33 So Pilate went into the Praetorium again, and called Jesus and asked Him, “Are You the King of the Jews?” 34 Jesus replied, “Are you saying this on your own initiative, or did others tell you about Me?” 35 Pilate answered, “I am not a Jew, am I? Your own people and their chief priests have handed You over to me. What have You done [that is worthy of death]?” 36 Jesus replied, “My kingdom is not of this world [nor does it have its origin in this world]. If My kingdom were of this world, My servants would be fighting [hard] to keep Me from being handed over to the Jews; but as it is, My kingdom is not of this world.” 37 So Pilate said to Him, “Then You are a King?” Jesus answered, “You say [correctly] that I am a King. This is why I was born, and for this I have come into the world, to testify to the truth. Everyone who is of the truth [who is a friend of the truth and belongs to the truth] hears and listens carefully to My voice.” 38 Pilate said to Him [scornfully], “What is truth?”

And when he had said this, he went out to the Jews again and told them, “I find no guilt in Him [no crime, no cause for an accusation]. 39 But you have a custom that I release someone for you at the Passover. So shall I release for you the King of the Jews?” 40 Then they all shouted back again, “Not this Man, but Barabbas!” Now Barabbas was a [g]robber.

Notas al pie

  1. John 18:1 Most of the time this was a dry stream bed (wadi), but the winter rains would turn it into a torrent of water. The ravine separated Jerusalem from the Mount of Olives. In the OT King David took this same route while escaping from Jerusalem to the Mount of Olives, after he was betrayed by Absalom and Ahithophel (2 Sam 15:23).
  2. John 18:3 A “cohort” was a sub-unit of a Roman legion and normally was composed of about 600 troops, but could be fewer in number. The Jewish religious leaders probably made arrangements with Pilate for Judas to have temporary use of the troops.
  3. John 18:13 See note 11:49.
  4. John 18:15 Most likely John, the author of this Gospel.
  5. John 18:22 It was illegal to strike the accused.
  6. John 18:28 Jesus’ arrest occurred after He and His disciples had eaten the Passover supper. Passover/Feast of Unleavened Bread lasted seven days.
  7. John 18:40 Or insurrectionist.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Johanu 18

Wọ́n mú Jesu

1Nígbà tí Jesu sì ti sọ nǹkan wọ̀nyí tán, ó jáde pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lọ sókè odò Kidironi, níbi tí àgbàlá kan wà, nínú èyí tí ó wọ̀, Òun àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.

Judasi, ẹni tí ó fihàn, sì mọ ibẹ̀ pẹ̀lú: nítorí nígbà púpọ̀ ni Jesu máa ń lọ síbẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Nígbà náà ni Judasi, lẹ́yìn tí ó ti gba ẹgbẹ́ ọmọ-ogun, àti àwọn oníṣẹ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisi wá síbẹ̀ ti àwọn ti fìtílà àti ògùṣọ̀, àti ohun ìjà.

Nítorí náà bí Jesu ti mọ ohun gbogbo tí ń bọ̀ wá bá òun, ó jáde lọ, ó sì wí fún wọn pé, “Ta ni ẹyin ń wá?”

Wọ́n sì dá a lóhùn wí pé, “Jesu ti Nasareti.”

Jesu sì wí fún wọn pé, “Èmi nìyí.” (Àti Judasi ọ̀dàlẹ̀, dúró pẹ̀lú wọn.) Nítorí náà bí ó ti wí fún wọn pé, “Èmi nìyí,” wọ́n bì sẹ́yìn, wọ́n sì ṣubú lulẹ̀.

Nítorí náà ó tún bi wọ́n léèrè, wí pé, “Ta ni ẹ ń wá?”

Wọ́n sì wí pé, “Jesu ti Nasareti.”

Jesu dáhùn pé, “Mo ti wí fún yín pé, èmi nìyí: ǹjẹ́ bí èmi ni ẹ bá ń wá, ẹ jẹ́ kí àwọn wọ̀nyí máa lọ: Kí ọ̀rọ̀ nì kí ó lè ṣẹ, èyí tó wí pé, Àwọn tí ìwọ fi fún mi, èmi kò sọ ọ̀kan nù nínú wọn.”

10 Nígbà náà ni Simoni Peteru ẹni tí ó ní idà, fà á yọ, ó sì ṣá ọmọ ọ̀dọ̀ olórí àlùfáà, ó sì ké etí ọ̀tún rẹ̀ sọnù. Orúkọ ìránṣẹ́ náà a máa jẹ́ Mákọ́ọ̀sì.

11 Nítorí náà Jesu wí fún Peteru pé, “Tẹ idà rẹ bọ inú àkọ̀ rẹ: ago tí baba ti fi fún mi, èmi ó ṣe aláìmu ún bí?”

Jesu níwájú Annasi

12 Nígbà náà ni ẹgbẹ́ ọmọ-ogun àti olórí ẹ̀ṣọ́, àti àwọn oníṣẹ́ àwọn Júù mú Jesu, wọ́n sì dè é. 13 Wọ́n kọ́kọ́ fà á lọ sọ́dọ̀ Annasi; nítorí òun ni àna Kaiafa, ẹni tí í ṣe olórí àlùfáà ní ọdún náà. 14 Kaiafa sá à ni ẹni tí ó ti bá àwọn Júù gbìmọ̀ pé, ó ṣàǹfààní kí ènìyàn kan kú fún àwọn ènìyàn.

Peteru sẹ́ Jesu ní àkọ́kọ́

15 Simoni Peteru sì ń tọ Jesu lẹ́yìn, àti ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn kan: ọmọ-ẹ̀yìn náà jẹ́ ẹni mí mọ̀ fún olórí àlùfáà, ó sì bá Jesu wọ ààfin olórí àlùfáà lọ. 16 Ṣùgbọ́n Peteru dúró ní ẹnu-ọ̀nà lóde. Nígbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn náà tí í ṣe ẹni mí mọ̀ fún olórí àlùfáà jáde, ó sì bá olùṣọ́nà náà sọ̀rọ̀, ó sì mú Peteru wọlé.

17 Nígbà náà ni ọmọbìnrin náà tí ń ṣọ́ ẹnu-ọ̀nà wí fún Peteru pé, “Ìwọ pẹ̀lú ha ń ṣe ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ọkùnrin yìí bí?”

Ó wí pé, “Èmi kọ́.”

18 Àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ àti àwọn aláṣẹ sì dúró níbẹ̀, àwọn ẹni tí ó ti dáná nítorí ti òtútù mú, wọ́n sì ń yáná: Peteru sì dúró pẹ̀lú wọn, ó ń yáná.

Alábojútó àlùfáà fi ọ̀rọ̀ wá Jesu lẹ́nu wò

19 Nígbà náà ni olórí àlùfáà bi Jesu léèrè ní ti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, àti ní ti ẹ̀kọ́ rẹ̀.

20 Jesu dá a lóhùn pé, “Èmi ti sọ̀rọ̀ ní gbangba fún aráyé; nígbà gbogbo ni èmi ń kọ́ni nínú Sinagọgu, àti ní tẹmpili níbi tí gbogbo àwọn Júù ń péjọ sí: èmi kò sì sọ ohun kan ní ìkọ̀kọ̀. 21 Èéṣe tí ìwọ fi ń bi mí léèrè? Béèrè lọ́wọ́ àwọn tí ó ti gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, ohun tí mo wí fún wọn: wò ó, àwọn wọ̀nyí mọ ohun tí èmi wí.”

22 Bí ó sì ti wí èyí tan, ọ̀kan nínú àwọn aláṣẹ tí ó dúró tì í fi ọwọ́ rẹ̀ lu Jesu, pé, “alábojútó àlùfáà ni ìwọ ń dá lóhùn bẹ́ẹ̀?”

23 Jesu dá a lóhùn pé, “Bí mo bá sọ̀rọ̀ búburú, jẹ́rìí sí búburú náà: ṣùgbọ́n bí rere bá ni, èéṣe tí ìwọ fi ń lù mí?” 24 Nítorí Annasi rán an lọ ní dídè sọ́dọ̀ Kaiafa olórí àlùfáà.

Peteru sẹ́ Jesu ní ìgbà kejì àti ìgbà kẹta

25 Ṣùgbọ́n Simoni Peteru dúró, ó sì ń yáná. Nígbà náà ni wọ́n wí fún un pé, “Ìwọ pẹ̀lú ha jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀?”

Ó sì sẹ́, wí pé, “Èmi kọ́.”

26 Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ olórí àlùfáà, tí ó jẹ́ ìbátan ẹni tí Peteru gé etí rẹ̀ sọnù, wí pé, “Èmi ko ha rí ọ pẹ̀lú rẹ̀ ní àgbàlá?” 27 Peteru tún sẹ́: lójúkan náà àkùkọ sì kọ.

Jesu níwájú Pilatu

28 Nígbà náà, wọ́n fa Jesu láti ọ̀dọ̀ Kaiafa lọ sí ibi gbọ̀ngàn ìdájọ́: ó sì jẹ́ kùtùkùtù òwúrọ̀; àwọn tìkára wọn kò wọ inú gbọ̀ngàn ìdájọ́, kí wọn má ṣe di aláìmọ́, ṣùgbọ́n kí wọn lè jẹ àsè ìrékọjá. 29 Nítorí náà Pilatu jáde tọ̀ wọ́n lọ, ó sì wí pé, “Ẹ̀sùn kín ní ẹ̀yin mú wá fun ọkùnrin yìí?”

30 Wọ́n sì dáhùn wí fún un pé, “Ìbá má ṣe pé ọkùnrin yìí ń hùwà ibi, a kì bá tí fà á lé ọ lọ́wọ́.”

31 Nítorí náà Pilatu wí fún wọn pé, “Ẹ mú un tìkára yín, kí ẹ sì ṣe ìdájọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òfin yín.”

Nítorí náà ni àwọn Júù wí fún un pé, “Kò tọ́ fún wa láti pa ẹnikẹ́ni.” 32 Kí ọ̀rọ̀ Jesu ba à lè ṣẹ, èyí tí ó sọ tí ó ń ṣàpẹẹrẹ irú ikú tí òun yóò kú.

33 Nítorí náà, Pilatu tún wọ inú gbọ̀ngàn ìdájọ́ lọ, ó sì pe Jesu, ó sì wí fún un pé, “Ìwọ ha ni a pè ni ọba àwọn Júù bí?”

34 Jesu dáhùn pé, “Èrò ti ara rẹ ni èyí, tàbí àwọn ẹlòmíràn sọ ọ́ fún ọ nítorí mi?”

35 Pilatu dáhùn wí pé, “Èmi ha jẹ́ Júù bí? Àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè rẹ, àti àwọn olórí àlùfáà ni ó fà ọ́ lé èmi lọ́wọ́: kín ní ìwọ ṣe?”

36 Jesu dáhùn wí pé, “Ìjọba mi kì í ṣe ti ayé yìí. Ìbá ṣe pé ìjọba mi jẹ́ ti ayé yìí, àwọn ìránṣẹ́ mi ìbá jà, kí a má ba à fi mí lé àwọn Júù lọ́wọ́: ṣùgbọ́n nísinsin yìí ìjọba mi kì í ṣe láti ìhín lọ.”

37 Nítorí náà, Pilatu wí fún un pé, “ọba ni ọ́ nígbà náà?”

Jesu dáhùn wí pé, “Ìwọ wí pé, ọba ni èmi jẹ́. Nítorí èyí ni a ṣe bí mí, àti nítorí ìdí èyí ni mo sì ṣe wá sí ayé kí n lè jẹ́rìí sí òtítọ́, olúkúlùkù ẹni tí í ṣe ti òtítọ́ ń gbọ́ ohùn mi.”

38 Pilatu wí fún un pé, “Kín ni òtítọ́?” Nígbà tí ó sì ti wí èyí tan, ó tún jáde tọ àwọn Júù lọ, ó sì wí fún wọn pé, “Èmi kò rí ẹ̀ṣẹ̀ kan lọ́wọ́ rẹ̀. 39 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ní àṣà kan pé, kí èmi dá ọ̀kan sílẹ̀ fún yín nígbà àjọ ìrékọjá: nítorí náà ẹ ó ha fẹ́ kí èmi dá ọba àwọn Júù sílẹ̀ fún yín bí?”

40 Nítorí náà gbogbo wọn tún kígbe pé, “Kì í ṣe ọkùnrin yìí, bí kò ṣe Baraba!” Ọlọ́ṣà sì ni Baraba.